2 Kọrinti 13 – YCB & KJV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 13:1-14

Àwọn ìkìlọ̀ ìkẹyìn

113.1: 2Kọ 12.14; De 19.15.Èyí ni ó dí ìgbà kẹta tí èmi ń tọ̀ yín wá. Ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó fi ìdí ọ̀rọ̀ gbogbo múlẹ̀. 2Mo ti sọ fún yín ṣáájú, mo sì ń sọ fún yín tẹ́lẹ̀, bí ẹni pé mo wà pẹ̀lú yín nígbà kejì, àti bí èmi kò ti sí lọ́dọ̀ yín ní ìsinsin yìí, mo kọ̀wé sí àwọn tí ó ti ṣẹ̀ náà, àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn, pé bí mo bá tún padà wá, èmi kì yóò dá wọn sí. 3Níwọ́n bí ẹ̀yin tí ń wá ààmì Kristi ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín. 413.4: Fp 2.7-8; Ro 6.8.Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láààyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú jásí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.

5Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnrayín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù. 6Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù. 7Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù. 8Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́. 9Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín. 10Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.

Ìkíni ìkẹyìn

11Ní àkótán, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnṣe ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínú kan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.

1213.12: Ro 16.16.Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

1313.13: Fp 4.22.Gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run níbi kí i yín.

1413.14: Ro 16.20.Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa, àti ìfẹ́ Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀ ti Èmí Mímọ́, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

King James Version

2 Corinthians 13:1-14

1This is the third time I am coming to you. In the mouth of two or three witnesses shall every word be established. 2I told you before, and foretell you, as if I were present, the second time; and being absent now I write to them which heretofore have sinned, and to all other, that, if I come again, I will not spare: 3Since ye seek a proof of Christ speaking in me, which to you-ward is not weak, but is mighty in you. 4For though he was crucified through weakness, yet he liveth by the power of God. For we also are weak in him, but we shall live with him by the power of God toward you. 5Examine yourselves, whether ye be in the faith; prove your own selves. Know ye not your own selves, how that Jesus Christ is in you, except ye be reprobates? 6But I trust that ye shall know that we are not reprobates. 7Now I pray to God that ye do no evil; not that we should appear approved, but that ye should do that which is honest, though we be as reprobates. 8For we can do nothing against the truth, but for the truth. 9For we are glad, when we are weak, and ye are strong: and this also we wish, even your perfection. 10Therefore I write these things being absent, lest being present I should use sharpness, according to the power which the Lord hath given me to edification, and not to destruction.

11Finally, brethren, farewell. Be perfect, be of good comfort, be of one mind, live in peace; and the God of love and peace shall be with you. 12Greet one another with an holy kiss.

13All the saints salute you. 14The grace of the Lord Jesus Christ, and the love of God, and the communion of the Holy Ghost, be with you all. Amen.