Esteri 3 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esteri 3:1-15

Ọ̀tẹ̀ Hamani láti pa àwọn Júù run

1Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. 2Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un.

3Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” 4Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.

5Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. 6Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi.

7Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari.

8Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. 9Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.”

10Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. 11Ọba sọ fún Hamani pé, “pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”

12Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnrarẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀. 13A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn. 14Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.

15Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

以斯帖記 3:1-15

哈曼圖謀滅絕猶太人

1後來,亞哈隨魯王擢升亞甲哈米大他的兒子哈曼,使他的權位高過他所有的同僚。 2王命令所有在宮門供職的臣僕都要向哈曼跪拜,但末底改不肯跪拜。 3在宮門供職的臣僕問末底改:「你為何違抗王的命令?」 4他們天天勸他,他卻不聽。他們便把這件事告訴哈曼,想看看末底改這樣做是否能站得住,因為末底改已告訴他們自己是猶太人。 5哈曼末底改不肯向他跪拜,就怒氣填胸。 6他得知末底改猶太人後,便不屑於只害末底改一人,而是要剷除亞哈隨魯王國內所有的猶太人,即末底改的同胞。

7亞哈隨魯王十二年一月,即尼散月,有人在哈曼面前抽普珥,也就是抽籤,來決定哪月哪日下手,結果抽中十二月,即亞達月。

8哈曼亞哈隨魯王說:「有一個民族散居在王境內各省的眾民族中,他們的律例與各族的律例不同,他們不遵守王的律例,所以容忍他們對王不利。 9王若願意,就請降旨消滅他們。我願捐三百四十五噸銀子交給管理國事的人,納入王的庫房。」 10於是,王摘下手上的戒指,交給猶太人的仇敵——亞甲哈米大他的兒子哈曼11對他說:「這些銀子歸你,這個民族也交給你,隨你處置。」

12一月十三日,王的書記被召來,他們以亞哈隨魯王的名義,照哈曼的吩咐,用各省的文字和各族的語言寫諭旨,用王的戒指蓋印,送交各總督、各省省長和各族首領。 13諭旨由信差送到王的各省,限令在一天之內,即十二月,也就是亞達月十三日,把猶太人的男女老少全部剷除、殺光、滅盡,並奪取他們的財物。 14諭旨的抄本作為法令頒佈到各省,通知各族為那天做好準備。 15信差奉王的命令急忙上路,諭旨也在書珊城裡頒佈了。王和哈曼坐下飲酒,書珊城一片慌亂。