Isaiah 66 – YCB & JCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 66:1-24

Ìdájọ́ àti ìrètí

166.1-2: Mt 5.34; Ap 7.49-50.Báyìí ni Olúwa wí:

“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,

ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi,

Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?

Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

2Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,

bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”

ni Olúwa wí.

“Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:

ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,

tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.

3Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ

ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan

àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ,

dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn;

ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ

dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,

ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí,

dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà.

Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n,

ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;

4Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn

n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.

Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,

nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀.

Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi

wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”

5Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,

Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:

“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,

tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,

‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,

kí a le rí ayọ̀ yín!’

Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.

666.6: If 16.1,17.Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,

gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!

Ariwo tí Olúwa ní í ṣe

tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun

tí ó tọ́ sí wọn.

766.7: If 12.5.“Kí ó tó lọ sí ìrọbí,

ó ti bímọ;

kí ó tó di pé ìrora dé bá a,

ó ti bí ọmọkùnrin.

8Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?

Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?

Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan

tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?

Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí

bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.

9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí

kí èmi má sì mú ni bí?”

ni Olúwa wí.

“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ

nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”

Ni Ọlọ́run yín wí.

10“Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,

gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;

ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,

gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.

11Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn

nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára;

Ẹ̀yin yóò mu àmuyó

ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”

12Nítorí báyìí ni Olúwa wí:

“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò

àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;

ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀

a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.

13Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,

bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú

a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”

14Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn

ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;

ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,

ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná

àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;

òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,

àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.

16Nítorí pẹ̀lú iná àti idà

ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,

àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.

17“Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.

18“Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.

19“Èmi yóò sì gbé ààmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. 20Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́. 21Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni Olúwa wí.

2266.22: Isa 65.17; 2Pt 3.13; If 21.1.“Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé. 23Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí. 2466.24: Mk 9.48.“Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”

Japanese Contemporary Bible

イザヤ書 66:1-24

66

さばきと希望

1「天はわたしの王座、地はわたしの足台だ。

あなたがたにこれ以上の神殿を

建てることができようか。

2わたしはこの手で天と地を造った。

全部がわたしのものだ。

それでもわたしは、

謙遜になって深く罪を悔い、

わたしのことばにおののく者に目をかける。

3しかし、自分勝手な道を選び、

罪にふける者はのろわれる。

彼らのささげ物を、わたしは絶対に受け入れない。

たとえ牛を祭壇にささげても、見向きもしない。

子羊や穀物をささげても、

犬や豚の血を供えたときのように、顔をしかめる。

わたしに香をたいているつもりでも、

偶像を拝んでいるのだとみなす。

4わたしは彼らに、彼らが恐れているものを送る。

わたしが呼んだのに答えようとせず、

話しかけたのに聞こうともしなかったからだ。

それどころか、わたしの見ている前で悪いことをし、

わたしが憎むことを、

そうと知りながら行った。

5神を恐れる者は、神のことばを聞いておののけ。

あなたがたの同胞は、わたしに忠実だというだけで、

あなたがたを憎み、退ける。

『神に栄光があるように。主を信じて、

せいぜい幸せになるがいい』と彼らはあざける。

だが、そう言う彼らが恥を見るようになる。」

6町が騒ぎ立っています。

いったいどうしたというのでしょう。

神殿から聞こえてくる、

あのすさまじい物音は何でしょう。

あれは、主が敵に報復している音です。

7-8こんなに不思議なことを見聞きした者が

いるでしょうか。

まだ産みの苦しみの前に、一日のうちに、

突然、イスラエルの国が産み落とされるのです。

陣痛が始まると同時に、

赤ん坊が生まれ、国が出現するのです。

9「わたしは胎を開かせておきながら、

産ませないことがあろうか」

と、あなたの神である主は言います。

そんなことは、天地がひっくり返っても、

あるはずがありません。

10エルサレムを愛し、そのために嘆いてきた者よ、

エルサレムといっしょに喜び、楽しめ。

11エルサレムをこの上もない喜びとせよ。

赤ん坊が母親の豊かな乳房を吸うように、

エルサレムの栄光を堪能するまで飲め。

12主は告げます。

「繁栄が川のようにエルサレムにみなぎりあふれる。

わたしがそのようにするからだ。

外国の富はこの都に流れ込む。

子どもたちはエルサレムの乳房を吸い、

わきに抱かれ、ひざの上であやされる。

13わたしはその都で、幼児が母親に慰められるように、

あなたがたを慰める。

14あなたがたはエルサレムを見て心を躍らせる。

あなたがたのからだは力が満ちる。

すべての人が、

神の民に加えられた主の恵み深い御手と、

敵に向けられた主の憤りとを見る。」

15見よ。神は怒りをぶちまけ、激しく責めたてるために、

火に包まれ、すべてのものを破壊する

速い戦車に乗って来ます。

16火と剣で、世界をさばくのです。

主に殺される者が、いかに多いことでしょう。

17主は告げます。

「庭の木のうしろに隠してある偶像をこっそり拝み、

そこで豚の肉やねずみ、その他の禁じられている物を

おいしそうに食べる者はみな、悲惨な最期を迎える。

18わたしには、彼らが何をしようとしているか、すべてわかっている。何を考えているかも知っている。そこで、すべての国の人々をエルサレムの前に集め、わたしの栄光を見せる。 19彼らの目の前で驚くような奇跡をして見せ、逃れた者を宣教師として諸国に送る。行く先は、タルシシュ、プル、ルデ、メシェク、ロシュ、トバル、ヤワン(ギリシヤ)、それに、わたしの評判を耳にしたこともなく、わたしの栄光を見たこともない、海の向こうの国々だ。こうして、わたしの栄光を外国人に告げ知らせる。 20彼らは、すべての国々から、あなたがたの同胞を神への贈り物として、馬、車、かご、らば、らくだに乗せ、わたしの聖なる山エルサレムへ大切に運んで来る。ちょうど刈り入れの時期に、主のものとしてきよめた器に供え物を載せ、続々と神殿へ運び込むのと同じように。 21こうして帰って来た者の中から、わたしは祭司とレビ人を選び出す。」

主はそう告げます。

22「わたしの造る新しい天と地がいつまでも残るように。

あなたがたはいつまでもわたしの民となり、

あなたがたに与えられる名は永久にすたれない。

23すべての者が、週ごとに、また月ごとに、

わたしを礼拝するために来る。

24彼らは出て行って、

わたしに背いた者たちのしかばねを見る。

それにわいたうじはいつまでも死なず、

しかばねを焼く火も消えず、

すべての人が目をそむける。」