Habakuku 3 – YCB & NIVUK

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Habakuku 3:1-19

Àdúrà Habakuku

1Àdúrà wòlíì Habakuku gẹ́gẹ́ bí sígónótì. Ohun èlò orin.

2Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ;

ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa

sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,

ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀;

ni ìbínú, rántí àánú.

3Ọlọ́run yóò wa láti Temani,

ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Parani

ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,

ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ

4Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn

ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ,

níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ;

ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

6Ó dúró, ó sì mi ayé;

ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì

a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká,

àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba:

ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

7Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú

àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.

8Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa?

Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí?

Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun

tí ìwọ fi ń gun ẹṣin,

àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?

9A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá,

gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ,

ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.

10Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì

àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ;

ibú ń ké ramúramù

ó sì gbé irú omi sókè.

11Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn,

pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ,

àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

12Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,

ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.

13Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,

àti láti gba ẹni ààmì òróró rẹ là;

Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,

ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀

14Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ

nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀

jáde láti tú wá ká:

ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.

15Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,

ó sì da àwọn omi ńlá ru.

16Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,

ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;

ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,

ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,

mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú

láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.

17Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,

tí èso kò sí nínú àjàrà;

tí igi olifi ko le so,

àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;

tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,

tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,

18síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,

èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.

19Olúwa Olódùmarè ni agbára mi,

òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín,

yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.

New International Version – UK

Habakkuk 3:1-19

Habakkuk’s prayer

1A prayer of Habakkuk the prophet. On shigionoth.3:1 Probably a literary or musical term

2Lord, I have heard of your fame;

I stand in awe of your deeds, Lord.

Repeat them in our day,

in our time make them known;

in wrath remember mercy.

3God came from Teman,

the Holy One from Mount Paran.3:3 The Hebrew has Selah (a word of uncertain meaning) here and at the middle of verse 9 and at the end of verse 13.

His glory covered the heavens

and his praise filled the earth.

4His splendour was like the sunrise;

rays flashed from his hand,

where his power was hidden.

5Plague went before him;

pestilence followed his steps.

6He stood, and shook the earth;

he looked, and made the nations tremble.

The ancient mountains crumbled

and the age-old hills collapsed –

but he marches on for ever.

7I saw the tents of Cushan in distress,

the dwellings of Midian in anguish.

8Were you angry with the rivers, Lord?

Was your wrath against the streams?

Did you rage against the sea

when you rode your horses

and your chariots to victory?

9You uncovered your bow,

you called for many arrows.

You split the earth with rivers;

10the mountains saw you and writhed.

Torrents of water swept by;

the deep roared

and lifted its waves on high.

11Sun and moon stood still in the heavens

at the glint of your flying arrows,

at the lightning of your flashing spear.

12In wrath you strode through the earth

and in anger you threshed the nations.

13You came out to deliver your people,

to save your anointed one.

You crushed the leader of the land of wickedness,

you stripped him from head to foot.

14With his own spear you pierced his head

when his warriors stormed out to scatter us,

gloating as though about to devour

the wretched who were in hiding.

15You trampled the sea with your horses,

churning the great waters.

16I heard and my heart pounded,

my lips quivered at the sound;

decay crept into my bones,

and my legs trembled.

Yet I will wait patiently for the day of calamity

to come on the nation invading us.

17Though the fig-tree does not bud

and there are no grapes on the vines,

though the olive crop fails

and the fields produce no food,

though there are no sheep in the sheepfold

and no cattle in the stalls,

18yet I will rejoice in the Lord,

I will be joyful in God my Saviour.

19The Sovereign Lord is my strength;

he makes my feet like the feet of a deer,

he enables me to tread on the heights.