1 Tẹsalonika 4 – YCB & NUB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Tẹsalonika 4:1-18

Gbígbé ìgbé ayé tó wu Ọlọ́run

1Ní ìparí, ará, a sọ fún un yín bí ẹ ti ń gbé láti wu Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí ń ṣe. Nísinsin yìí, a béèrè, a sì ń rọ̀ yín nínú Jesu Olúwa láti ṣe bẹ́ẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ sí. 2Nítorí pé, ẹ̀yin mọ àṣẹ tí a pa fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jesu.

34.3: 1Kọ 6.18.Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ́, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, 44.4: 1Kọ 7.2; 1Pt 3.7.kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti ṣàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá, 5kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run; 6àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni nínú yín máa ṣe rẹ arákùnrin rẹ̀ jẹ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. 7Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú ìwà èérí, bí kò ṣe sínú ìgbé ayé mímọ́. 8Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.

9Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 114.11: Ef 4.28; 2Tẹ 3.10-12.Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.

Ìpadàbọ̀ wá olúwa

134.13: Ef 2.12.Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí. 144.14: 2Kọ 4.14.A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá. 15Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀. 164.16: Mt 24.31; 1Kọ 15.23; 2Tẹ 2.1.Nítorí pé, Olúwa fúnrarẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde. 17Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé. 18Nítorí náà, ẹ tu ara yín nínú, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

Swedish Contemporary Bible

1 Thessalonikerbrevet 4:1-18

Lev så att ni ärar Gud

1Syskon, låt mig tillägga detta: Ni har fått lära er av oss hur man lever för att behaga Gud, och så lever ni också. Men vi vädjar till er för Herren Jesus skull att göra det ännu mer. 2Ni vet vilka föreskrifter vi gav er från Herren Jesus.

3För detta är Guds vilja: att ni ska bli heliga. Ni ska hålla er borta från all sexuell omoral. 4Var och en ska lära sig att behärska sin egen kropp4:4 Ordagrant: …hur han ska behandla sitt eget kärl. Annan tolkning: Var och en ska skaffa en egen hustru i helighet och ära. i helighet och ära, 5så att han inte lever i begär och lidelser, som hedningar som inte känner Gud. 6Ingen får kränka eller utnyttja någon annan troende på det här området, för Herren straffar allt sådant, det har vi redan klart och tydligt talat om för er. 7Gud har ju inte kallat oss till att leva i orenhet, utan till att leva i helighet. 8Den som förkastar detta, gör det inte mot människor, utan mot Gud som ger er sin heliga Ande.

9När det gäller att älska varandra som trossyskon, behöver jag inte skriva till er. Gud själv har ju lärt er att älska varandra, 10och er kärlek till alla de troende i hela Makedonien har redan vuxit sig stark. Trots det, syskon, ber vi er att göra ännu mer. 11Sätt en ära i att leva ett stilla liv, att försörja er själva och sköta ert arbete, precis som vi tidigare har sagt. 12Då kommer ni att bli respekterade av människor utanför församlingen och blir inte beroende av någon.

Vi ska uppstå från de döda

13Syskon, vi vill också att ni ska veta hur det går med dem som dör, för att ni inte ska sörja som de andra som inte har något hopp. 14När vi tror att Jesus har dött och uppstått, tror vi att Gud tillsammans med honom också ska föra till sig alla troende som har dött. 15Vi vill meddela er det som Herren själv har lärt oss: Vi som fortfarande lever när Herren kommer tillbaka ska inte komma före de döda. 16När Herren själv kommer ner från himlen, och en befallning hörs, ljudet av en ärkeängels röst och en Guds trumpet, då ska alla som har dött i Kristus uppstå först. 17Efter det ska vi, som fortfarande lever och finns kvar på jorden, föras bort bland molnen tillsammans med dem för att möta Herren i luften. Och sedan ska vi för alltid vara med honom. 18Trösta och uppmuntra nu varandra med dessa ord.