Galatia 3 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Galatia 3:1-29

Ìgbàgbọ́ tàbí iṣẹ́ òfin

1Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 2Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? 3Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? 4Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. 5Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? 63.6: Gẹ 15.6; Ro 4.3.Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”

7Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu. 83.8: Gẹ 12.3; 18.18; Ap 3.25.Bí ìwé mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìhìnrere ṣáájú fún Abrahamu, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” 93.9: Ro 4.16.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo.

103.10: De 27.26.Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n. 113.11: Hk 2.4; Ro 1.17; Hb 10.38.Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” 123.12: Le 18.5; Ro 10.5.Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 133.13: De 21.23.Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” 14Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.

Òfin àti ìlérí

15Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. 163.16: Gẹ 12.7.Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣe wí pé, Fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀, bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kristi. 173.17: Ek 12.40.Èyí tí mò ń wí ni pé: májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣàájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, kí ó sì mú ìlérí náà di aláìlágbára. 183.18: Ro 11.6.Nítorí bí ogún náà bá dúró lórí ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí í òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Abrahamu nípa ìlérí.

193.19: Ro 5.20.Ǹjẹ́ kí ha ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipasẹ̀ àwọn angẹli ṣe ìlànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá. 20Ǹjẹ́ onílàjà kì í ṣe alárinà ti ẹnìkan, ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.

213.21: Ro 8.2-4.Nítorí náà òfin ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọ ni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà. 223.22: Ro 3.9-19; 11.32.Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ti fi yé wa pé gbogbo ènìyàn ni ń bẹ lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fihàn. 24Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́. 25Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùtọ́jú mọ́.

Ọmọ Ọlọ́run

26Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 27Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti bamitiisi sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀. 283.28: Ro 10.12.Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. 29Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

King James Version

Galatians 3:1-29

1O foolish Galatians, who hath bewitched you, that ye should not obey the truth, before whose eyes Jesus Christ hath been evidently set forth, crucified among you? 2This only would I learn of you, Received ye the Spirit by the works of the law, or by the hearing of faith? 3Are ye so foolish? having begun in the Spirit, are ye now made perfect by the flesh? 4Have ye suffered so many things in vain? if it be yet in vain. 5He therefore that ministereth to you the Spirit, and worketh miracles among you, doeth he it by the works of the law, or by the hearing of faith? 6Even as Abraham believed God, and it was accounted to him for righteousness.

7Know ye therefore that they which are of faith, the same are the children of Abraham. 8And the scripture, foreseeing that God would justify the heathen through faith, preached before the gospel unto Abraham, saying, In thee shall all nations be blessed. 9So then they which be of faith are blessed with faithful Abraham. 10For as many as are of the works of the law are under the curse: for it is written, Cursed is every one that continueth not in all things which are written in the book of the law to do them. 11But that no man is justified by the law in the sight of God, it is evident: for, The just shall live by faith. 12And the law is not of faith: but, The man that doeth them shall live in them. 13Christ hath redeemed us from the curse of the law, being made a curse for us: for it is written, Cursed is every one that hangeth on a tree: 14That the blessing of Abraham might come on the Gentiles through Jesus Christ; that we might receive the promise of the Spirit through faith. 15Brethren, I speak after the manner of men; Though it be but a man’s covenant, yet if it be confirmed, no man disannulleth, or addeth thereto. 16Now to Abraham and his seed were the promises made. He saith not, And to seeds, as of many; but as of one, And to thy seed, which is Christ. 17And this I say, that the covenant, that was confirmed before of God in Christ, the law, which was four hundred and thirty years after, cannot disannul, that it should make the promise of none effect. 18For if the inheritance be of the law, it is no more of promise: but God gave it to Abraham by promise. 19Wherefore then serveth the law? It was added because of transgressions, till the seed should come to whom the promise was made; and it was ordained by angels in the hand of a mediator. 20Now a mediator is not a mediator of one, but God is one. 21Is the law then against the promises of God? God forbid: for if there had been a law given which could have given life, verily righteousness should have been by the law. 22But the scripture hath concluded all under sin, that the promise by faith of Jesus Christ might be given to them that believe.

23But before faith came, we were kept under the law, shut up unto the faith which should afterwards be revealed. 24Wherefore the law was our schoolmaster to bring us unto Christ, that we might be justified by faith. 25But after that faith is come, we are no longer under a schoolmaster. 26For ye are all the children of God by faith in Christ Jesus. 27For as many of you as have been baptized into Christ have put on Christ. 28There is neither Jew nor Greek, there is neither bond nor free, there is neither male nor female: for ye are all one in Christ Jesus. 29And if ye be Christ’s, then are ye Abraham’s seed, and heirs according to the promise.