Gẹnẹsisi 15 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 15:1-21

Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Abramu

1Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Abramu wá lójú ìran pé:

“Abramu má ṣe bẹ̀rù,

Èmi ni ààbò rẹ,

Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”

2Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” 3Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”

415.4: Gẹ 17.16,21; 18.10; 21.2.Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” 515.5: Ro 4.18; Hb 11.12.Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”

615.6: Ro 4.3; Ga 3.6; Jk 2.23.Abramu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

7Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”

8Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”

9Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

10Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. 11Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.

1215.12: Jb 4.13,14.Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. 1315.13: Ek 1.1-14; Ap 7.6.15.13-14: Ek 12.40,41; Ap 7.7.Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irínwó ọdún (400). 14Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. 15Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. 16Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”

17Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. 1815.18: Gẹ 17.2,7,9-14,21.Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: 19ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, 20àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. 21Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”

King James Version

Genesis 15:1-21

1After these things the word of the LORD came unto Abram in a vision, saying, Fear not, Abram: I am thy shield, and thy exceeding great reward.

2And Abram said, Lord GOD, what wilt thou give me, seeing I go childless, and the steward of my house is this Eliezer of Damascus? 3And Abram said, Behold, to me thou hast given no seed: and, lo, one born in my house is mine heir. 4And, behold, the word of the LORD came unto him, saying, This shall not be thine heir; but he that shall come forth out of thine own bowels shall be thine heir. 5And he brought him forth abroad, and said, Look now toward heaven, and tell the stars, if thou be able to number them: and he said unto him, So shall thy seed be. 6And he believed in the LORD; and he counted it to him for righteousness.

7And he said unto him, I am the LORD that brought thee out of Ur of the Chaldees, to give thee this land to inherit it. 8And he said, Lord GOD, whereby shall I know that I shall inherit it? 9And he said unto him, Take me an heifer of three years old, and a she goat of three years old, and a ram of three years old, and a turtledove, and a young pigeon. 10And he took unto him all these, and divided them in the midst, and laid each piece one against another: but the birds divided he not. 11And when the fowls came down upon the carcases, Abram drove them away.

12And when the sun was going down, a deep sleep fell upon Abram; and, lo, an horror of great darkness fell upon him. 13And he said unto Abram, Know of a surety that thy seed shall be a stranger in a land that is not theirs, and shall serve them; and they shall afflict them four hundred years; 14And also that nation, whom they shall serve, will I judge: and afterward shall they come out with great substance. 15And thou shalt go to thy fathers in peace; thou shalt be buried in a good old age. 16But in the fourth generation they shall come hither again: for the iniquity of the Amorites is not yet full.

17And it came to pass, that, when the sun went down, and it was dark, behold a smoking furnace, and a burning lamp that passed between those pieces.15.17 a burning…: Heb. a lamp of fire 18In the same day the LORD made a covenant with Abram, saying, Unto thy seed have I given this land, from the river of Egypt unto the great river, the river Euphrates: 19The Kenites, and the Kenizzites, and the Kadmonites, 20And the Hittites, and the Perizzites, and the Rephaims, 21And the Amorites, and the Canaanites, and the Girgashites, and the Jebusites.