Ìfihàn 20 – YCB & HHH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 20:1-15

Ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún

1Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. 2O sì di Dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún ọdún. 3Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé: Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

420.4: Da 7.9,22,27.Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà ààmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún ọdún. 5Àwọn òkú ìyókù kò wà láààyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé. Èyí ni àjíǹde èkínní. 6Ẹni ìbùkún àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkínní náà: lórí àwọn wọ̀nyí ikú ẹ̀ẹ̀kejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún.

Ìparun Satani

7Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀. 820.8: El 38.2,9,15.Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun. 920.9: 2Ọb 1.10-12.Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà: iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run. 10A sì wọ́ Èṣù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti sulfuru, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé.

Àwọn òkú gba ìdájọ́

1120.11-12: Da 7.9-10.Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ; a kò sì rí ààyè fún wọn mọ́. 12Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́; a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀; a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè: a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 13Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn. 14Àti ikú àti ipò òkú ni a sì sọ sínú adágún iná. Èyí ni ikú kejì. 1520.15: If 3.5.Bí a bá sì rí ẹnikẹ́ni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè, a ó sọ ọ́ sínú adágún iná.

Habrit Hakhadasha/Haderekh

התגלות 20:1-15

1אחרי כן ראיתי מלאך יורד מן השמים, ובידו מפתח התהום ושרשרת גדולה וכבדה. 2המלאך תפס את התנין – הלא הוא הנחש הקדמוני, המלשין, השטן – וכבלו בשרשרת למשך אלף שנים. 3המלאך השליכו אל התהום, סגר ונעל את פי התהום, כדי שהשטן לא יוכל להתעות יותר את העמים עד שיחלפו אלף השנים. בתום אלף השנים הוא ישוחרר לזמן קצר. 4לאחר מכן ראיתי כיסאות שעליהם ישבו מקבלי סמכות המשפט. ראיתי גם את נשמותיהם של אלה אשר נרצחו על־שום עדותם למען ישוע המשיח ולמען דבר אלוהים, ואת נשמותיהם של אלה אשר לא השתחוו לחיה ולפסלה, ולא נשאו את אות החותם של החיה על מצחם או זרועם. כל אלה קמו לתחייה ומלכו עם המשיח אלף שנים.

5זאת תחיית המתים הראשונה. (יתר המתים קמו לתחייה רק לאחר אלף השנים). 6ברוכים וקדושים אלה שקמים בתחייה הראשונה; המוות השני לא יפגע בהם, כי יהיו כוהנים לאלוהים ולמשיחו וימלכו איתו אלף שנים.

7בתום אלף השנים ישוחרר השטן ממאסרו. 8הוא ילך להתעות את עמי־העולם – את גוג ומגוג שמספר צבאם כחול אשר על שפת הים – ויסיתם להילחם נגד אלוהים.

9הצבא האדיר הזה יעלה ויתפשט על מרחבי הארץ, ויתקיף את מחנה בני־אלוהים ואת (ירושלים) העיר האהובה. ברם אלוהים יוריד עליהם אש מן השמים שתשרוף אותם. 10השטן אשר הסיתם יושלך לאגם אש וגופרית, מקום שאליו הושלכו החיה ונביא השקר, והם יתייסרו יומם ולילה לעולם ועד.

11לאחר מכן ראיתי כיסא גדול ולבן, וראיתי גם את היושב עליו – זה אשר מפניו נמלטו הארץ והשמים, אך לא מצאו מקום להסתתר. 12ראיתי את המתים, את הקטנים והגדולים, עומדים לפני כיסא אלוהים; ראיתי ספרים נפתחים, ביניהם גם ספר החיים, והמתים נשפטו לפי מעשיהם הכתובים בספרים. 13הים נאלץ להשיב את המתים הקבורים בו. גם המוות והשאול נאלצו להשיב את מתיהם, וכל אחד נשפט בהתאם למעשיו. 14המוות והשאול הושלכו לאגם האש, שהוא המוות השני. 15כל אלה שלא נכתב שמם בספר החיים הושלכו גם הם לאגם האש.