Esekiẹli 48 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 48:1-35

Pínpín ilẹ̀ náà

1“Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn:

“Ní òpin àríwá, Dani yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hetiloni lọ sí Lebo-Hamati; Hasari-Enani àti ààlà àríwá tí Damasku tí ó kángun sí Hamati yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà-oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn.

2Aṣeri yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbègbè Dani láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

3Naftali yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Aṣeri láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

4Manase yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbègbè Naftali láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

5Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

6Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn.

7Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

8“Ní agbègbè Juda, láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn ni yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Èyí tí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní ìbú, gígùn rẹ̀ láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ bákan náà bí ọ̀kan nínú àwọn ìpín ìyókù; láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi mímọ́ yóò sì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀.

9“Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fi fún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 10Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà. Èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúúsù. Ní àárín gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà. 11Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn ọmọ Sadoku tí wọn jẹ́ olóòtítọ́ nínú sí sìn mí, tiwọn kò sì ṣáko lọ bí ti àwọn Lefi ṣe ṣe nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ. 12Èyí yóò jẹ́ ọrẹ pàtàkì fún wọn láti ara ìpín ibi mímọ́ ilẹ̀ náà, ìpín tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, tí ó jẹ́ ààlà agbègbè àwọn Lefi.

13“Ní àkọjúsí agbègbè àwọn àlùfáà, àwọn Lefi yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹẹdọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, àti inú rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. 14Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí pààrọ̀ ọ̀kankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ̀ náà, a kò sì gbọdọ̀ fi fún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.

15“Agbègbè tí o ṣẹ́kù, tí ń ṣe ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, yóò jẹ́ ibi àìmọ́ fun ìlú ńlá náà fún ilé gbígbé àti fún agbègbè: Ìlú ńlá náà yóò wà ní àárín rẹ̀, 1648.16: If 21.16.Ìwọ̀nyí sì níbi a ṣe wọ́n ọ́n: ní ìhà àríwá ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ni ìhà gúúsù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ní ìhà ìlà-oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́. 17Ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn fún ìlú ńlá náà yóò jẹ igba àti àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúúsù, ìgbà àti ìgbà pẹ̀lú àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. 18Èyí tí ó kù ní agbègbè náà, tí ó jẹ́ àkọjúsí ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlú ńlá náà. 19Àwọn òṣìṣẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dá oko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli. 20Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà.

21“Èyí tí ó ṣẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbègbè tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Èyí yóò lọ títí dé ìhà ìlà-oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà-oòrùn. Agbègbè méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹmpili yóò wa ní àárín wọn. 22Ilẹ̀ ìní àwọn Lefi àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárín agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé yóò wà ní àárín ààlà tí Juda àti ààlà tí Benjamini.

23“Ní ti àwọn ẹ̀yà tí ó kù:

“Benjamini yóò ní ìpín kan; èyí yóò wà láti ìhà ìlà-oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀-oòrùn.

24Simeoni yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Benjamini láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

25Isakari yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Simeoni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

26Sebuluni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Isakari láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

27Gadi yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Sebuluni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

28Ààlà tí gúúsù Gadi yóò dé gúúsù láti Tamari lọ sí odò Meriba Kadeṣi lẹ́yìn náà títí dé odo ti Ejibiti lọ sí Òkun ńlá fún àwọn ẹ̀yà Israẹli, ìwọ̀nyí ní yóò sì jẹ́ ìpín wọn” ní Olúwa Ọlọ́run wí.

29“Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi ìbò pín ní ogún fún àwọn ẹ̀yà Israẹli, wọ̀nyí sì ni ìpín wọn,” ní Olúwa Olódùmarè wí.

Àwọn ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà

30“Ìwọ̀nyí ní yóò jẹ́ ẹnu-ọ̀nà àbájáde ìlú ńlá náà:

“Bẹ̀rẹ̀ láti ìhà àríwá, ti ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, 3148.31-35: If 21.12-13.ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli pè. Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Reubeni, ọ̀nà tí Juda ọ̀nà tí Lefi.

32Ní ìhà ìlà-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ni ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ọ̀nà Josẹfu, ọ̀nà tí Benjamini àti ọ̀nà tí Dani.

33Ní ìhà gúúsù, èyí tí wíwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Simeoni, ojú ọ̀nà Isakari àti ojú ọ̀nà Sebuluni.

34Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Gadi, ojú ọ̀nà Aṣeri àti ojú ọ̀nà Naftali.

