Jobu 28 – YCB & NAV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 28:1-28

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jobu

1Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ,

àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.

2Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin,

bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.

3Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn,

ó sì ṣe àwárí ìṣúra

láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.

4Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè,

àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀,

wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.

5Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá,

àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná

6Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Safire,

o sì ní erùpẹ̀ wúrà.

7Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀,

àti ojú gúnnugún kò rí i rí;

8Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí,

bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.

9Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta,

ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

10Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,

ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

11Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya,

ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

12Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,

níbo sì ni òye ń gbe?

13Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

14Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”;

omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”

15A kò le è fi wúrà rà á,

bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

16A kò le è fi wúrà ofiri,

tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e.

17Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;

bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.

18A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi;

iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.

19Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀;

bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá?

Tàbí níbo ni òye ń gbé?

21A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo,

ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

22Ibi ìparun àti ikú wí pé,

àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

23Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀,

òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.

24Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé,

ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

25Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́,

ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi.

26Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,

tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

27Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde;

ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

28Àti fún ènìyàn ni ó wí pé,

“Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n,

àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

Ketab El Hayat

أيوب 28:1-28

أين توجد الحكمة؟

1لَا رَيْبَ أَنَّ هُنَاكَ مَنْجَماً لِلْفِضَّةِ وَبَوْتَقَةً لِتَمْحِيصِ الذَّهَبِ. 2يُسْتَخْرَجُ الْحَدِيدُ مِنَ التُّرَابِ، وَمِنَ الْمَعْدَنِ الْخَامِ يُصْهَرُ النُّحَاسُ. 3قَدْ وَضَعَ الإِنْسَانُ حَدّاً لِلظُّلْمَةِ، وَبَحَثَ فِي أَقْصَى طَرَفٍ عَنِ الْمَعْدَنِ فِي الظُّلُمَاتِ الْعَمِيقَةِ. 4حَفَرُوا مَنْجَماً بَعِيداً، فِي مَوْضِعٍ مُقْفِرٍ مِنَ السُّكَّانِ، هَجَرَتْهُ أَقْدَامُ النَّاسِ، وَتَدَلُّوْا فِيهِ. 5أَمَّا الأَرْضُ الَّتِي تُنْبِتُ لَنَا خَيْراً فَقَدِ انْقَلَبَ أَسْفَلُهَا كَمَا بِنَارٍ. 6يَكْمُنُ فِي صُخُورِهَا الْيَاقُوتُ الأَزْرَقُ، وَفِي تُرَابِهَا الذَّهَبُ. 7لَمْ يَهْتَدِ إِلَى طَرِيقِهَا طَيْرٌ جَارِحٌ، وَلَمْ تُبْصِرْهُ عَيْنُ صَقْرٍ. 8لَمْ تَطَأْهُ أَقْدَامُ الضَّوَارِي أَوْ يَسْلُكْ فِيهِ اللَّيْثُ. 9امْتَدَّتْ أَيْدِيهِمْ إِلَى الصَّوَّانِ، وَقَلَبُوا الْجِبَالَ مِنْ أُصُولِهَا. 10حَفَروا مَمَرَّاتٍ فِي صُخُورِهَا، وَعَايَنَتْ أَعْيُنُهُمْ كُلَّ ثَمِينٍ. 11سَدُّوا مَجَارِيَ الأَنْهَارِ، وَأَبْرَزُوا مَكْنُونَاتِ قِيعَانِهَا إِلَى النُّورِ.

12وَلَكِنْ أَيْنَ تُوجَدُ الْحِكْمَةُ؟ وَأَيْنَ مَقَرُّ الْفِطْنَةِ؟ 13لَا يُدْرِكُ الإِنْسَانُ قِيمَتَهَا، وَلا يُمْكِنُ أَنْ تُوجَدَ فِي أَرْضِ الأَحْيَاءِ. 14يَقُولُ الْغَمْرُ: لَيْسَتْ هِيَ فِيَّ؛ وَيَقُولُ الْبَحْرُ إِنِّي لَا أَمْلِكُهَا. 15لَا تُقَايَضُ بِالذَّهَبِ الْخَالِصِ، وَلا تُوْزَنُ الْفِضَّةُ ثَمَناً لَهَا. 16لَا تُثَمَّنُ بِذَهَبِ أُوفِيرَ أَوْ بِالْجَزْعِ الْكَرِيمِ أَوْ بِالْيَاقُوتِ الأَزْرَقِ. 17لَا يُعَادِلُهَا ذَهَبٌ أَوْ زُجَاجٌ، وَلا تُسْتَبْدَلُ بِمُجَوْهَرَاتٍ مِنَ الذَّهَبِ الْخَالِصِ. 18لَا يُذْكَرُ مَعَهَا الْمُرْجَانُ أَوِ الْبَلُّوْرُ، فَثَمَنُ الْحِكْمَةِ أَغْلَى مِنْ كُلِّ اللَّآلِئِ. 19لَا يُقَارَنُ بِها يَاقُوتُ كُوشٍ وَلا تُثَمَّنُ بِالذَّهَبِ النَّقِيِّ. 20إِذاً مِنْ أَيْنَ تَأْتِي الْحِكْمَةُ، وَأَيْنَ هُوَ مَقَرُّ الْفِطْنَةِ؟ 21إِنَّهَا مَحْجُوبَةٌ عَنْ عَيْنَيْ كُلِّ حَيٍّ، وَخَافِيَةٌ عَنْ طَيْرِ السَّمَاءِ. 22الْهَلاكُ وَالْمَوْتُ قَالا: قَدْ بَلَغَتْ مَسَامِعَنَا شَائِعَةٌ عَنْهَا. 23اللهُ وَحْدَهُ يَعْلَمُ الطَّرِيقَ إِلَيْهَا وَيَعْرِفُ مَقَرَّهَا، 24لأَنَّهُ يَرَى أَقْصَى الأَرْضِ وَيُحِيطُ بِجَمِيعِ مَا تَحْتَ السَّمَاوَاتِ. 25عِنْدَمَا جَعَلَ لِلرِّيحِ وَزْناً وَعَايَرَ الْمِيَاهَ بِمِقْيَاسٍ، 26عِنْدَمَا وَضَعَ سُنَناً لِلْمَطَرِ وَمَمَرّاً لِصَوَاعِقِ الرُّعُودِ، 27آنَئِذٍ رَآهَا وَأَذَاعَ خَبَرَهَا وَأَثْبَتَهَا وَفَحَصَهَا، 28ثُمَّ قَالَ لِلإِنْسَانِ: انْظُرْ، إِنَّ مَخَافَةَ الرَّبِّ هِيَ الْحِكْمَةُ، وَتَفَادِي الشَّرِّ هُوَ الْفِطْنَةُ».