1 Samuẹli 30 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 30:1-31

Dafidi pa gbogbo àwọn Amaleki

1Ó sì ṣe nígbà ti Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì bọ̀ sí Siklagi ní ọjọ́ kẹta, àwọn ará Amaleki sì ti kọlu ìhà gúúsù, àti Siklagi, wọ́n sì ti kùn ún ní iná. 2Wọ́n sì kó àwọn obìnrin tí ń bẹ nínú rẹ̀ ní ìgbèkùn, wọn kò sì pa ẹnìkan, ọmọdé tàbí àgbà, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ.

3Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin sì wọ ìlú Siklagi, sì wò ó, a ti kùn ún ni iná; àti obìnrin wọn, àti ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn ni a kó ni ìgbèkùn lọ. 4Dafidi àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sọkún. 5A sì kó àwọn aya Dafidi méjèèjì nígbèkùn lọ, Ahinoamu ará Jesreeli àti Abigaili aya Nabali ará Karmeli. 6Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

7Dafidi sì wí fún Abiatari àlùfáà, ọmọ Ahimeleki pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú efodu fún mi wá níhìn-ín yìí. Abiatari sì mú efodu náà wá fún Dafidi. 8Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa: nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”

9Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi Àfonífojì Besori, apá kan sì dúró. 10Ṣùgbọ́n Dafidi àti irínwó ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, tiwọn kò lè kọjá odò Besori sì dúró lẹ́yìn.

11Wọ́n sì rí ará Ejibiti kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu. 12Wọ́n sì fún un ní àkàrà, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti síírí àjàrà gbígbẹ́ méjì: nígbà tí ó sì jẹ ẹ́ tán, ẹ̀mí rẹ̀ sì sọjí: nítorí pé kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi ní ọjọ́ mẹ́ta ní ọ̀sán, àti ní òru.

13Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?”

Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Ejibiti ni èmi, ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Amaleki. Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ọjọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn. 14Àwa sì gbé ogun lọ sí ìhà gúúsù tí ará Kereti, àti sí ìhà ti Juda, àti sí ìhà gúúsù ti Kalebu; àwa sì kun Siklagi ní iná.”

15Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí?”

Òun sì wí pé, “Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́; èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ.”

16Ó sì mú un sọ̀kalẹ̀, sì wò ó, wọ́n sì tàn ká ilẹ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ìkógun púpọ̀ tí wọ́n kó láti ilẹ̀ àwọn Filistini wá, àti láti ilẹ̀ Juda. 17Dafidi sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ọjọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irínwó ọmọkùnrin tí wọ́n gun ìbákasẹ tí wọ́n sì sá. 18Dafidi sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki ti kó: Dafidi sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì. 19Kò sì ṣí nǹkan tí ó kù fún wọn, kékeré tàbí ńlá, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, tàbí ìkógun, tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ti kó: Dafidi sì gba gbogbo wọn. 20Dafidi sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáájú àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dafidi.”

Dafidi sí pín ìkógun náà

21Dafidi sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, tiwọn kò lè tọ́ Dafidi lẹ́yìn mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni àfonífojì Besori: wọ́n sì lọ pàdé Dafidi, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dafidi sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn. 22Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Beliali nínú àwọn tí o bá Dafidi lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”

23Dafidi sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́ ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́. 24Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọ̀ràn yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.” 25Láti ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Israẹli títí di òní yìí.

26Dafidi sì padà sí Siklagi, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbàgbà Juda, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀tá Olúwa wa.”

27Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Beteli àti sí àwọn tí ó wà ní gúúsù tí Ramoti, àti sí àwọn tí ó wà ní Jattiri. 28Àti sí àwọn tí ó wà ní Aroeri, àti sí àwọn tí ó wà ní Sifimoti, àti sí àwọn tí ó wà ni Eṣitemoa. 29Àti si àwọn tí ó wà ni Rakeli, àti sí àwọn tí ó wà ní ìlú àwọn Jerahmeeli, àti sí àwọn tí ó wà ni ìlú àwọn ará Keni, 30àti sí àwọn tí ó wà ni Horma, àti sí àwọn ti ó wà ní Bori-Aṣani, àti sí àwọn tí ó wà ni Ataki. 31Àti àwọn tí ó wà ni Hebroni, àti sí gbogbo àwọn ìlú ti Dafidi tìkára rẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìn ká.

Korean Living Bible

사무엘상 30:1-31

아말렉군에 대한 다윗의 보복

1다윗과 그의 부하들이 30:1 또는 ‘제 삼 일에’이틀 후에 자기들이 사는 시글락으로 돌아왔 을 때 그들은 아말렉 사람들이 자기들의 성을 습격하여 불사르고

2거기에 남아 있던 여자들과 아이들을 모조리 끌어간 사실을 알게 되었다.

3다윗과 그의 부하들은 잿더미로 변한 그들의 성을 보고 그들의 가족들에게 일어난 일을 생각하며

4울 기력이 없을 때까지 큰 소리로 울었다.

5다윗의 두 아내 아히노암과 아비가일도 포로로 잡혀갔다.

