Joṣua 2 – YCB & PCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 2:1-24

Rahabu àti àwọn Ayọ́lẹ̀wò

12.1: Hb 11.31; Jk 2.25.Nígbà náà ni Joṣua ọmọ Nuni rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àṣírí láti Ṣittimu. Ó sì wí pé, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jeriko.” Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé panṣágà kan, tí à ń pè ní Rahabu wọ́n sì dúró síbẹ̀.

2A sì sọ fún ọba Jeriko, “Wò ó! Àwọn ará Israẹli kan wá ibí ní alẹ́ yìí láti wá yọ́ ilẹ̀ yí wò.” 3Ọba Jeriko sì ránṣẹ́ sí Rahabu pé: “Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá, tí ó wọ inú ilé rẹ jáde wá, nítorí wọ́n wá láti yọ́ gbogbo ilẹ̀ yìí wò ni.”

4Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “lóòtítọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá. 5Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò láti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.” 6(Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.) 7Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè.

8Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà. 9Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín. 10Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá. 11Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé. 12Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ̀yin yóò fún mi ní ààmì tó dájú: 13pé ẹ̀yin yóò dá ẹ̀mí baba àti ìyá mi sí; arákùnrin mi àti arábìnrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, àti pé ẹ̀yin yóò gbà wá là lọ́wọ́ ikú.”

14“Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín!” àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú. “Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà.”

15Nígbà náà ní ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ ní ojú u fèrèsé, nítorí ilé tí ó ń gbé wà ní ara odi ìlú. 16Ó sì ti sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí orí òkè, kí ẹ sì fi ara pamọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta kí àwọn tí ń lépa yín má ba à rí i yín títí tí wọn yóò fi darí. Lẹ́yìn náà kí ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ.”

17Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa ba à lè mọ́ kúrò nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí. 18Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò so okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ. 19Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án. 20Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.”

21Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.”

Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.

22Nígbà tí wọ́n kúrò, wọ́n sì lọ sí orí òkè wọ́n sì dúró ní ibẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn alépa fi wá wọn ní gbogbo ọ̀nà wọ́n sì padà láìrí wọn. 23Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin méjì náà padà. Wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ odò, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wọ́n sì sọ fún un gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn. 24Wọ́n sì sọ fún Joṣua, “Nítòótọ́ ni Olúwa tí fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́; gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ìbẹ̀rùbojo ti mú nítorí i wa.”

Persian Contemporary Bible

يوشع 2:1-24

يوشع جاسوسانی به اريحا می‌فرستد

1يوشع، دو جاسوس از شطيم به آن طرف رود اردن فرستاد تا وضعيت آن سرزمين و بخصوص شهر اريحا را بررسی كنند. وقتی آنها به آن شهر رسيدند، به خانهٔ فاحشه‌ای به نام راحاب رفتند تا شب را در آنجا بگذرانند. 2همان شب به پادشاه اريحا خبر رسيد كه چند جاسوس اسرائيلی وارد شهر شده‌اند.

3پادشاه افرادی را با اين پيغام نزد راحاب فرستاد: «مردانی را كه به خانهٔ تو آمده‌اند به ما تحويل بده، زيرا آنها جاسوس هستند.»

4اما راحاب كه آن دو مرد را پنهان كرده بود، گفت: «آنها پيش من آمدند، ولی نفهميدم چه كسانی بودند. 5هنگامی كه هوا تاريک شد، پيش از بسته شدن دروازه‌ها از شهر خارج شدند و من نمی‌دانم كجا رفتند. اگر به دنبال آنها بشتابيد می‌توانيد به ايشان برسيد.»

