1 Kronika 28 – YCB & CARS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 28:1-21

Àwọn èrò Dafidi lórí ilé Olúwa

1Dafidi pe gbogbo àwọn oníṣẹ́ ti Israẹli láti péjọ ní Jerusalẹmu: Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóso ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn oníṣẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀.

2Ọba Dafidi dìde dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀, o sì wí pé “Fetísílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni lọ́kàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ. 3Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀ sílẹ̀”.

4“Síbẹ̀ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Israẹli, títí láé. Ó yan Juda gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Juda, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Israẹli. 5Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú Olúwa ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Solomoni láti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba ti Olúwa lórí Israẹli. 6Ó wí fún mi pé, Solomoni ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, Nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a rẹ̀. 7Èmi yóò fi ìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.

8“Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsin yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Israẹli àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí Olúwa, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa: Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé.

9“Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí Olúwa ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé. 10Gbèrò báyìí nítorí tí Olúwa ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún Olúwa. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.”

11Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé Olúwa náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú. 12Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn rẹ̀ fún ti ààfin ilé Olúwa àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀. 13Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn rẹ̀. 14Ó yàn ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà tí a ó lò níbi oríṣìí ìsìn, àti ìwọ̀n fàdákà fún gbogbo ohun èlò fàdákà tí a ó lò fún oríṣìí ìsìn: 15Ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn; àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtílà fàdákà àti àwọn fìtílà rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìdúró fìtílà. 16Ìwọ̀n ti wúrà fun tábìlì, tábìlì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀; ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà; 17Ìwọ̀n kìkì wúrà fún àwọn àmúga ìjẹun, àwọn ìbùwọ́n ọpọ́n àti àwọn ìkòkò ìpọnmi; ìwọ̀n wúrà fún gbogbo àwopọ̀kọ́ fàdákà; 18Àti ìwọ̀n ìdá wúrà fún Pẹpẹ tùràrí ó fún un ní ètò fún kẹ̀kẹ́, ìyẹn ni pé àwọn ìdúró kérúbù wúrà tí wọ́n tan iye wọn ká, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí Olúwa.

19“Gbogbo èyí,” ni Dafidi wí pé, “Èmi ní kíkọ sílẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa sórí mi, ó sì fún mí ní ìmọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ ètò yìí.”

20Dafidi tún sọ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára kí o sì gbóyà, kí o sì ṣe iṣẹ́ náà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí dààmú, nítorí Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ. Òun kì yóò sì jọ ọ kule tàbí kọ Ọ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ fún ìsìn ní ti ilé Olúwa yóò fi parí. 21Ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ṣetán fún gbogbo iṣẹ́ ilé Olúwa. Gbogbo ọkùnrin tí ó ní ìfẹ́ sí i tí ó sì ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn yóò gbọ́rọ̀ sí gbogbo àṣẹ rẹ.”

Священное Писание

1 Летопись 28:1-21

Замыслы Давуда о храме

1Давуд собрал в Иерусалиме всех сановников Исраила: вождей родов, начальников во главе воинских отделений, которые служили царю, тысячников и сотников, сановников, надзирающих за всем добром и скотом, принадлежащим царю и его сыновьям, и придворных вместе с могучими и доблестными воинами.

2Царь Давуд встал и сказал:

– Послушайте меня, мои братья и мой народ! Я хотел построить дом, чтобы там покоился сундук соглашения с Вечным – подножие для ног нашего Бога, и сделал приготовления к строительству. 3Но Всевышний сказал мне: «Ты не построишь дома для поклонения Мне, потому что ты воин и проливал кровь». 4Но Вечный, Бог Исраила, избрал меня из всей моей семьи, чтобы мои потомки были царями Исраила навеки. Он избрал Иуду вождём28:4 См. Нач. 49:10., из дома Иуды избрал мою семью, а из всех сыновей моего отца Ему было угодно сделать царём всего Исраила меня28:4 См. 1 Цар. 16:1-3.. 5Из всех моих сыновей – а Вечный дал мне их много – Он избрал моего сына Сулеймана, чтобы он сел на престоле царства Вечного над Исраилом28:5 См. 22:9, а также 2 Цар. 7:12; 12:24-25.. 6Он сказал мне: «Сулейман, твой сын, построит Мой дом и Мои дворы, потому что Я избрал его, чтобы он был Мне сыном, а Я буду ему Отцом. 7Я утвержу его царство навеки, если он будет неуклонно исполнять Мои повеления и законы, как это делается сейчас».

8И теперь, перед глазами всего Исраила и собрания Вечного, вслух перед нашим Богом, я поручаю вам: тщательно исполняйте все повеления Вечного, вашего Бога, чтобы вам всегда владеть этой прекрасной землёй и передать её в вечное наследие вашим потомкам.

9И ты, Сулейман, сын мой, знай Бога твоего отца и служи Ему всем сердцем и всей душой, ведь Вечный испытывает всякое сердце и понимает всякий замысел и всякую мысль. Если ты будешь искать Его, то найдёшь Его, но если ты оставишь Его, Он отвергнет тебя навсегда. 10Смотри же, ведь Вечный избрал тебя, чтобы ты построил дом для святилища. Будь твёрд и действуй!

11И Давуд отдал своему сыну Сулейману план притвора храма, его зданий, кладовых, верхних помещений, внутренних комнат и места для очищения грехов. 12Он отдал ему чертежи всего, что у него было на душе28:12 Или: «что было открыто ему Духом». относительно двора вокруг дома Вечного, всех комнат вокруг него, сокровищниц дома Всевышнего и сокровищниц для посвящённых вещей. 13Он дал ему наставления о священнослужителях и левитах, о всём деле служения в храме Вечного и обо всех предметах, которыми пользуются при службе. 14Он установил, сколько должны весить золотые предметы для различных служений и сколько – серебряные: 15сколько золота и серебра должно пойти на каждый подсвечник и светильник, в зависимости от его назначения; 16сколько золота должно пойти на столы для священного хлеба и сколько серебра – на столы серебряные; 17сколько чистого золота нужно на вилки, кропильные чаши и кувшины; сколько золота и серебра на блюда 18и сколько очищенного золота на жертвенник для возжигания благовоний. Ещё он отдал ему план для колесницы с херувимами из золота, которые простирали свои крылья над сундуком соглашения с Вечным, укрывая его.

19– Всё это, – сказал Давуд, – заключено в плане, написанном по указаниям, которые Вечный Сам дал мне.

20Ещё Давуд сказал своему сыну Сулейману:

– Будь твёрд и мужествен и действуй! Не бойся, не падай духом, потому что Вечный Бог, мой Бог, с тобой. Он не покинет и не оставит тебя, пока не будет завершена вся работа над храмом Вечного. 21Священнослужители и левиты готовы к любой работе в храме Всевышнего, и всякий доброволец, искусный в каком бы то ни было ремесле, будет помогать тебе в работе, а вельможи и весь народ будут слушаться всех твоих повелений.