35“Jíjìnnà rẹ̀ yípo yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì-dínlógún (18,000) ìgbọ̀nwọ́.

“Orúkọ ìlú náà láti ìgbà náà yóò jẹ́: ‘Olúwa wà níbẹ̀.’ ”

New Amharic Standard Version

ሕዝቅኤል 48:1-35

የምድሪቱ አከፋፈል

1“ስማቸው የተዘረዘረው ነገዶች እነዚህ ናቸው፤

“በሰሜኑ ድንበር የዳን ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የሔትሎንን መንገድ ተከትሎ እስከ ሐማት መተላለፊያ ይደርሳል። ሐጸርዔናንና ከሐማት ቀጥሎ ያለው የደማስቆ ሰሜናዊ ድንበር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ላለው ወሰኑ አንድ ክፍል ይሆናል።

2የአሴር ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የዳንን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

3የንፍታሌም ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የአሴርን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

4የምናሴ ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የንፍታሌምን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

5የኤፍሬም ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የምናሴን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

6የሮቤል ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የኤፍሬምን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

7የይሁዳ ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የሮቤልን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

8“ይሁዳን ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ የሚያዋስነው ምድር ለመባ የሚቀርብ ድርሻ ይሆናል፤ ስፋቱም ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ነው፤ ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያለውም ርዝመቱ፣ ከነገዶቹ ድርሻ እንደ አንዱ ሆኖ፣ መቅደሱ በመካከሉ ይሆናል።

9ለእግዚአብሔር የምታቀርቡት የዚህ መባ ርዝመት ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ሲሆን፣ ስፋቱ ዐሥር ሺሕ ክንድ ይሆናል። 10ይህ ለካህናቱ የተቀደሰ ድርሻ ይሆናል፤ በሰሜን በኩል ርዝመቱ ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ፣ በምዕራብ በኩል ወርዱ ዐሥር ሺሕ ክንድ በምሥራቅ በኩል ወርዱ ዐሥር ሺሕ ክንድ ሲሆን፣ በደቡብ በኩል ርዝመቱ ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ይሆናል፤ የእግዚአብሔርም መቅደስ በመካከሉ ይቆማል። 11ይህም እስራኤላውያን በሳቱ ጊዜ፣ እንደ ሳቱት ሌዋውያን ሳይስቱ ለቀሩት፣ በታማኝነት ላገለገሉኝ ለተቀደሱት ካህናት ለሳዶቃውያን ይሆናል። 12የሌዋውያንን ምድር ከሚያዋስነው፣ ከምድሪቱ ቅዱስ ድርሻ እጅግ የተቀደሰው ድርሻ ለእነርሱ ልዩ ስጦታ ይሆናል።

13“ከካህናቱም ምድር ጐን ለጐን ሌዋውያኑ ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ርዝመትና ዐሥር ሺሕ ክንድ ወርድ ያለው ይዞታ ይኖራቸዋል፤ ጠቅላላ ርዝመቱ ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ፣ ወርዱም ዐሥር ሺሕ ክንድ ይሆናል። 14ከዚህ ላይ መሸጥ ወይም መለወጥ የለባቸውም። ይህ ከምድሪቱ ሁሉ ምርጥ ስለሆነ፣ ወደ ሌላ እጅ አይተላለፍም፤ ለእግዚአብሔር የተቀደሰ ነውና።

15“አምስት ሺሕ ክንድ ወርድና ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ርዝመት ያለው የቀረው ቦታ ለከተማዪቱ የጋራ ጥቅም፣ ለቤት ሥራና ለከብት ማሰማሪያ ይውላል፤ ከተማዪቱም በመካከሉ ትሆናለች፤ 16የከተማዪቱም መጠን በሰሜን አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ፣ በደቡብ አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ፣ በምሥራቅ አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ፣ የምዕራቡም እንዲሁ አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ ይሆናል። 17የከተማዪቱ ከብት ማሰማሪያ ቦታ፣ በሰሜን ሁለት መቶ አምሳ ክንድ፣ በደቡብ ሁለት መቶ አምሳ ክንድ፣ በምሥራቅ ሁለት መቶ አምሳ ክንድ፣ በምዕራብም ሁለት መቶ አምሳ ክንድ ይሆናል። 18ከዚህ የሚቀረው፣ የተቀደሰውን ክፍል የሚያዋስነውና በተጓዳኝ ያለው ቦታ በምሥራቅ ዐሥር ሺሕ ክንድ፣ በምዕራብ ዐሥር ሺሕ ክንድ ይሆናል። ምርቱም ለከተማዪቱ ሠራተኞች ምግብ ይሆናል። 19ምድሪቱን የሚያርሱ የከተማዪቱ ሠራተኞች ከሁሉም ነገዶች ይመጣሉ። 20አጠቃላይ ይዞታው በአራቱም ማእዘን እኩል ሲሆን፣ እያንዳንዱ ማእዘን ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ነው፤ ከከተማዪቱ ድርሻ ጋር የተቀደሰውን ክፍል ልዩ መባ በማድረግ ታስቀምጣላችሁ።

