1 Samuẹli 2 – YCB & NVI-PT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 2:1-36

Àdúrà Hana

1Hana sì gbàdúrà pé:

“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;

Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.

Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi,

nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.

2“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;

kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;

kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

3“Má ṣe halẹ̀;

má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde

nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,

láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

4“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,

àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.

5Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,

àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.

Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.

Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.

6Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;

ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.

7Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;

ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.

8Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,

ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,

láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,

láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo:

“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,

ó sì ti gbé ayé ka orí wọn

9Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,

àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.

“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.

10A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;

láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;

Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,

yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.”

11Elkana sì lọ sí Rama sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà.

Àwọn ọmọ Eli búburú

12Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa. 13Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. 14Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo. 15Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.”

16Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́,” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”

17Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.

18Ṣùgbọ́n Samuẹli ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní efodu ọ̀gbọ̀. 19Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mú wá fún un lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún. 20Eli súre fún Elkana àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn. 21Olúwa si bojú wo Hana, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Samuẹli ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.

22Eli sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Israẹli; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 23Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. 24Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹ̀yin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀. 25Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, ta ni yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.

26Ọmọ náà Samuẹli ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú.

Wòlíì sọtẹ́lẹ̀ nípa ilé Eli

27Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao. 28Èmi sì yàn án kúrò láàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rú ẹbọ lórí pẹpẹ mi, láti fi tùràrí jóná, láti wọ efodu níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Israẹli máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀. 29Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo pàṣẹ ní ibùjókòó mi: ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jù mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Israẹli àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’

30“Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí. 31Kíyèsi i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ. 32Ìwọ yóò rí wàhálà ti Àgọ́, nínú gbogbo ọlá tí Ọlọ́run yóò fi fún Israẹli; kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láéláé. 33Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ní ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sọkún yọ lójú àti láti banújẹ́: Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.

34“ ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, yóò jẹ́ ààmì fún ọ—àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà. 35Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi: Èmi yóò fi ẹsẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo. 36Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”

Nova Versão Internacional

1 Samuel 2:1-36

A Oração de Ana

1Então Ana orou assim:

“Meu coração exulta no Senhor;

no Senhor minha força2.1 Hebraico: meu chifre; também no versículo 10. é exaltada.

Minha boca se exalta sobre os meus inimigos,

pois me alegro em tua libertação.

2“Não há ninguém santo2.2 Ou Não há nenhum Santo como o Senhor;

não há outro além de ti;

não há rocha alguma como o nosso Deus.

3“Não falem tão orgulhosamente,

nem saia de sua boca tal arrogância,

pois o Senhor é Deus sábio;

é ele quem julga os atos dos homens.

4“O arco dos fortes é quebrado,

mas os fracos são revestidos de força.

5Os que tinham muito agora trabalham por comida,

mas os que estavam famintos agora não passam fome.

A que era estéril deu à luz sete filhos,

mas a que tinha muitos filhos ficou sem vigor.

6“O Senhor mata e preserva a vida;

ele faz descer à sepultura2.6 Hebraico: Sheol. Essa palavra também pode ser traduzida por profundezas, ou morte. e dela resgata.

7O Senhor é quem dá pobreza e riqueza;

ele humilha e exalta.

8Levanta do pó o necessitado

e do monte de cinzas ergue o pobre;

ele os faz sentar-se com príncipes

e lhes dá lugar de honra.

“Pois os alicerces da terra são do Senhor;

sobre eles estabeleceu o mundo.

9Ele guardará os pés dos seus santos,

mas os ímpios serão silenciados nas trevas,

pois não é pela força que o homem prevalece.

10Aqueles que se opõem ao Senhor serão despedaçados.

Ele trovejará do céu contra eles;

o Senhor julgará até os confins da terra.

“Ele dará poder a seu rei

e exaltará a força do seu ungido”.

11Então Elcana voltou para casa em Ramá, mas o menino começou a servir o Senhor sob a direção do sacerdote Eli.

A Maldade dos Filhos de Eli

12Os filhos de Eli eram ímpios; não se importavam com o Senhor 13nem cumpriam os deveres de sacerdotes para com o povo; sempre que alguém oferecia um sacrifício, o auxiliar do sacerdote vinha com um garfo de três dentes, 14e, enquanto a carne estava cozinhando, ele enfiava o garfo na panela, ou travessa, ou caldeirão, ou caçarola, e o sacerdote pegava para si tudo o que vinha no garfo. Assim faziam com todos os israelitas que iam a Siló. 15Mas, antes mesmo de queimarem a gordura, vinha o auxiliar do sacerdote e dizia ao homem que estava oferecendo o sacrifício: “Dê um pedaço desta carne para o sacerdote assar; ele não aceitará de você carne cozida, somente crua”.

