2 Tẹsalonika 2 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Tẹsalonika 2:1-17

Ọkùnrin aláìlófin náà

12.1: 1Tẹ 4.15-17.Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará, 22.2: 2Tẹ 3.17.kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná. 32.3: Ef 5.6-8; Da 7.8,25; 11.36; If 13.5; Jh 17.12.Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé. 42.4: El 28.2.Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.

52.5: 1Tẹ 3.4.Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín. 6Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an. 7Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà. 82.8: Isa 11.4.Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun. 92.9: Mt 24.24; Jh 4.48.Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì ààmì àti àdàmọ̀dì idán, 10Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà. 112.11: Ro 1.28.Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́, 12kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.

Ẹ dúró ṣinṣin

132.13: 2Tẹ 1.3; Ef 1.4; 1Pt 1.2.Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. 14Òun ti pè yín sí èyí nípa ìhìnrere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jesu Kristi Olúwa wa.

152.15: 1Kọ 16.13; 11.2.Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.

162.16: 1Tẹ 3.11; 1Pt 1.3.Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. 17Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס השנייה אל-התסלוניקים 2:1-17

1בנוגע לבואו של ישוע המשיח אדוננו ופגישתנו איתו, אני מבקש מכם, אחים יקרים, אנא, 2אל תאבדו את עשתונותיכם ואל תפחדו משמועות כזב, חזיונות שווא, נבואות שקר ומסמכים מזויפים, שנכתבו כביכול על־ידי, שמספרים כי הגיע יום ה׳. 3אל תניחו לאף אחד לרמות ולבלבל אתכם, כי לפניכן יפרוץ המרד ואיש הרשע יתגלה, זה שנידון לאבדון. 4הוא ירומם את עצמו מעל כל מה שמאלוהים וכל מה שקדוש, עד שיעז אפילו לשבת בהיכל אלוהים ויכריז שהוא עצמו אלוהים! 5האם אינכם זוכרים שסיפרתי לכם כל זאת כשהייתי אצלכם? 6עכשיו אתם יודעים מה מונע בעדו מלהופיע לפני הזמן המתאים.

7מעלליו הרעים כבר משתוללים בעולם, אך הוא עצמו יוכל להופיע רק כשיוסר המעצור מדרכו. 8ואז יתגלה בן־האבדון הרשע, אשר האדון ישוע ישתק בהבל־פיו וישמיד אותו כליל בזוהר כבודו. 9הרשע הזה יבוא בשליחות השטן ובכוחו, וידהים את כולם באותות־שקר ואחיזת־עיניים. 10הוא יצליח להטעות את האנשים שנועדו לגיהינום, בגלל סירובם לאהוב את האמת שבכוחה להושיעם. 11על כן יניח להם אלוהים להאמין בכל השקרים האלה, 12כדי שיוכל לשפטם על אשר האמינו בשקרים, עשו בכוונה את הרע וסרבו להאמין באמת.

13אך אנו חייבים להודות תמיד לאלוהים בעדכם, אחי יקירי האדון, כי עוד מבראשית הוא בחר להושיע ולטהר אתכם באמצעות רוח הקודש ואמונתכם באמת. 14הוא אף הזמינכם לקחת חלק בכבודו של אדוננו ישוע המשיח, באמצעות הבשורה שבישרנו לכם.

15על כן, אחים יקרים, התמידו באמונתכם, ואל תרפו מכל מה שלימדנו אתכם בכתב ובעל־פה.

16מי ייתן שאדוננו ישוע המשיח ואלוהים אבינו, אשר אהב אותנו והעניק לנו נחמת־עולם ותקווה שאיננו ראויים לה, 17ינחם את לבכם ויעזור לכם בכל דבר טוב שתאמרו או תעשו.