21“በተቀደሰው ድርሻና በከተማዪቱ ቦታ ግራና ቀኝ ያለው ቀሪ ቦታ፣ ለገዥው ይሆናል፤ ይህም ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ከሆነው ከተቀደሰው ቦታ አንሥቶ በምሥራቅ በኩል እስከ ምሥራቁ ወሰን ይዘልቃል፤ በምዕራቡም በኩል እንዲሁ ሃያ አምስት ሺሕ ክንድ ከሆነው ይዞታ አንሥቶ እስከ ምዕራቡ ወሰን ይዘልቃል። የየነገዱ ድርሻ ከሆነውም መሬት ጐን ለጐን የሚሄዱት ቦታዎች የገዥው ይሆናሉ። የተቀደሰው ቦታና መቅደሱ በመካከላቸው ይሆናሉ። 22ስለዚህ የሌዋውያኑ ይዞታና የከተማዪቱ ይዞታ ለገዥው በተሰጠው ቦታ መካከል ይሆናል፤ የገዥው ቦታም በይሁዳ ድንበርና በብንያም ድንበር መካከል ይሆናል።

23“የቀሩት ነገዶች ድርሻ እንደሚከተለው ይሆናል፤

“የብንያም ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ይዘልቃል።

24የስምዖን ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የስምዖንን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

25የይሳኮር ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የስምዖንን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

26የዛብሎን ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የይሳኮርን ምድር ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

27የጋድ ነገድ አንድ ድርሻ ይኖረዋል፤ ይህም የዛብሎንን ግዛት ከምሥራቅ እስከ ምዕራብ ያዋስናል።

28የጋድ ደቡባዊ ወሰን ከታማር ደቡብ እስከ ሜሪባ ቃዴስ ውሆች ይደርሳል፤ የግብፅን ደረቅ ወንዝ ይዞ እስከ ታላቁ ባሕር48፥28 ሜድትራኒያንን ያመለክታል ይዘልቃል።

29“ ለእስራኤል ነገዶች ርስት አድርጋችሁ የምታከፋፍሏት ምድር ይህች ናት፤ ድርሻዎቻቸውም እነዚህ ናቸው” ይላል ጌታ እግዚአብሔር

የከተማዪቱ በሮች

30“ የከተማዪቱ መውጫ በሮች እነዚህ ናቸው፤

“ከሰሜን በኩል አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ ርዝመት ካለው በር አንሥቶ፣ 31የከተማዪቱ በሮች በእስራኤል ነገዶች ስም ይጠራሉ፤ በሰሜን በኩል ያሉት ሦስቱ በሮች የሮቤል ነገድ በር፣ የይሁዳ ነገድ በርና የሌዊ ነገድ በር ይሆናሉ።

32በምሥራቅ በኩል አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ ርዝመት ባለው በር ሦስት በሮች ይኖራሉ፤ እነዚህም የዮሴፍ በር፣ የብንያም በርና የዳን በር ናቸው።

33በደቡብ በኩል አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ ርዝመት ባለው በር ሦስት በሮች አሉ፤ እነዚህም የስምዖን በር፣ የይሳኮር በርና የዛብሎን በር ናቸው።

34በምዕራብ በኩል አራት ሺሕ አምስት መቶ ክንድ ርዝመት ባለው በር ሦስት በሮች ይኖራሉ፤ እነዚህም የጋድ በር፣ የአሴር በርና የንፍታሌም በር ናቸው።

35“ የከተማዪቱም ዙሪያ ዐሥራ ስምንት ሺሕ ክንድ ይሆናል፤

“ የከተማዪቱ ስም፣ ከዚያን ጊዜ ጀምሮ ‘እግዚአብሔር በዚያ አለ’ ” ይሆናል።