Ìṣe àwọn Aposteli 11 – YCB & TNCV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 11:1-30

Peteru ṣàlàyé nípa àwọn ìhùwàsí rẹ̀

1Àwọn aposteli àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Judea sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 2Nígbà tí Peteru sì gòkè wá sí Jerusalẹmu, àwọn ti ìkọlà ń bá a wíjọ́ 3wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”

411.4-17: Ap 10.1-48.Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé, 5“Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi. 6Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko igbó, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 7Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Peteru: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’

8“Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘rara Olúwa! Nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láéláé.’

9“Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kejì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’ 10Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.

11“Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesarea sí mi. 12Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà: 13Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí angẹli kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Peteru; 14ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’

15“Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe. 1611.16: Ap 1.5.Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’ 17Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”

18Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”

Ìjọ ní Antioku

1911.19: Ap 8.4.Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. 20Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. 21Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.

22Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; 23Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. 24Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.

25Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu, 26nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”

27Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá sí Antioku. 28Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.) 29Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea. 30Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.

Thai New Contemporary Bible

กิจการของอัครทูต 11:1-30

เปโตรชี้แจงการกระทำของเขา

1เหล่าอัครทูตและพวกพี่น้องทั่วแคว้นยูเดียได้ยินว่าคนต่างชาติก็ได้รับพระวจนะของพระเจ้าด้วย 2ดังนั้นเมื่อเปโตรกลับมาที่กรุงเยรูซาเล็มพวกผู้เชื่อซึ่งเข้าสุหนัตแล้วจึงวิพากษ์วิจารณ์เขา 3และกล่าวว่า “ท่านเข้าไปในบ้านของผู้ที่ไม่ได้เข้าสุหนัตและรับประทานอาหารกับเขา”

4เปโตรจึงชี้แจงทุกสิ่งที่เกิดขึ้นให้ฟังตามลำดับว่า 5“ข้าพเจ้าอยู่ที่เมืองยัฟฟา ขณะกำลังอธิษฐานและตกอยู่ในภวังค์ข้าพเจ้าก็ได้รับนิมิต เห็นสิ่งหนึ่งเหมือนผ้าผืนใหญ่ทั้งสี่มุมหย่อนจากฟ้าสวรรค์ลงมายังที่ซึ่งข้าพเจ้าอยู่ 6ข้าพเจ้ามองเข้าไปเห็นสัตว์สี่เท้าของแผ่นดินโลก สัตว์ป่า สัตว์เลื้อยคลาน และนกในอากาศ 7แล้วข้าพเจ้าได้ยินเสียงหนึ่งบอกข้าพเจ้าว่า ‘เปโตรเอ๋ย จงลุกขึ้นฆ่ากินเถิด’

8“ข้าพเจ้าตอบว่า ‘ไม่ได้พระเจ้าข้า! ไม่เคยมีสิ่งเป็นมลทินหรือไม่สะอาดเข้าปากของข้าพระองค์เลย’

9“เสียงนั้นพูดจากฟ้าสวรรค์เป็นครั้งที่สองว่า ‘อย่าเรียกสิ่งซึ่งพระเจ้าทรงชำระให้สะอาดแล้วว่าเป็นมลทิน’ 10เป็นเช่นนี้ถึงสามครั้ง แล้วทั้งหมดนั้นก็ถูกรับขึ้นสู่ฟ้าสวรรค์อีก

11“ทันใดนั้นเองชายสามคนจากเมืองซีซารียาที่เขาส่งมาหาข้าพเจ้าก็มาหยุดอยู่ที่บ้านซึ่งข้าพเจ้าพักอยู่ 12พระวิญญาณทรงสั่งให้ข้าพเจ้าไปกับพวกเขาโดยไม่ต้องลังเล พี่น้องหกคนนี้ก็ไปด้วยและเราเข้าไปในบ้านของชายผู้นั้น 13เขาเล่าให้เราฟังว่าได้เห็นทูตสวรรค์มาปรากฏในบ้านของเขาและกล่าวว่า ‘จงส่งคนไปเมืองยัฟฟา แล้วรับตัวซีโมนที่เรียกกันว่าเปโตรมาเถิด 14เขาจะแจ้งเรื่องราวแก่เจ้าแล้วเจ้ากับทั้งครัวเรือนของเจ้าจะได้รับความรอดผ่านเรื่องราวนั้น’

