1 Johanu 4 – Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn YCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Johanu 4:1-21

Ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò

1Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. 2Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni: 34.3: 1Jh 2.18.Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.

4Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ. 54.5: Jh 15.19.Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn. 64.6: Jh 8.47.Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.

Ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti àwa

74.7: 1Jh 2.29.Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa: nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run. 8Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run. 94.9: Jh 3.16.Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa, nítorí tí Ọlọ́run rán ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo sì ayé, kí àwa lè yè nípasẹ̀ rẹ̀. 104.10: Jh 15.12; 1Jh 4.19; 2.2.Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kì í ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òun fẹ́ wá, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. 11Olùfẹ́, bí Ọlọ́run bá fẹ́ wa báyìí, ó yẹ kí a fẹ́ràn ara wa pẹ̀lú. 124.12: Jh 1.18.Ẹnikẹ́ni kò ri Ọlọ́run nígbà kan rí. Bí àwa bá fẹ́ràn ara wa, Ọlọ́run ń gbé inú wa, a sì mú ìfẹ́ rẹ̀ pé nínú wa.

134.13: 1Jh 3.24.Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń gbé inú rẹ̀, àti Òun nínú wa, nítorí tí ó ti fi Ẹ̀mí rẹ̀ fún wa. 144.14: Jh 4.42; 3.17.Àwa tí rí, a sì jẹ́rìí pé Baba rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé. 15Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Ọmọ Ọlọ́run ni, Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú Ọlọ́run. 16Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́.

Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. 174.17: 1Jh 2.28.Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. 18Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́.

194.19: 1Jh 4.10.Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa. 204.20: 1Jh 2.4.Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, “Èmi fẹ́ràn Ọlọ́run,” tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀, èké ni: nítorí ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ tí ó rí, báwo ni yóò tí ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run tí òun kò rí? 21Òfin yìí ni àwa sì rí gbà láti ọwọ́ rẹ̀ wá, pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run kí ó fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.