1 Ọba 15 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 15:1-34

Abijah ọba Juda

115.1,2,7: 2Ki 13.1,2.Ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Jeroboamu ọmọ Nebati, Abijah jẹ ọba lórí Juda, 2ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́ta ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.

3Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. 4Ṣùgbọ́n, nítorí i Dafidi Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jerusalẹmu nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jẹ ọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀. 5Nítorí tí Dafidi ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pàṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Uriah ará Hiti.

6Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní gbogbo ọjọ́ ayé Abijah. 7Ní ti ìyókù ìṣe Abijah, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ogun sì wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. 815.8-12: 2Ki 14.1-5.Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Asa ọba Juda

9Ní ogún ọdún Jeroboamu ọba Israẹli, Asa jẹ ọba lórí Juda, 10Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ńlá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu.

11Asa sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. 12Ó sì mú àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò. 1315.13-22: 2Ki 15.16–16.6.Ó sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. 14Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Asa pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo. 15Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa.

16Ogun sì wà láàrín Asa àti Baaṣa ọba Israẹli ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. 17Baaṣa, ọba Israẹli sì gòkè lọ sí Juda, ó sì kọ́ Rama láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba lọ.

18Nígbà náà ni Asa mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Beni-Hadadi ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni ọba Siria tí ó ń gbé ní Damasku. 19Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrín èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Baaṣa, ọba Israẹli, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”

20Beni-Hadadi gba ti Asa ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Israẹli. Ó sì ṣẹ́gun Ijoni, Dani àti Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo Kinnereti pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. 21Nígbà tí Baaṣa sì gbọ́ èyí, ó sì ṣíwọ́ kíkọ́ Rama, ó sì lọ kúrò sí Tirsa. 22Nígbà náà ni Asa ọba kéde ká gbogbo Juda, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta Rama kúrò àti igi rẹ̀, tí Baaṣa fi kọ́lé. Asa ọba sì fi wọ́n kọ́ Geba ti Benjamini àti Mispa.

2315.23,24: 2Ki 16.12-14.Ní ti ìyókù gbogbo ìṣe Asa, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, ààrùn ṣe é ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 2415.24: 2Ki 17.1.Asa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Nadabu ọba Israẹli

25Nadabu ọmọ Jeroboamu sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún kejì Asa ọba Juda, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjì. 26Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà baba rẹ̀ àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó mú Israẹli dá.

27Baaṣa ọmọ Ahijah ti ilé Isakari sì dìtẹ̀ sí i, Baaṣa sì kọlù ú ní Gibetoni, ìlú àwọn ará Filistini, nígbà tí Nadabu àti gbogbo Israẹli dó ti Gibetoni. 28Baaṣa sì pa Nadabu ní ọdún kẹta Asa ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

29Ó sì ṣe, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba ó pa gbogbo ilé Jeroboamu, kò sì ku ẹnìkan tí ń mí fún Jeroboamu, ṣùgbọ́n ó run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ó sọ nípa ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ Ahijah ará Ṣilo: 30Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, àti nítorí tí ó ti mú Olúwa Ọlọ́run Israẹli bínú.

31Ní ti ìyókù ìṣe Nadabu àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? 32Ogun sì wà láàrín Asa àti Baaṣa ọba Israẹli ní gbogbo ọjọ́ wọn.

Baaṣa ọba Israẹli

33Ní ọdún kẹta Asa ọba Juda, Baaṣa ọmọ Ahijah sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli ní Tirsa, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́rìnlélógún. 34Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀.

Thai New Contemporary Bible

1พงศ์กษัตริย์ 15:1-34

กษัตริย์อาบียาห์แห่งยูดาห์

(2พศด.13:1-2,22—14:1)

1อาบียาห์15:1 สำเนาต้นฉบับภาษาฮีบรูส่วนใหญ่ว่าอาบียัมเช่นเดียวกับข้อ 7 และ 8ขึ้นเป็นกษัตริย์แห่งยูดาห์ตรงกับปีที่สิบแปดของรัชกาลเยโรโบอัมบุตรเนบัท 2พระองค์ทรงครองราชย์อยู่ในกรุงเยรูซาเล็มสามปี ราชมารดาคือมาอาคาห์ธิดาของอาบีชาโลม15:2 เป็นอีกรูปหนึ่งของอับซาโลมเช่นเดียวกับข้อ 10

