2 Kọrinti 2 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 2:1-17

1Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá. 2Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́? 3Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀: nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi. 4Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

Ìdáríjì fún ẹlẹ́ṣẹ̀

5Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. 6Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. 7Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. 8Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. 9Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo. 10Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi. 11Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.

Ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun

122.12: Ap 16.8.Ṣùgbọ́n nígbà ti mo dé Troasi láti wàásù ìhìnrere Kristi, tí mo sì rí i wí pé Olúwa ti ṣí ìlẹ̀kùn fún mi, 13síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.

14Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé: 16Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí? 17Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

New International Reader’s Version

2 Corinthians 2:1-17

1So I made up my mind that I would not make another painful visit to you. 2If I make you sad, who is going to make me glad? Only you, the people I made sad. 3What I wrote to you I wrote for a special reason. When I came, I didn’t want to be troubled by those who should make me glad. I was sure that all of you would share my joy. 4I was very troubled when I wrote to you. My heart was sad. My eyes were full of tears. I didn’t want to make you sad. I wanted to let you know that I love you very deeply.

Forgive Those Who Make You Sad

5Suppose someone has made us sad. In some ways, he hasn’t made me sad so much as he has made all of you sad. But I don’t want to put this too strongly. 6He has been punished because most of you decided he should be. This punishment is enough. 7Now you should forgive him and comfort him. Then he won’t be sad more than he can stand. 8So I’m asking you to tell him again that you still love him. 9I wrote to you for another special reason. I wanted to see if you could stand the test. I wanted to see if you could obey everything asked of you. 10Anyone you forgive I also forgive. Was there anything to forgive? If so, I have forgiven it for your benefit, knowing that Christ is watching. 11We don’t want Satan to outsmart us. We know how he does his evil work.

Serving Under the New Covenant

12I went to Troas to preach the good news about Christ. There I found that the Lord had opened a door of opportunity for me. 13But I still had no peace of mind. I couldn’t find my brother Titus there. So I said goodbye to the believers at Troas and went on to Macedonia.

14Give thanks to God! He always leads us as if we were prisoners in Christ’s victory parade. Through us, God spreads the knowledge of Christ everywhere like perfume. 15God considers us to be the pleasing smell that Christ is spreading. He is spreading it among people who are being saved and people who are dying. 16To those who are dying, we are the smell of death. To those who are being saved, we are the perfume of life. Who is able to do this work? 17Unlike many people, we aren’t selling God’s word to make money. In fact, it is just the opposite. Because of Christ we speak honestly before God. We speak like people God has sent.