Deuteronomi 33 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 33:1-29

Mose bùkún fún àwọn ẹ̀yà

1Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú. 2Ó sì wí pé:

Olúwa ti Sinai wá,

ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá

ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.

Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá

láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.

3Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,

gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.

Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,

àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,

4òfin tí Mose fi fún wa,

ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.

5Òun ni ọba lórí Jeṣuruni

ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,

pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

6“Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,

tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”

7Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:

Olúwa gbọ́ ohùn Juda

kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.

Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,

kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”

8Ní ti Lefi ó wí pé:

“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà

pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.

Ẹni tí ó dánwò ní Massa,

ìwọ bá jà ní omi Meriba.

9Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,

‘Èmi kò buyì fún wọn.’

Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,

tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,

ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,

ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.

10Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀

àti Israẹli ní òfin rẹ̀.

Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀

àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.

11Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa,

kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;

àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,

kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

12Ní ti Benjamini ó wí pé:

“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,

òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,

ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”

13Ní ti Josẹfu ó wí pé:

“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,

fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì

àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;

14àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá

àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;

15pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì

àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;

16Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀

àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.

Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,

lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.

17Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;

ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.

Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,

pàápàá títí dé òpin ayé.

Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún (10,000) Efraimu,

àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún (1,000) Manase.”

18Ní ti Sebuluni ó wí pé:

“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,

àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.

19Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè

àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,

wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,

nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”

20Ní ti Gadi ó wí pé:

“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!

Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,

ó sì fa apá ya, àní àtàrí.

21Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;

ìpín olórí ni a sì fi fún un.

Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,

ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,

àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”

22Ní ti Dani ó wí pé:

“Ọmọ kìnnìún ni Dani,

tí ń fò láti Baṣani wá.”

23Ní ti Naftali ó wí pé:

“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run

àti ìbùkún Olúwa;

yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”

24Ní ti Aṣeri ó wí pé:

“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;

jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀

kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.

25Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,

agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.

26“Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,

ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ

àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.

27Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,

àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.

Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,

ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’

28Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,

orísun Jakọbu nìkan

ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,

níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.

29Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,

ta ni ó dàbí rẹ,

ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?

Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀

àti idà ọláńlá rẹ̀.

Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,

ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

New Amharic Standard Version

ዘዳግም 33:1-29

ሙሴ የእስራኤልን ነገዶች ባረከ

33፥1-29 ተጓ ምብ – ዘፍ 49፥1-28

1የእግዚአብሔር (ያህዌ) ሰው ሙሴ ከመሞቱ በፊት ለእስራኤላውያን የሰጠው ቃለ ቡራኬ ይህ ነው፤ 2እንዲህም አለ፦

እግዚአብሔር (ያህዌ) ከሲና መጣ፤

በእነርሱም ላይ ከሴይር እንደ ማለዳ ፀሓይ ወጣ፤

ከፋራን ተራራ አበራላቸው፤

ከአእላፋት ቅዱሳኑ ጋር33፥2 ወይም በአእላፋት ቅዱሳኑ። መጣ፤

በስተ ቀኙ የሚነድድ እሳት ነበር።

3በርግጥ ሕዝቡን የምትወድ አንተ ነህ፤

ቅዱሳኑ ሁሉ በእጅህ ውስጥ ናቸው።

ከእግርህ ሥር ሁሉ ይሰግዳሉ፤

ከአንተ ትእዛዝ ይቀበላሉ፤

4ይህ ሙሴ የሰጠን ሕግ፣

የያዕቆብ ጉባኤ ርስት ነው።

5የሕዝቡ አለቆች ከእስራኤል ነገዶች ጋር ሆነው፣

በአንድነት በተሰበሰቡ ጊዜ፣

እርሱ በይሹሩን33፥5 በዚህ ስፍራና በቍጥር 26 ላይ ይሽሩን ማለት፣ ቅን ወይም ትክክለኛ ማለት ሲሆን ይኸውም እስራኤልን የሚያሳይ ነው። ላይ ንጉሥ ነበር።

6“ሮቤል በሕይወት ይኑር፤ አይሙት፤

የወገኖቹ ቍጥርም አይጕደልበት።”

7ስለ ይሁዳ የተናገረው ይህ ነው፦

እግዚአብሔር (ያህዌ) ሆይ፤ የይሁዳን ጩኸት ስማ፤

ወደ ወገኖቹም አምጣው።

በገዛ እጆቹ ራሱን ይከላከላል፤

አቤቱ ከጠላቶቹ ጋር ሲዋጋ ረዳቱ ሁን!”

8ስለ ሌዊም እንዲህ አለ፦

“ቱሚምህና ኡሪምህ፣

ለምትወድደው ሰው ይሁን፤

ማሳህ በተባለው ቦታ ፈተንኸው፤

በመሪባም ውሃ ከእርሱ ጋር ተከራከርህ።

9ስለ አባቱና ስለ እናቱ ሲናገርም፣

‘ስለ እነርሱ ግድ የለኝም’ አለ።

ወንድሞቹን አልለያቸውም፤

ልጆቹንም አላወቃቸውም።

ለቃልህ ግን ጥንቃቄ አደረገ፤

ኪዳንህንም ጠበቀ።

10ሥርዐትህን ለያዕቆብ፣

ሕግህንም ለእስራኤል ያስተምራል።

ዕጣን በፊትህ፣

የሚቃጠለውን መሥዋዕት ሁሉ በመሠዊያህ ላይ ያቀርባል።

11እግዚአብሔር (ያህዌ) ሆይ፤ ኀይሉን ሁሉ ባርክለት፤

በእጁ ሥራ ደስ ይበልህ፤

በእርሱ ላይ የሚነሡበትን ሽንጣቸውን ቍረጠው፤

ጠላቶቹንም እንዳያንሠራሩ አድርገህ ምታቸው።”

