Hagai 1 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Hagai 1:1-15

Ìpè láti tún ilé Olúwa kọ́

1Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.

2Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé Olúwa.’ ”

3Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé: 4“Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnrayín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”

5Ní ṣinṣin yìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 6Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”

7Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 8Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí. 9“Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀. 10Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde. 11Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”

12Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa.

13Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí. 14Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn, 15ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

哈該書 1:1-15

耶和華命令百姓重建聖殿

1大流士王執政第二年六月一日,耶和華藉著先知哈該撒拉鐵的兒子猶大省長所羅巴伯約撒答的兒子大祭司約書亞說:

2「萬軍之耶和華說,『這些百姓說,重建耶和華殿的時候還沒到。』」 3因此,耶和華對先知哈該說: 4「這殿還是一片廢墟,你們卻住在華麗的房子裡。 5萬軍之耶和華說,你們要認真反省自己的行為。 6你們種多收少,吃不飽,喝不足,穿不暖,掙來的工錢卻放在漏口袋中。」

7萬軍之耶和華說:「你們要認真反省自己的行為。 8你們要上山伐木,重建這殿,好讓我歡喜並得到尊崇。這是耶和華說的。 9你們盼望豐收,結果收的很少;你們把收成帶回家,我卻把它們吹走。這是什麼緣故?萬軍之耶和華告訴你們,『因為你們都忙於建自家的房子,任由我的殿一片廢墟。 10所以,天不降雨露,地無出產。 11我讓旱災臨到大地、群山、五穀、葡萄、橄欖等地裡的出產以及人畜,使你們一切的勞碌付諸東流。』」

12撒拉鐵的兒子猶大省長所羅巴伯約撒答的兒子大祭司約書亞和所有的餘民1·12 餘民」指「從流亡之地歸回的人」。聽到他們的上帝耶和華藉先知哈該所講的話,都順服耶和華的話。百姓都敬畏耶和華。 13耶和華的使者哈該向百姓傳達耶和華的話,說:「耶和華說,『我與你們同在。』」 14耶和華感動撒拉鐵的兒子猶大省長所羅巴伯約撒答的兒子大祭司約書亞和所有的餘民,他們就動工建造他們的上帝萬軍之耶和華的殿, 15時值大流士王執政第二年六月二十四日。