Hagai 2 – YCB & NIVUK

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Hagai 2:1-23

Ẹwà Tẹmpili tuntun náà

1Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai wí pé: 2“Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 3‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín? 4Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni Olúwa wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà;’ ni Olúwa wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 5‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’

6“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. 7Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 8‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Ìbùkún fún àwọn ènìyàn tí a sọ di àìmọ́

10Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hagai wá pé: 11“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé: 12Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”

Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

13Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”

Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”

14Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.

15“ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili Olúwa. 16Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òṣùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀. 17Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 18‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa lélẹ̀, rò ó dáradára: 19Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan.

“ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”

Serubbabeli òrùka èdìdì Olúwa

20Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé: 21“Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé. 22Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”

23Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

New International Version – UK

Haggai 2:1-23

1on the twenty-first day of the seventh month, the word of the Lord came through the prophet Haggai: 2‘Speak to Zerubbabel son of Shealtiel, governor of Judah, to Joshua son of Jozadak,2:2 Hebrew Jehozadak, a variant of Jozadak; also in verse 4 the high priest, and to the remnant of the people. Ask them, 3“Who of you is left who saw this house in its former glory? How does it look to you now? Does it not seem to you like nothing? 4But now be strong, Zerubbabel,” declares the Lord. “Be strong, Joshua son of Jozadak, the high priest. Be strong, all you people of the land,” declares the Lord, “and work. For I am with you,” declares the Lord Almighty. 5“This is what I covenanted with you when you came out of Egypt. And my Spirit remains among you. Do not fear.”

6‘This is what the Lord Almighty says: “In a little while I will once more shake the heavens and the earth, the sea and the dry land. 7I will shake all nations, and what is desired by all nations will come, and I will fill this house with glory,” says the Lord Almighty. 8“The silver is mine and the gold is mine,” declares the Lord Almighty. 9“The glory of this present house will be greater than the glory of the former house,” says the Lord Almighty. “And in this place I will grant peace,” declares the Lord Almighty.’

Blessings for a defiled people

10On the twenty-fourth day of the ninth month, in the second year of Darius, the word of the Lord came to the prophet Haggai: 11‘This is what the Lord Almighty says: “Ask the priests what the law says: 12if someone carries consecrated meat in the fold of their garment, and that fold touches some bread or stew, some wine, olive oil or other food, does it become consecrated?” ’

The priests answered, ‘No.’

13Then Haggai said, ‘If a person defiled by contact with a dead body touches one of these things, does it become defiled?’

‘Yes,’ the priests replied, ‘it becomes defiled.’

14Then Haggai said, ‘ “So it is with this people and this nation in my sight,” declares the Lord. “Whatever they do and whatever they offer there is defiled.

15‘ “Now give careful thought to this from this day on2:15 Or to the days past – consider how things were before one stone was laid on another in the Lord’s temple. 16When anyone came to a heap of twenty measures, there were only ten. When anyone went to a wine vat to draw fifty measures, there were only twenty. 17I struck all the work of your hands with blight, mildew and hail, yet you did not return to me,” declares the Lord. 18“From this day on, from this twenty-fourth day of the ninth month, give careful thought to the day when the foundation of the Lord’s temple was laid. Give careful thought: 19is there yet any seed left in the barn? Until now, the vine and the fig-tree, the pomegranate and the olive tree have not borne fruit.

‘ “From this day on I will bless you.” ’

Zerubbabel the Lord’s signet ring

20The word of the Lord came to Haggai a second time on the twenty-fourth day of the month: 21‘Tell Zerubbabel governor of Judah that I am going to shake the heavens and the earth. 22I will overturn royal thrones and shatter the power of the foreign kingdoms. I will overthrow chariots and their drivers; horses and their riders will fall, each by the sword of his brother.

23‘ “On that day,” declares the Lord Almighty, “I will take you, my servant Zerubbabel son of Shealtiel,” declares the Lord, “and I will make you like my signet ring, for I have chosen you,” declares the Lord Almighty.’