1 Timotiu 6 – YCB & NUB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Timotiu 6:1-21

Àwọn ẹrú

1Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 2Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́.

Ìfẹ́ owó

Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú. 3Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu, 4Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá, 5àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.

6Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. 7Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. 8Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. 9Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. 10Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú fún Timotiu

11Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù. 12Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀. 136.13: Jh 18.37.Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu, 14Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. 15Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa. 16Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín.

17Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò; 18Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; 19kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.

20Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀; 21èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́.

Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ.

Swedish Contemporary Bible

1 Timotheosbrevet 6:1-21

Råd angående slavar

1De som bär slaveriets ok ska visa sina ägare verklig respekt, så att Guds namn och läran inte ska smädas. 2Om slavägaren också är troende, får inte slaven visa mindre respekt därför att de båda är bröder. Tvärtom bör slavarna i så fall tjänstgöra ännu villigare, eftersom deras tjänst då blir till nytta för troende och älskade bröder.

Falsk undervisning och sann rikedom

Så ska du undervisa och förmana. 3Om någon kommer med en falsk undervisning och inte håller sig till vår Herre Jesus Kristus sunda budskap och den fromma läran, 4är han förblindad och okunnig. Han har ett sjukligt behov av att diskutera och strida om ord, vilket leder till avundsjuka, gräl, förolämpningar, onda misstankar 5och ständiga bråk mellan människor med fördärvade sinnen, människor som har gått miste om sanningen och menar att fromheten ska löna sig.

6Och visst är fromheten en rikedom, om man kan vara nöjd med det man har. 7Vi hade inget med oss när vi föddes, och vi kan inget ta med oss när vi dör. 8Om vi har mat och kläder, så ska vi vara nöjda. 9De som vill bli rika råkar ut för många frestelser och faller offer för dåraktiga och skadliga begär som störtar människor i fördärv och undergång. 10Kärleken till pengar är roten till allt ont. Genom den har många övergett sin tro och vållat sig själva mycket lidande.

Slutliga anvisningar

11Men du som tillhör Gud ska hålla dig borta från allt detta och sträva efter rättfärdighet, gudsfruktan, tro, kärlek, tålamod och mildhet. 12Kämpa trons goda kamp. Håll fast vid det eviga livet, som du kallades till när du avlade den goda trosbekännelsen inför många vittnen.

13Jag uppmanar dig inför Gud, som ger liv åt allt, och inför Kristus Jesus, som med en god bekännelse vittnade inför Pontius Pilatus: 14bevara denna befallning, så att det inte finns något befläckat eller något att anklaga dig för, till den dag vår Herre Jesus Kristus kommer tillbaka, 15som den salige och ende härskaren ska låta oss få se när tiden är inne, han som är alla kungars Kung och alla herrars Herre, 16han som är den ende som är odödlig och bor i ett ljus som ingen människa kan närma sig. Ingen människa har någonsin sett honom eller kan se honom. Hans är äran och makten i all evighet. Amen.

17Varna dem som är rika i den här världen att inte skryta och inte sätta sitt hopp till något så osäkert som rikedomar, utan till Gud, som ger oss allt vi behöver för att kunna njuta av livet. 18Säg åt dem att göra gott, så att de blir rika på goda gärningar i stället, och uppmana dem att vara generösa och dela med sig av det de har. 19Då samlar de sig en skatt, en god grund för framtiden, och de vinner det verkliga livet.

20Käre Timotheos, bevara det som har anförtrotts dig. Håll dig borta från gudlöst prat och motstridiga idéer som kallas kunskap men inte är det. 21En del har börjat lita på den och irrat sig bort från tron.

Nåd åt er alla.