Jobu 12 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 12:1-25

Ìdáhùn Jobu

1Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé:

2“Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà,

ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!

3Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin:

èmi kò kéré sí i yín:

àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?

4“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,

tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn:

à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà,

gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.

6Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù;

àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu,

àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.

7“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́,

àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

8Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ,

àwọn ẹja inú Òkun yóò sì sọ fún ọ.

9Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan

wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?

10Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà,

Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.

11Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí

tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?

12Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún,

àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.

13“Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára:

Òun ló ni ìmọ̀ àti òye.

14Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́;

Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.

15Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ;

Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.

16Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun;

Ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.

17Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò,

A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18Ó tú ìdè ọba,

Ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

19Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò,

Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

20Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò,

Ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.

21Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá,

Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.

22Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá,

Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.

23Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;

Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.

24Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé,

A sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.

25Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀,

Òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.

New International Version

Job 12:1-25

Job

1Then Job replied:

2“Doubtless you are the only people who matter,

and wisdom will die with you!

3But I have a mind as well as you;

I am not inferior to you.

Who does not know all these things?

4“I have become a laughingstock to my friends,

though I called on God and he answered—

a mere laughingstock, though righteous and blameless!

5Those who are at ease have contempt for misfortune

as the fate of those whose feet are slipping.

6The tents of marauders are undisturbed,

and those who provoke God are secure—

those God has in his hand.12:6 Or those whose god is in their own hand

7“But ask the animals, and they will teach you,

or the birds in the sky, and they will tell you;

8or speak to the earth, and it will teach you,

or let the fish in the sea inform you.

9Which of all these does not know

that the hand of the Lord has done this?

10In his hand is the life of every creature

and the breath of all mankind.

11Does not the ear test words

as the tongue tastes food?

12Is not wisdom found among the aged?

Does not long life bring understanding?

13“To God belong wisdom and power;

counsel and understanding are his.

14What he tears down cannot be rebuilt;

those he imprisons cannot be released.

15If he holds back the waters, there is drought;

if he lets them loose, they devastate the land.

16To him belong strength and insight;

both deceived and deceiver are his.

17He leads rulers away stripped

and makes fools of judges.

18He takes off the shackles put on by kings

and ties a loincloth12:18 Or shackles of kings / and ties a belt around their waist.

19He leads priests away stripped

and overthrows officials long established.

20He silences the lips of trusted advisers

and takes away the discernment of elders.

21He pours contempt on nobles

and disarms the mighty.

22He reveals the deep things of darkness

and brings utter darkness into the light.

23He makes nations great, and destroys them;

he enlarges nations, and disperses them.

24He deprives the leaders of the earth of their reason;

he makes them wander in a trackless waste.

25They grope in darkness with no light;

he makes them stagger like drunkards.