12ስለ ብንያም እንዲህ አለ፦

የእግዚአብሔር (ያህዌ) ወዳጅ የሆነ በእርሱ ተጠብቆ በሰላም ይረፍ፤

ቀኑን ሙሉ ይጋርደዋልና፤

እግዚአብሔር (ያህዌ) የሚወድደውም ሰው በትከሻዎቹ መካከል ያርፋል።”

13ስለ ዮሴፍ ደግሞ እንዲህ አለው፦

እግዚአብሔር (ያህዌ) ምድሩን ይባርክ፤

ድንቅ የሆነውን ጠል ከላይ ከሰማይ በማውረድ፣

ከታች የተንጣለለውን ጥልቅ ውሃ

14ፀሓይ በምታስገኘው ምርጥ ፍሬ፣

ጨረቃም በምትሰጠው እጅግ መልካም

15ከጥንት ተራሮች በተገኘ ምርጥ ስጦታ፣

በዘላለማዊ ኰረብቶች ፍሬያማነት፤

16ምድር በምታስገኘው ምርጥ ስጦታና በሙላቷ፣

በሚቃጠለው ቍጥቋጦም ውስጥ በነበረው በእርሱ ሞገስ።

እነዚህ ሁሉ በወንድሞቹ መካከል ገዥ በሆነው፣

በዮሴፍ ዐናት ላይ ይውረዱ።

17በግርማው እንደ በኵር ኰርማ ነው፤

ቀንዶቹም የጐሽ ቀንዶች ናቸው።

በእነርሱም ሕዝቦችን፣

በምድር ዳርቻ ላይ ያሉትን እንኳ ሳይቀር ይወጋል፤

እነርሱም የኤፍሬም ዐሥር ሺዎቹ ናቸው፤

የምናሴም ሺዎቹ እንደዚሁ ናቸው።”

18ስለ ዛብሎንም እንዲህ አለ፦

“ዛብሎን ሆይ፤ ወደ ውጭ በመውጣትህ፣

አንተም ይሳኮር በድንኳኖችህ ውስጥ ደስ ይበልህ፤

19አሕዛብን ወደ ተራራው ይጠራሉ፤

በዚያም የጽድቅን መሥዋዕት ያቀርባሉ።

በባሕሮች ውስጥ ያለውን በተትረፈረፈ ብልጽግና፣

በአሸዋውም ውስጥ የተደበቀውን ሀብት ይደሰቱበታል።”

20ስለ ጋድም እንዲህ አለ፦

“የጋድን ግዛት የሚያሰፋ የተመሰገነ ነው!

ክንድንና ራስን በመገነጣጠል፣

ጋድ እንደ አንበሳ በዚያ ይኖራል።

21ለም የሆነውን መሬት ለራሱ መረጠ፤

የአለቃም ድርሻ ለእርሱ ተጠብቆለታል።

የሕዝቡ መሪዎች በተሰበሰቡ ጊዜ፣

የእግዚአብሔርን (ያህዌ) የቅን ፈቃድና፣

በእስራኤል ላይ የበየነውን ፍርዱን ፈጸመ።”

22ስለ ዳንም እንዲህ አለ፦

“ዳን ከባሳን ዘልሎ የሚወጣ፣

የአንበሳ ደቦል ነው።”

23ስለ ንፍታሌምም እንዲህ አለ፦

“ንፍታሌም በእግዚአብሔር (ያህዌ) ሞገስ ረክቷል፤

በበረከቱም ተሞልቷል፤

ባሕሩንና የደቡብን ምድር ይወርሳል።”

24ስለ አሴርም እንዲህ አለ፦

“አሴር ከሌሎች ልጆች ይልቅ የተባረከ ነው፤

በወንድሞቹ ዘንድ ተወዳጅ ይሁን፤

እግሩንም በዘይት ውስጥ ያጥልቅ።

25የደጃፍህ መቀርቀሪያ ብረትና ናስ ይሆናል፤

ኀይልህም በዘመንህ ሁሉ ይኖራል።

26“አንተን ለመርዳት በሰማያት ላይ፣

በደመናትም ላይ በግርማው እንደሚገሠግሥ፣

እንደ ይሽሩን አምላክ ያለ ማንም የለም።

27ዘላለማዊ አምላክ (ኤሎሂም) መኖርያህ ነው፤

የዘላለም ክንዶቹም ከሥርህ ናቸው፤

‘እርሱን አጥፋው!’ በማለት፣

ጠላትህን ከፊትህ ያስወግደዋል።

28ስለዚህ እስራኤል ብቻውን በሰላም ይኖራል፤

የሰማያት ጠል በሚወርድበት፣

እህልና የወይን ጠጅ ባለበት ምድር፣

የያዕቆብን ምንጭ የሚነካው የለም።

29እስራኤል ሆይ፤ አንተ ቡሩክ ነህ፤

እግዚአብሔር (ያህዌ) ያዳነው ሕዝብ፣

እንደ አንተ ያለ ማን አለ?

እርሱ ጋሻህና ረዳትህ፣ የክብርህም ሰይፍ ነው።

ጠላቶችህ በፍርሀት ከፊትህ ያፈገፍጋሉ፤

አንተም የማምለኪያ ኰረብታቸውን

መረማመጃ ታደርጋለህ።”