1 Peteru 1 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Peteru 1:1-25

1Peteru, aposteli Jesu Kristi,

Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia, 2àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi:

Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.

Ìyìn sí Ọlọ́run fún ìrètí tó wà láààyè

3Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́: 7Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.

10Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. 11Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. 12Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.

Ẹ jẹ́ mímọ́

13Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 161.16: Le 11.44-45.Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”

17Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín, 21Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

22Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 241.24-25: Isa 40.6-9.Nítorí pé,

“Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,

àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.

Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,

25Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”

Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìhìnrere tí a wàásù fún yín.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

彼得前書 1:1-25

1我是耶穌基督的使徒彼得,寫信給蒙上帝揀選,寄居在本都加拉太加帕多迦亞細亞庇推尼各地的人。 2你們蒙揀選是按照父上帝預先定好的旨意,藉著聖靈得以聖潔,好順服耶穌基督,並靠祂的血得到潔淨。

願上帝賜給你們豐豐富富的恩典和平安!

活潑的盼望

3願頌讚歸於我們主耶穌基督的父上帝!祂有無窮的憐憫,藉著耶穌基督從死裡復活使我們獲得重生,有活潑的盼望, 4可以承受那不會朽壞、沒有污點、不會衰殘、為你們存留在天上的產業。 5你們這些因信而蒙上帝用大能保守的人,必能得到那已經預備好、在末世要顯明的救恩。

6為此,即使現今你們必須暫時在百般試煉中忍受痛苦,也要滿懷喜樂。 7這樣,你們的信心經過試驗便顯明是真實的,比那經過火煉仍會壞掉的金子更加寶貴,使你們可以在耶穌基督顯現時得到稱讚、榮耀和尊貴。 8你們雖然沒有見過基督,卻愛祂;雖然現在看不見祂,卻信祂,並且有無法形容、充滿榮耀的喜樂。 9因為你們得到了信心帶來的果效,就是你們的靈魂得救。

10有關這救恩,那些預言恩典要臨到你們的眾先知早已詳細尋求查考了。 11基督的靈曾在他們心中指示他們,預言基督要受苦,然後得榮耀。他們便詳細查考這些事會在什麼時候、什麼情況下發生。 12他們得到啟示,知道他們傳講這些事不是為了自己,而是為了你們。現在,那些靠著從天上差來的聖靈向你們傳福音的人,已經將這些事傳給你們了。連天使也想把這些事看個明白。

要聖潔像主

13所以,要預備好你們的心,謹慎自律,專心盼望耶穌基督顯現時要帶給你們的恩典。 14你們既是順服的兒女,就不要再像從前無知的時候那樣放縱私慾。 15那呼召你們的是聖潔的,你們在一切事上也要聖潔。 16因為聖經上說:「你們要聖潔,因為我是聖潔的。」

17既然你們稱呼那位按各人的行為公正無私地審判人的上帝為父,就應該存著敬畏的心過你們在世上寄居的日子。 18要知道,你們從傳統的、沒有意義的生活中被救贖出來,不是靠金銀等會朽壞的東西, 19而是靠無瑕無疵的代罪羔羊——基督的寶血。 20基督是上帝在創世以前預先揀選的,卻在這末世為你們顯現。 21你們藉著基督信了使祂從死裡復活、賜祂榮耀的上帝,所以,你們的信心和盼望都在於上帝。

22你們既因順服真理,潔淨了自己的心,能夠真誠地愛弟兄姊妹,就當以清潔的心彼此切實相愛。 23你們獲得重生,不是藉著會腐爛的種子,而是藉著不會腐爛的種子——上帝活潑永存的道。 24因為

「芸芸眾生盡如草,

榮華不過草上花;

草必枯乾花必殘,

25唯有主道永長存。」

這道就是傳給你們的福音。