6다윗은 입장이 대단히 난처하게 되었다. 왜냐하면 그의 부하들이 잃어버린 자식들 때문에 몹시 슬퍼하며 그를 돌로 쳐서 죽이려고 했기 때문이었다. 그러나 다윗은 그의 하나님 여호와를 의지하고 용기를 얻었다.

7그때 다윗은 아비아달 제사장에게 “에봇을 가져오시오” 하였다. 아비아달이 에봇을 다윗에게 가져오자

8그는 여호와께 “내가 저 침략자들을 따라가서 잡을까요?” 하고 물었다. 그러자 여호와께서는 “좋다. 그들을 쫓아가거라. 네가 빼앗긴 모든 것을 도로 찾을 것이다” 하고 말씀하셨다.

9-10그래서 다윗과 그의 부하 600명은 아 말렉군의 추격에 나섰다. 그들이 브솔 시내에 이르렀을 때 그들 중 200명은 너무 지쳐서 그 시내를 건너지 못하고 나머지 400명만 시내를 건너갔다.

11-12다윗의 부하들은 추격을 계속하던 중 들에서 이집트 청년 하나를 만나 그를 다윗에게 데리고 왔다. 그는 3일 동안 물 한 모금 마시지 못하고 아무것도 먹지 못한 채 기진 맥진해 있었다. 그래서 그들이 무화과 뭉치에서 뗀 덩이 하나와 건포도 두 송이와 물을 그에게 주자 그는 그것을 먹고 곧 힘을 얻어 정신을 차렸다.

13이때 다윗이 그에게 물었다. “너는 누구며 어디서 왔느냐?” “나는 이집트 사람이며 아말렉 사람의 종입니다. 내가 병이 들자 주인은 3일 전에 나를 버려 두고 떠났습니다.

14우리는 네겝에 있는 그렛 사람의 땅과 유다 남쪽 지방과 갈렙 사람의 땅을 침략하고 시글락을 불살랐습니다.”

15“그러면 그들이 어디로 갔는지 나에게 말해 줄 수 있겠느냐?” “만일 당신이 나를 죽이거나 내 주인에게 넘겨 주지 않겠다고 하나님의 이름으로 맹세한다면 내가 당신을 그들에게 인도하겠습니다.”

16그래서 그는 다윗과 그 부하들을 아말렉군이 있는 곳으로 인도하였다. 이때 아말렉군은 이곳 저곳 사방에 흩어져서 먹고 마시며 춤을 추고 있었는데 이것은 그들이 블레셋 사람과 유다 사람들에게서 약탈해 온 엄청난 전리품 때문이었다.

17다윗과 그의 부하들은 그들을 기습하여 다음날 저녁까지 계속 쳤으므로 낙타를 타고 도주한 400명의 청년들 외에는 살아 남은 자가 없었다.

18-19다윗은 아말렉 사람들이 약탈해 간 것을 모두 되찾고 그의 두 아내도 찾았으며 그의 부하들도 잃었던 그들의 가족과 소유물을 도로 찾았다.

20또 그들은 모든 양떼와 소떼를 약탈하여 몰고 오면서 “이것은 다윗의 약탈물이다!” 하고 외쳤다.

21그들이 브솔 시내까지 왔을 때 지쳐서 그 곳에 남아 있던 200명의 병력이 다윗과 그의 부하들을 환영하러 나왔다. 그래서 다윗은 그들을 따뜻이 맞아 주었다.

22그러나 참전한 다윗의 부하들 중에 악한 건달들이 “저들은 우리와 함께 가지 않았습니다. 그러므로 저들은 전리품을 하나도 가질 자격이 없습니다. 저들에게 아내와 자식들만 주어서 떠나게 하십시오” 하였다.

23그러나 다윗은 이렇게 대답하였다. “내 형제들아, 그건 안 된다. 여호와께서 우리를 안전하게 지키시고 우리를 도와 원수들을 쳐부수게 하셨다.

24너희가 이런 말을 한다고 들어 줄 사람이 있겠느냐? 전쟁터에 직접 나가 싸운 사람이나 여기에 남아 우리의 소유물을 지킨 사람이나 다 같이 전리품을 나누어 가져야 한다.”

25다윗은 이것을 하나의 법으로 정했으며 그때부터 이것은 이스라엘에서 계속 지켜졌다.

26다윗은 시글락에 돌아와서 전리품의 일부를 30:26 또는 ‘그 친구 유다 장로들’유다 장로들에게 보냈는데 그는 “내가 여호와의 원수들에게서 뺏은 전리품을 여러분에게 선물로 드립니다” 라는 말과 함께

27-31그것을 다음 지역의 장로들에게 보냈 다: 벧엘, 네겝의 라못, 얏딜, 아로엘, 십못, 에스드모아, 라갈, 여라므엘 사람의 성들과 겐 사람의 성들, 호르마, 볼 – 아산, 아닥, 헤브론, 그리고 다윗과 그의 부하들이 왕래하던 모든 곳이었다.