1 Johanu 1 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Johanu 1:1-10

Ọ̀rọ̀ Ìyè

11.1-2: Lk 24.39; Jh 1.1; 4.14; 15.27; 20.20,25; Ap 4.20; 1Jh 2.13.Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú; èyí tí a kéde; ní ti ọ̀rọ̀ ìyè; 2iyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rìí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa. 3Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. 41.4: Jh 15.11; 2Jh 12.Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.

Rírìn nínú ìmọ́lẹ̀

51.5: 1Jh 3.11.Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá. 61.6-8: Jh 3.2; 1Jh 2.4,11.Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́. 71.7: If 1.5.Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo.

8Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa. 9Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. 101.10: 1Jh 5.10.Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרתו הראשונה של יוחנן השליח 1:1-10

1אנחנו כותבים לכם על דבר־החיים אשר היה מבראשית: שמענו אותו באוזנינו וראינו אותו במו עינינו. אכן, הבטנו בו ונגענו בו בידינו. 2אנחנו מספרים לכם על המשיח, שהוא חיי הנצח, אשר היה עם האב בשמים ולאחר מכן נגלה אלינו. כן, אנו מעידים שישוע המשיח – החיים – נגלה אלינו. 3אני חוזר ואומר: ראינו אותו ושמענו אותו, ואנו מספרים לכם זאת כדי שגם אתם תיהנו מההתחברות שיש לנו עם אלוהים האב ועם בנו ישוע המשיח.

4אנו מספרים לכם זאת מסיבה נוספת: כדי שגם אתם תימלאו שמחה רבה כמונו.

5זאת הבשורה שאלוהים ביקש מאיתנו לבשר לכם: אלוהים הוא אור ואין בו כל חושך. 6אם אנו אומרים שיש לנו התחברות עם אלוהים בשעה שאנו חוטאים וחיים בחושך, אנחנו משקרים! 7אך אם אנו חיים באור אלוהים, כמו המשיח, כשדבריו תמיד לנגד עינינו, יש לנו התחברות נפלאה איש עם רעהו, והדם ששפך בעדנו ישוע המשיח מנקה ומטהר אותנו מכל חטא.

8אם אנו טוענים שאין בנו חטא, אנו משלים את עצמנו ומסרבים להכיר באמת. 9אך אם נתוודה על חטאינו (לפני אלוהים), אנו בטוחים שיסלח לנו ויטהר אותנו מכל רע. 10אם אנו מכחישים שחטאנו, לא זו בלבד שאנו משקרים, אנו עושים גם את אלוהים לשקרן, שכן הוא אמר שכולנו חטאנו.