2 Samuẹli 2 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 2:1-32

A yan Dafidi ní ọba Juda

1Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ Olúwa. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?”

Olúwa sì wí pé, “Gòkè lọ.”

Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?”

Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.”

2Nígbà náà ni Dafidi gòkè lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili obìnrin opó Nabali ti Karmeli. 3Dafidi sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hebroni àti ìlú rẹ̀ mìíràn. 4Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Juda wá sí Hebroni, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ààmì òróró yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Juda.

Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, àwọn ọkùnrin ti Jabesi Gileadi ni ó sin òkú Saulu, 5Dafidi rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi láti sọ fún wọn pé, “Olúwa bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Saulu ọ̀gá yín nípa sí sin ín. 6Olúwa kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí. 7Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Saulu ọba yín ti kú, ilé Juda sì ti fi ààmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”

Ogun láàrín ilé Dafidi àti Saulu

8Lákòókò yìí, Abneri ọmọ Neri olórí ogun Saulu ti mú Iṣboṣeti ọmọ Saulu, ó sì mú un kọjá sí Mahanaimu. 9Ó sì fi jẹ ọba lórí Gileadi Aṣuri àti Jesreeli àti lórí Efraimu àti lórí Benjamini àti lórí gbogbo Israẹli.

10Iṣboṣeti ọmọ Saulu sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. Ilé Juda sì ń tọ Dafidi lẹ́yìn. 11Gbogbo àkókò tí Dafidi fi jẹ ọba ní Hebroni lórí ilé Juda sì jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.

12Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni. 13Joabu ọmọ Seruiah pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dafidi jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gibeoni. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún.

14Nígbà náà, Abneri sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.”

Joabu sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é.”

15Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Benjamini àti Iṣboṣeti ọmọ Saulu àti méjìlá fún Dafidi. 16Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gibeoni ti à ń pè ni Helikatihu Hasurimu.

17Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì ṣẹ́gun Abneri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Israẹli.

18Àwọn ọmọkùnrin Seruiah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Joabu, Abiṣai àti Asaheli. Nísinsin yìí ẹsẹ̀ Asaheli sì fẹ́rẹ̀ bí ẹsẹ̀ èsúró tí ó wà ní pápá. 19Asaheli sì ń lépa Abneri, bí òun tí ń lọ kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì láti máa tọ́ Abneri lẹ́yìn. 20Abneri bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ Asaheli ni?”

Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

21Nígbà náà, Abneri sọ fún un pé, “Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì; mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ.” Ṣùgbọ́n Asaheli kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀.

22Abneri tún kìlọ̀ fún Asaheli, “Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀? Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Joabu lójú?”

23Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Abneri sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ̀, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Asaheli gbé ṣubú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́.

24Joabu àti Abiṣai sì lépa Abneri: oòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Amima tí o wà níwájú Giah lọ́nà ijù Gibeoni. 25Àwọn ọmọ Benjamini sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Abneri, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan.

26Abneri sì pe Joabu, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parun títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ì tí ì mọ̀ pé yóò korò níkẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.”

27Joabu sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.”

28Joabu sì fọ́n ìpè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Israẹli mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́.

29Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu.

30Joabu sì dẹ́kun àti máa tọ Abneri lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kàn-dínlógún ni ó kú pẹ̀lú Asaheli nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. 31Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjì-dín-nírínwó ènìyàn. 32Wọ́n si gbé Asaheli wọ́n sì sin ín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu. Joabu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hebroni.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

撒母耳記下 2:1-32

大衛做猶大王

1這事以後,大衛求問耶和華:「我可以回到猶大的城邑嗎?」耶和華說:「可以。」大衛又問:「我應該回到哪一座城呢?」耶和華說:「希伯崙。」 2大衛就帶著他的兩個妻子耶斯列亞希暖迦密拿八的遺孀亞比該,一起上到希伯崙3他還把部下和他們的家屬一起帶去,住在希伯崙地區的城邑。 4猶大人到希伯崙膏立大衛猶大支派的王。

大衛聽說是基列·雅比人埋葬了掃羅5就派人去告訴他們:「你們這樣厚待你們的主人掃羅,把他安葬,願耶和華賜福給你們! 6願耶和華以慈愛和信實待你們,我也會厚待你們,因為你們做了這事。 7現在你們的主掃羅已經死了,猶大支派已經膏立我做他們的王,你們要剛強勇敢。」

大衛家與掃羅家爭戰

8那時,掃羅的元帥尼珥的兒子押尼珥帶著掃羅的兒子伊施波設過河來到瑪哈念9立他為王統治基列亞書利耶斯列以法蓮便雅憫以色列其餘的地方。 10掃羅的兒子伊施波設四十歲登基,統治以色列兩年。猶大支派則跟隨大衛11大衛希伯崙做王統治猶大支派七年半。

12有一次,尼珥的兒子押尼珥帶領掃羅的兒子伊施波設的軍隊,從瑪哈念前往基遍13洗魯雅的兒子約押帶領大衛的軍隊出來,在基遍池與他們相遇。一方坐在池這邊,一方坐在池那邊。 14押尼珥約押說:「讓雙方的青年起來在我們面前較量一下吧。」約押說:「好啊。」 15於是,雙方都選了十二人出來, 16他們各自抓住對方的頭髮,用刀刺對方的肋旁,同歸於盡。於是基遍的那個地方叫「刀田」。 17那天,兩軍惡戰,押尼珥以色列人被大衛的人馬殺敗。 18當時,洗魯雅的三個兒子約押亞比篩亞撒黑都在場。亞撒黑跑得飛快如鹿, 19他跟在押尼珥後面,不偏不離,窮追不捨。 20押尼珥回頭問道:「你是亞撒黑嗎?」亞撒黑說:「正是。」 21押尼珥說:「你去追趕別人,奪取他的兵器吧。」但亞撒黑還是窮追不捨。 22押尼珥又對他說:「快走開吧,非逼我殺你嗎?我若殺了你,還有何顏面見你哥哥約押呢?」 23亞撒黑還是不肯甘休。押尼珥就用槍柄刺入他的肚腹,穿透了他的後背,他便倒地身亡。眾人趕到那裡,都停了下來。

24約押亞比篩卻繼續追趕押尼珥。太陽落山時,他們追到了基亞附近的亞瑪山,通往基遍曠野的路旁。 25便雅憫人在押尼珥的帶領下聚集在一個山頭上。 26押尼珥約押喊道:「我們非要無休止地殺下去嗎?難道你不知道這樣下去必有苦果嗎?你什麼時候才命你的人停止追殺自己的同胞呢?」 27約押說:「我憑永活的上帝起誓,你要是不這樣說,我們會一直追到天亮。」 28於是,約押吹響號角,所有的人便停止了戰鬥,不再追趕以色列的軍隊。

29押尼珥和隨從連夜趕路,穿過了亞拉巴,過了約旦河,第二天又馬不停蹄地走了一個上午,回到瑪哈念30約押追趕押尼珥回來後細點人數,發現除亞撒黑外還損失了十九個人。 31大衛的軍隊殺了三百六十個跟隨押尼珥便雅憫人。 32約押和他的隨從把亞撒黑送到伯利恆,葬在他父親的墳墓裡。然後,他們整夜趕路,黎明的時候回到了希伯崙