6ولی راحاب قبلاً آن دو مرد را به پشت بام برده، ايشان را زير توده‌ای از ساقه‌های كتان كه در آنجا گذاشته بود، مخفی كرده بود. 7پس مأمورانِ پادشاهِ اريحا در جستجوی آن دو نفر تا كرانهٔ رود اردن پيش رفتند. به مجرد اينكه آنها از شهر خارج شدند، دروازه‌های شهر را از پشت سر ايشان بستند. 8شب، پيش از آنكه آن دو مرد بخوابند، راحاب نزد ايشان به پشت بام رفت 9و به آنها گفت: «من شک ندارم كه خداوند، سرزمين ما را به شما خواهد داد. همهٔ ما از شما اسرائيلی‌ها می‌ترسيم. هر کس نام اسرائيل را می‌شنود از ترس می‌لرزد. 10چون شنيده‌ايم كه چگونه موقع خروج از مصر، خداوند از ميان دريای سرخ راه خشكی برای شما پديد آورد تا از آن بگذريد! خبر داريم كه به سيحون و عوج، پادشاهان اموری‌ها كه در طرف شرق اردن بودند، چه كرديد و چگونه آنها و مردمانشان را نابود ساختيد. 11وقتی اين خبرها را شنيديم، ترس وجود ما را فرا گرفت و جرأت خود را از دست داديم؛ زيرا خدای شما، خدای آسمان و زمين است و مانند او خدايی نيست. 12‏-13حال از شما می‌خواهم كه به نام خدايتان برای من قسم بخوريد و نشانه‌ای به من بدهيد كه وقتی شهر اريحا را تصرف نموديد، در ازای كمكی كه به شما كردم، مرا همراه پدر و مادر و خواهران و برادرانم و خانواده‌های آنها حفظ كنيد تا كشته نشويم.»

14آن دو مرد جواب دادند: «اگر در مورد ما با كسی سخن نگويی، به جان خود قسم می‌خوريم كه وقتی خداوند اين سرزمين را به ما داد، ترتيبی بدهيم كه به تو و بستگانت آسيبی نرسد.»

15خانهٔ راحاب بر حصار شهر قرار داشت، پس او آن دو مرد را با طناب از پنجرهٔ اتاقش پايين فرستاد. 16سپس به ايشان گفت: «به كوه فرار كنيد و سه روز در آنجا پنهان شويد تا مأمورانی كه به جستجوی شما رفته‌اند بازگردند. آنگاه می‌توانيد به راه خود ادامه دهيد.»

17‏-18آن دو نفر پيش از رفتن به او گفتند: «وقتی ما به اين شهر حمله كرديم، تو پدر و مادر و برادران و خواهران و خانواده‌های آنها را در خانهٔ خود جمع كن و اين طناب قرمز را به همين پنجره ببند. اگر اين كار را نكنی و آسيبی به شما برسد، ما در برابر قسمی كه خورده‌ايم مسئول نخواهيم بود. 19اگر كسی از خانه بيرون برود، خونش به گردن خودش است و ما مسئول مرگش نخواهيم بود. ما قسم می‌خوريم كسانی كه در اين خانه بمانند كشته نشوند و به ايشان كوچكترين آسيبی نرسد. 20اما اگر تو دربارهٔ ما با كسی سخن بگويی، اين قسم باطل می‌شود.»

21راحاب گفت: «آنچه را كه گفتيد می‌پذيرم.» سپس ايشان را روانه كرد و طناب قرمز را به پنجره بست. 22آن دو به كوه رفتند و سه روز در آنجا ماندند. تعقيب‌كنندگان همهٔ راهها را جستجو كردند و چون ايشان را نيافتند، ناچار به شهر بازگشتند. 23آنگاه آن دو نفر از كوه به زير آمده، از رود اردن عبور نمودند و نزد يوشع بازگشتند و آنچه برايشان اتفاق افتاده بود به او گزارش دادند.

24آنها به يوشع گفتند: «اطمينان داريم كه خداوند تمام آن سرزمين را به ما بخشيده است، زيرا مردم آنجا از ترس ما روحيهٔ خود را باخته‌اند!»