2 Timotiu 4 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Timotiu 4:1-22

1Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. 2Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. 3Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. 4Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. 5Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.

6Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. 7Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; 8Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.

Àwọn àkíyèsí ti ara ẹni

9Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. 104.10: Kl 4.14; Fm 24; 2Kọ 8.23; Ga 2.3; Tt 1.4.Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. 11Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. 12Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu. 13Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.

14Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: 15Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.

16Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn. 17Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

19Kí Priska àti Akuila, àti ilé Onesiforu.

20Erastu wà ní Kọrinti: ṣùgbọ́n mo fi Tirofimu sílẹ̀ ni Miletu nínú àìsàn. 21Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù.

Eubulu kí ọ, àti Pudeni, àti Linu, Klaudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin.

22Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín.

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס השנייה אל-טימותיוס 4:1-22

1אני מצווה עליך לפני אלוהים ולפני אדוננו ישוע המשיח, אשר ישפוט את החיים ואת המתים בבואו ובמלכותו: 2הטף את דבר האלוהים בכל עת – בכל הזדמנות שבאה לידך, בין אם זה נוח או לא. הוכח, הזהר ותקן את אנשיך כשיש צורך בכך; עודד אותם לעשות את הטוב ולמד אותם בסבלנות את דבר ה׳. 3כי יבוא הזמן שהאנשים לא יקשיבו לאמת, ויחפשו מורים שילמדו אותם מה שהם רוצים לשמוע. 4הם לא יקשיבו לדבר אלוהים, ויפנו בשמחה לאגדות ולשקרים.

5אבל אתה שמור על קור רוחך, ואל תפחד לסבול למען האדון. הדרך אנשים אחרים לאמונה במשיח, ובצע את כל המוטל עליך על הצד הטוב ביותר.

6אני אומר לך דברים אלה משום שלא נותר לי זמן רב להיות איתך. שעתי קרבה – תוך זמן קצר אעבור מן העולם הזה ואהיה בשמים. 7נלחמתי את המלחמה הטובה למען האדון, רצתי במרוץ הגדול ותמיד נשארתי נאמן לו. הגיעה העת שאנוח. 8עתה שמור לי בשמים כתר צדקה אשר האדון, שופט־הצדק, ייתן לי ביום שובו, ולא רק לי, כי אם לכל אלה שמצפים לשובו בכיליון עיניים.

9אנא, בוא אלי במהירות האפשרית, 10כי דימס עזב אותי בגלל אהבתו לדברי העולם הזה, והלך לתסלוניקי. קריסקיס הלך לגלטיא, וטיטוס הלך לדלמטיה. 11רק לוקס נמצא איתי. הבא איתך את מרקוס, כי אני זקוק לעזרתו.

12(גם טוכיקוס איננו כאן, כי שלחתיו לאפסוס). 13אנא, הבא איתך את מעילי אשר השארתי אצל אחינו קרפוס בטרואס, ואת הספרים, והחשוב ביותר – את כתבי הקלף.

14אלכסנדרוס חרש הנחושת עולל לי רעות רבות. ישלם לו אלוהים כגמולו.

15היזהר ממנו, כי הוא מתנגד בחריפות לכל מה שאנחנו מאמינים.

16כשהביאו אותי למשפט בפעם הראשונה, איש לא היה כאן כדי לעזור לי; כולם ברחו להם. (אני מקווה שאלוהים לא ישפוט אותם על כך). 17אך האדון חיזק אותי ועזר לי, כדי שאוכל להטיף את הבשורה באומץ לכל העולם, ובכך הצילני מלוע הארי. 18אכן, האדון יצילני תמיד מכל רע ויביאני אל מלכותו בשמים. לאלוהים הכבוד לעולם ועד. – אמן.

19אנא, מסור דרישת־שלום בשמי לפריסקה, לעקילס ולאלה שגרים בביתו של אוניסיפורוס. 20ארסטוס נשאר בקורינתוס, ואת טרופימוס השארתי חולה במיליטוס.

21השתדל לבוא לכאן לפני בוא החורף. אובולוס, פודיס, לינוס, קלודיה וכל האחים דורשים בשלומך.

22אדוננו ישוע המשיח יברך אותך ויהיה עם רוחך. – אמן.