3พระองค์ทรงทำบาปทุกอย่างเช่นเดียวกับราชบิดา และไม่ได้มีพระทัยภักดีแน่วแน่ต่อพระยาห์เวห์พระเจ้าของพระองค์เหมือนดาวิดบรรพบุรุษ 4แต่เพื่อเห็นแก่ดาวิด พระยาห์เวห์พระเจ้าของเขาทรงโปรดประทานดวงประทีปดวงหนึ่งในเยรูซาเล็ม โดยให้โอรสองค์หนึ่งขึ้นมาครองราชย์ต่อและทำให้เยรูซาเล็มเข้มแข็ง 5เพราะดาวิดได้ทำสิ่งที่ถูกต้องในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้า

ปฏิบัติตามพระบัญชาของพระองค์ทุกประการตลอดชีวิต ยกเว้นเรื่องที่เกี่ยวกับอุรียาห์ชาวฮิตไทต์

6ตลอดพระชนม์ชีพของอาบียาห์มีสงครามระหว่างเรโหโบอัม15:6 สำเนาต้นฉบับภาษาฮีบรูบางสำเนา และฉบับ Syr. ว่าอาบียัม(คือ อาบียาห์)กับเยโรโบอัม 7เหตุการณ์อื่นๆ ในรัชกาลอาบียาห์และพระราชกิจทั้งปวงมีบันทึกไว้ในจดหมายเหตุกษัตริย์แห่งยูดาห์ไม่ใช่หรือ? และมีสงครามระหว่างอาบียาห์กับเยโรโบอัม 8และอาบียาห์ทรงล่วงลับไปอยู่กับบรรพบุรุษและถูกฝังไว้ในเมืองดาวิด แล้วอาสาโอรสของพระองค์ขึ้นครองราชย์แทน

กษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์

(2พศด.14:2-3; 15:16—16:6; 16:11—17:1)

9อาสาขึ้นเป็นกษัตริย์แห่งยูดาห์ ตรงกับปีที่ยี่สิบของรัชกาลเยโรโบอัมแห่งอิสราเอล 10ทรงครองราชย์อยู่ 41 ปีในกรุงเยรูซาเล็ม เสด็จย่าของพระองค์คือมาอาคาห์ ธิดาของอาบีชาโลม

11อาสาทรงทำสิ่งที่ถูกต้องในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้าเหมือนดาวิดบรรพบุรุษ 12อาสาทรงเนรเทศโสเภณีชายประจำเทวสถานออกไปจากดินแดน และทรงขจัดเทวรูปทั้งปวงที่บรรพบุรุษสร้างขึ้น 13พระองค์ทรงถอดพระนางมาอาคาห์เสด็จย่าของพระองค์ออกจากตำแหน่งพระพันปีหลวง เพราะพระนางได้สร้างเสาเจ้าแม่อาเชราห์อันน่ารังเกียจ อาสาทรงโค่นเสานั้นและเผาทิ้งที่หุบเขาขิดโรน 14แม้พระองค์ไม่ได้ทรงรื้อสถานบูชาบนที่สูงทั้งหลายทิ้ง แต่พระทัยของอาสาก็ภักดีแน่วแน่ต่อองค์พระผู้เป็นเจ้าตลอดพระชนม์ชีพ 15พระองค์ทรงนำเงินและทองกับเครื่องใช้ไม้สอยต่างๆ ซึ่งพระองค์กับราชบิดาได้ถวายแด่พระเจ้ามาไว้ในพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า

16มีสงครามระหว่างอาสากับกษัตริย์บาอาชาแห่งอิสราเอลตลอดรัชกาล 17กษัตริย์บาอาชาแห่งอิสราเอลมาสู้รบกับยูดาห์ และบาอาชาทรงสร้างป้อมปราการที่เมืองรามาห์ เพื่อปิดทางเข้าออกสู่เขตแดนของกษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์

18อาสาจึงทรงนำเงินและทองคำที่เหลือทั้งหมดจากคลังพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า และจากท้องพระคลังของพระราชวังของพระองค์เองมามอบให้ข้าราชบริพารนำไปถวายกษัตริย์เบนฮาดัดแห่งอารัมซึ่งปกครองอยู่ที่เมืองดามัสกัส เบนฮาดัดนี้เป็นโอรสของทับริมโมน ซึ่งเป็นโอรสของเฮซีโอน กษัตริย์อาสาทูลว่า 19“ขอให้เราเป็นพันธมิตรกันเหมือนราชบิดาของเราทั้งสอง ข้าพเจ้าส่งเงินและทองนี้มากำนัลแด่ท่าน ขอให้ท่านตัดสัมพันธไมตรีกับกษัตริย์บาอาชาแห่งอิสราเอล เพื่อเขาจะได้ถอยทัพไปจากข้าพเจ้า”