16Se o homem lhe dissesse: “Deixe primeiro a gordura se queimar e então pegue o que quiser”, o auxiliar respondia: “Não. Entregue a carne agora. Se não, eu a tomarei à força”.

17O pecado desses jovens era muito grande à vista do Senhor, pois eles estavam tratando com desprezo a oferta do Senhor.

18Samuel, contudo, ainda menino, ministrava perante o Senhor, vestindo uma túnica de linho. 19Todos os anos sua mãe fazia uma pequena túnica e a levava para ele, quando subia a Siló com o marido para oferecer o sacrifício anual. 20Eli abençoava Elcana e sua mulher, dizendo: “O Senhor dê a você filhos desta mulher no lugar daquele por quem ela pediu e dedicou ao Senhor”. Então voltavam para casa. 21O Senhor foi bondoso com Ana; ela engravidou e deu à luz três filhos e duas filhas. Enquanto isso, o menino Samuel crescia na presença do Senhor.

22Eli, já bem idoso, ficou sabendo de tudo o que seus filhos faziam a todo o Israel e que eles se deitavam com as mulheres que serviam junto à entrada da Tenda do Encontro. 23Por isso lhes perguntou: “Por que vocês fazem estas coisas? De todo o povo ouço a respeito do mal que vocês fazem. 24Não, meus filhos; não é bom o que escuto se espalhando no meio do povo do Senhor. 25Se um homem pecar contra outro homem, os juízes poderão2.25 Ou Deus poderá intervir em seu favor; mas, se pecar contra o Senhor, quem intercederá por ele?” Seus filhos, contudo, não deram atenção à repreensão de seu pai, pois o Senhor queria matá-los.

26E o menino Samuel continuava a crescer, sendo cada vez mais estimado pelo Senhor e pelo povo.

Profecia contra a Família de Eli

27E veio um homem de Deus a Eli e lhe disse: “Assim diz o Senhor: ‘Acaso não me revelei claramente à família de seu pai, quando eles estavam no Egito, sob o domínio do faraó? 28Escolhi seu pai dentre todas as tribos de Israel para ser o meu sacerdote, subir ao meu altar, queimar incenso e usar um colete sacerdotal na minha presença. Também dei à família de seu pai todas as ofertas preparadas no fogo pelos israelitas. 29Por que vocês zombam de meu sacrifício e da oferta que determinei para a minha habitação? Por que você honra seus filhos mais do que a mim, deixando-os engordar com as melhores partes de todas as ofertas feitas por Israel, o meu povo?’

30“Portanto, o Senhor, o Deus de Israel, declara: ‘Prometi à sua família e à linhagem de seu pai que ministrariam diante de mim para sempre’. Mas agora o Senhor declara: ‘Longe de mim tal coisa! Honrarei aqueles que me honram, mas aqueles que me desprezam serão tratados com desprezo. 31É chegada a hora em que eliminarei a sua força e a força da família2.31 Hebraico: cortarei o seu braço e o braço da casa. de seu pai, e não haverá mais nenhum idoso na sua família, 32e você verá aflição na minha habitação. Embora Israel prospere, na sua família ninguém alcançará idade avançada. 33E todo descendente seu que eu não eliminar de meu altar será poupado apenas para consumir os seus olhos com lágrimas2.33 Ou cegar os olhos; ou ainda consumir os olhos de inveja e para entristecer o seu coração, e todos os seus descendentes morrerão no vigor da vida.

34“ ‘E o que acontecer a seus dois filhos, Hofni e Fineias, será um sinal para você: os dois morrerão no mesmo dia. 35Levantarei para mim um sacerdote fiel, que agirá de acordo com o meu coração e o meu pensamento. Edificarei firmemente a família dele, e ele ministrará sempre perante o meu rei ungido. 36Então todo o que restar da sua família virá e se prostrará perante ele, para obter uma moeda de prata e um pedaço de pão. E lhe implorará que o ponha em alguma função sacerdotal, para ter o que comer’ ”.