Esekiẹli 46 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 46:1-24

1“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i. 2Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́. 3Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. 4Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù. 5Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan. 6Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n. 7Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan. 8Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.

9“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde. 10Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.

11“ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan. 12Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.

13“ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀. 14Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí. 15Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

16“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ. 17Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀; Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn. 18Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”

19Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bàá ẹnu-ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀-oòrùn. 20O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má ṣe jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá, kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”

21Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan. 22Ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnu pọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà. 23Ní agbègbè inú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo. 24Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”

New International Version

Ezekiel 46:1-24

1“ ‘This is what the Sovereign Lord says: The gate of the inner court facing east is to be shut on the six working days, but on the Sabbath day and on the day of the New Moon it is to be opened. 2The prince is to enter from the outside through the portico of the gateway and stand by the gatepost. The priests are to sacrifice his burnt offering and his fellowship offerings. He is to bow down in worship at the threshold of the gateway and then go out, but the gate will not be shut until evening. 3On the Sabbaths and New Moons the people of the land are to worship in the presence of the Lord at the entrance of that gateway. 4The burnt offering the prince brings to the Lord on the Sabbath day is to be six male lambs and a ram, all without defect. 5The grain offering given with the ram is to be an ephah,46:5 That is, probably about 35 pounds or about 16 kilograms; also in verses 7 and 11 and the grain offering with the lambs is to be as much as he pleases, along with a hin46:5 That is, about 1 gallon or about 3.8 liters; also in verses 7 and 11 of olive oil for each ephah. 6On the day of the New Moon he is to offer a young bull, six lambs and a ram, all without defect. 7He is to provide as a grain offering one ephah with the bull, one ephah with the ram, and with the lambs as much as he wants to give, along with a hin of oil for each ephah. 8When the prince enters, he is to go in through the portico of the gateway, and he is to come out the same way.

9“ ‘When the people of the land come before the Lord at the appointed festivals, whoever enters by the north gate to worship is to go out the south gate; and whoever enters by the south gate is to go out the north gate. No one is to return through the gate by which they entered, but each is to go out the opposite gate. 10The prince is to be among them, going in when they go in and going out when they go out. 11At the feasts and the appointed festivals, the grain offering is to be an ephah with a bull, an ephah with a ram, and with the lambs as much as he pleases, along with a hin of oil for each ephah.

12“ ‘When the prince provides a freewill offering to the Lord—whether a burnt offering or fellowship offerings—the gate facing east is to be opened for him. He shall offer his burnt offering or his fellowship offerings as he does on the Sabbath day. Then he shall go out, and after he has gone out, the gate will be shut.

13“ ‘Every day you are to provide a year-old lamb without defect for a burnt offering to the Lord; morning by morning you shall provide it. 14You are also to provide with it morning by morning a grain offering, consisting of a sixth of an ephah46:14 That is, probably about 6 pounds or about 2.7 kilograms with a third of a hin46:14 That is, about 1 1/2 quarts or about 1.3 liters of oil to moisten the flour. The presenting of this grain offering to the Lord is a lasting ordinance. 15So the lamb and the grain offering and the oil shall be provided morning by morning for a regular burnt offering.

16“ ‘This is what the Sovereign Lord says: If the prince makes a gift from his inheritance to one of his sons, it will also belong to his descendants; it is to be their property by inheritance. 17If, however, he makes a gift from his inheritance to one of his servants, the servant may keep it until the year of freedom; then it will revert to the prince. His inheritance belongs to his sons only; it is theirs. 18The prince must not take any of the inheritance of the people, driving them off their property. He is to give his sons their inheritance out of his own property, so that not one of my people will be separated from their property.’ ”

19Then the man brought me through the entrance at the side of the gate to the sacred rooms facing north, which belonged to the priests, and showed me a place at the western end. 20He said to me, “This is the place where the priests are to cook the guilt offering and the sin offering46:20 Or purification offering and bake the grain offering, to avoid bringing them into the outer court and consecrating the people.”

21He then brought me to the outer court and led me around to its four corners, and I saw in each corner another court. 22In the four corners of the outer court were enclosed46:22 The meaning of the Hebrew for this word is uncertain. courts, forty cubits long and thirty cubits wide;46:22 That is, about 70 feet long and 53 feet wide or about 21 meters long and 16 meters wide each of the courts in the four corners was the same size. 23Around the inside of each of the four courts was a ledge of stone, with places for fire built all around under the ledge. 24He said to me, “These are the kitchens where those who minister at the temple are to cook the sacrifices of the people.”