20เบนฮาดัดทรงเห็นชอบกับกษัตริย์อาสา และทรงส่งแม่ทัพและกองกำลังไปโจมตีเมืองต่างๆ ของอิสราเอล ทรงพิชิตเมืองอิโยน ดาน อาเบลเบธมาอาคาห์ คินเนเรททั้งหมด รวมทั้งนัฟทาลี 21เมื่อบาอาชาทราบเรื่องนี้ก็หยุดการสร้างเมืองรามาห์ แล้วถอยทัพกลับไปยังทีรซาห์ 22จากนั้นกษัตริย์อาสาทรงเกณฑ์ทุกคนในยูดาห์ ไม่เว้นผู้ใดเลย ให้พวกเขาช่วยกันขนหินและไม้ซึ่งบาอาชาทรงใช้อยู่ที่เมืองรามาห์ นำไปสร้างเมืองเกบาในแดนเบนยามินและเมืองมิสปาห์

23เหตุการณ์อื่นๆ ในรัชกาลของอาสา ความสำเร็จทั้งปวง พระราชกิจทั้งสิ้น และเมืองต่างๆ ที่ทรงสร้างขึ้นมีบันทึกในจดหมายเหตุกษัตริย์แห่งยูดาห์ไม่ใช่หรือ? เมื่ออาสาทรงชราแล้วก็ทรงประชวรด้วยโรคที่พระบาท 24แล้วอาสาก็ทรงล่วงลับไปอยู่กับบรรพบุรุษ และถูกฝังไว้ด้วยกันในเมืองดาวิด และเยโฮชาฟัทโอรสของพระองค์ขึ้นครองราชย์แทน

นาดับแห่งอิสราเอล

25นาดับโอรสของเยโรโบอัมขึ้นเป็นกษัตริย์แห่งอิสราเอล ตรงกับปีที่สองของรัชกาลกษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์ ทรงครองราชย์เหนืออิสราเอลอยู่สองปี 26ทรงทำสิ่งที่ชั่วในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้า ดำเนินตามวิถีและบาปของราชบิดา ซึ่งชักนำอิสราเอลให้ทำตาม

27ฝ่ายบาอาชาบุตรอาหิยาห์เผ่าอิสสาคาร์วางแผนและลงมือสังหารนาดับ ขณะที่ทรงร่วมกับกองทัพอิสราเอลล้อมเมืองกิบเบโธนของฟีลิสเตีย 28บาอาชาปลงพระชนม์นาดับแล้วขึ้นครองราชย์แทน ตรงกับปีที่สามของรัชกาลกษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์

29ทันทีที่ขึ้นครองราชย์ บาอาชาก็ประหารวงศ์วานทั้งปวงของเยโรโบอัม ไม่ปล่อยให้ใครรอดชีวิตเลย เป็นไปตามที่องค์พระผู้เป็นเจ้าได้ตรัสไว้ผ่านทางอาหิยาห์ชาวชิโลห์ผู้รับใช้ของพระองค์ 30เพราะบาปที่เยโรโบอัมได้ทำและชักนำอิสราเอลให้ทำตาม และเพราะเขาได้ยั่วยุพระพิโรธของพระยาห์เวห์พระเจ้าแห่งอิสราเอล

31เหตุการณ์อื่นๆ ในรัชกาลของนาดับและพระราชกิจทั้งปวงมีบันทึกไว้ในจดหมายเหตุกษัตริย์แห่งอิสราเอลไม่ใช่หรือ? 32มีสงครามระหว่างอาสากับบาอาชากษัตริย์แห่งอิสราเอลตลอดรัชกาล

บาอาชาแห่งอิสราเอล

33บาอาชาบุตรอาหิยาห์ขึ้นเป็นกษัตริย์เหนือดินแดนอิสราเอลทั้งหมดที่เมืองทีรซาห์ ตรงกับปีที่สามของรัชกาลกษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์ ทรงครองราชย์อยู่ 24 ปี 34บาอาชาทรงทำสิ่งที่ชั่วในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้า ดำเนินตามวิถีและบาปของเยโรโบอัม ซึ่งชักนำให้อิสราเอลทำตาม