Ọbadiah 1 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ọbadiah 1:1-21

1Ìran ti Ọbadiah.

1-21: Isa 34; 63.1-6; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Am 1.11-12; Ml 1.2-5.Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.

Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá:

A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,

“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

2“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;

ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,

3Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,

ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,

tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,

ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,

‘ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’

4Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,

bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,

láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”

ni Olúwa wí.

5“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,

bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,

Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:

wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?

Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,

wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?

6Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,

tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.

7Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ

ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:

Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;

àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,

ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

8Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,

Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,

àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?

9A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Temani,

gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau

ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

10Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,

ìtìjú yóò bò ọ,

a ó sì pa ọ run títí láé.

11Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,

ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,

tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ

tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,

ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

12Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,

ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀

ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,

ní ọjọ́ ìparun wọn

ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀

ní ọjọ́ wàhálà wọn.

13Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,

ní ọjọ́ àjálù wọn.

Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀

nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.

Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,

ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

14Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà

láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.

Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú

wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

15“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé

lórí gbogbo àwọn kèfèrí.

Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;

ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.

16Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi

bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí

Wọn yóò mu wọn yóò sì mu àmutẹ́rùn

wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí

17Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni

Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́

àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn

18Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná

àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná

ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko

wọn yóò fi iná sí i,

wọn yóò jo run.

Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”

Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

19Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,

àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni

ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.

Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;

Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.

20Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani

yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;

àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi

yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní

21Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá

láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.

Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

俄巴底亚书 1:1-21

1俄巴底亚看到的异象。

耶和华惩罚以东

论到以东

主耶和华这样说:

“我们从耶和华那里听到消息,

有位使者被派到各国,说,

‘来!我们去攻打以东吧!’”

2耶和华对以东说:

“我要让你成为列国中最弱小的国家,

使你饱受藐视。

3你住在悬崖峭壁间,

住在高山上,

自以为谁也不能把你拉下来,

但你的骄傲欺骗了你。

4即使你如鹰高飞,

在星辰间筑巢,

我也必把你拉下来。

这是耶和华说的。

5“盗贼深夜洗劫你的家,

不会洗劫一空;

人们摘葡萄,不会摘光;

但你会被彻底毁灭!

6以扫1:6 以扫”又名“以东”。要被洗劫一空,

他藏的珍宝要被搜去。

7你的盟友将你逐出家园;

你的朋友欺骗你,战胜你;

你的知己设陷阱害你,

你却懵然不知。”

8耶和华说:“到那天,

我要毁灭以东的智者,

除掉以扫山上的明哲。

9提幔的勇士必惊慌失措,

以扫山上的人尽遭杀戮。

惩罚以东的原因

10“因你曾残暴地对待同胞兄弟雅各

你必蒙羞,永遭毁灭。

11外族人掠夺雅各的财物,

攻入耶路撒冷抽签分赃时,

你竟然袖手旁观,

就像他们的同伙一样。

12你的亲族遭难之日,

你不该幸灾乐祸;

犹大人被灭的日子,

你不该兴高采烈;

他们遭难的日子,

你不该口出狂言;

13我子民遭难的日子,

你不该闯进他们的城;

他们遭难的日子,

你不该幸灾乐祸;

他们遭难的日子,

你不该趁火打劫;

14你不该站在路口截杀那些逃亡者;

他们遭难的日子,

你不该把幸存者交给仇敌。

15“耶和华惩罚万国的日子近了。

必按你的所作所为报应你,

你的恶行必落到自己头上。

16你们犹大人在我的圣山上怎样饱饮愤怒,

万国也要照样饮,

且要大口吞下,

直到他们完全消逝。

以色列的复兴

17“然而,锡安山必成为避难所,

成为圣地。

雅各家必得到自己的产业。

18雅各家将成为火,

约瑟家将成为烈焰,

以扫家将成为碎秸,

被火焚烧、吞噬,无一人逃脱。

这是耶和华说的。

19“南地的人将占领以扫山;

丘陵的人将占领非利士

夺取以法莲撒玛利亚

便雅悯人将占领基列

20被掳的以色列人将返回家园,

占领远至撒勒法一带的土地;

耶路撒冷被掳到西法拉的人将占领南地各城。

21拯救者必登上锡安山,

统治以扫山,

耶和华必做王掌权。”