15“พอข้าพเจ้าเริ่มพูดพระวิญญาณบริสุทธิ์ก็เสด็จลงมาเหนือพวกเขาเหมือนที่ได้เสด็จมาเหนือเราทั้งหลายในตอนแรก 16แล้วข้าพเจ้าจึงนึกขึ้นได้ที่องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสไว้ว่า ‘ยอห์นให้บัพติศมาด้วย11:16 หรือในน้ำ แต่ท่านทั้งหลายจะได้รับบัพติศมาด้วย11:16 หรือในพระวิญญาณบริสุทธิ์’ 17ดังนั้นถ้าพระเจ้าทรงให้ของประทานอย่างเดียวกันแก่พวกเขาเหมือนที่ทรงให้แก่พวกเราผู้เชื่อในองค์พระเยซูคริสต์เจ้า แล้วข้าพเจ้าเป็นใครกันเล่าที่คิดว่าจะขัดขวางพระเจ้าได้?”

18เมื่อพวกเขาได้ยินเช่นนี้ก็ไม่มีข้อคัดค้านใดอีกและพากันสรรเสริญพระเจ้าว่า “ถ้าอย่างนั้น แม้คนต่างชาติพระเจ้าก็ทรงโปรดให้กลับใจใหม่เข้าสู่ชีวิตด้วย”

คริสตจักรในอันทิโอก

19ฝ่ายบรรดาผู้ที่กระจัดกระจายไปเนื่องจากการข่มเหงอันเกี่ยวโยงกับสเทเฟน ก็เดินทางไปไกลถึงเมืองฟีนิเซีย เกาะไซปรัสและเมืองอันทิโอก และเล่าเรื่องราวนั้นแก่พวกยิวเท่านั้น 20แต่ก็มีบางคนในพวกเขาที่มาจากเกาะไซปรัสและจากเมืองไซรีนได้ไปที่เมืองอันทิโอกและเล่าข่าวประเสริฐเรื่ององค์พระเยซูเจ้าแก่ชาวกรีกด้วย 21พระหัตถ์ของพระเจ้าอยู่กับเขาเหล่านั้น ผู้คนมากมายเชื่อและกลับใจมาหาองค์พระผู้เป็นเจ้า

22ข่าวนี้มาถึงคริสตจักรที่กรุงเยรูซาเล็มพวกเขาจึงส่งบารนาบัสไปยังเมืองอันทิโอก 23เมื่อบารนาบัสมาถึงและได้เห็นพยานหลักฐานที่แสดงถึงพระคุณของพระเจ้าก็ชื่นชมยินดีและให้กำลังใจพวกเขาทุกคนให้สัตย์ซื่อมั่นคงต่อองค์พระผู้เป็นเจ้าอย่างสุดใจ 24บารนาบัสเป็นคนดี เต็มด้วยพระวิญญาณบริสุทธิ์และความเชื่อ คนจำนวนมากก็มาเชื่อองค์พระผู้เป็นเจ้า

25แล้วบารนาบัสจึงไปตามหาเซาโลที่เมืองทาร์ซัส 26เมื่อพบแล้วก็พาเขามาเมืองอันทิโอก บารนาบัสกับเซาโลร่วมประชุมกับคริสตจักรและสั่งสอนคนเป็นอันมากตลอดหนึ่งปีเต็ม และที่เมืองอันทิโอกนั้นเองพวกสาวกได้ชื่อว่าคริสเตียนเป็นครั้งแรก

27ครั้งนั้นมีผู้เผยพระวจนะบางคนจากกรุงเยรูซาเล็มมาที่อันทิโอก 28พวกเขาคนหนึ่งชื่ออากาบัสยืนขึ้นพยากรณ์โดยพระวิญญาณว่าจะเกิดการกันดารอาหารอย่างรุนแรงทั่วจักรวรรดิโรมัน (เหตุการณ์ครั้งนี้เกิดขึ้นในสมัยของคลาวดิอัส) 29เหล่าสาวกจึงตัดสินใจว่าจะร่วมกันช่วยเหลือพวกพี่น้องที่อยู่ในแคว้นยูเดียตามกำลังของแต่ละคน 30พวกเขาทำตามนั้นโดยฝากความช่วยเหลือของพวกเขาให้บารนาบัสกับเซาโลนำมาให้เหล่าผู้ปกครองคริสตจักร