2โครินธ์ 12 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2โครินธ์ 12:1-21

นิมิตและหนามยอกกายเปาโล

1ข้าพเจ้าต้องโอ้อวดต่อไปถึงแม้จะไม่เกิดประโยชน์อะไรขึ้นมา ข้าพเจ้าก็ขอเล่าถึงนิมิตและการทรงสำแดงต่างๆ จากองค์พระผู้เป็นเจ้า 2ข้าพเจ้ารู้จักชายคนหนึ่งในพระคริสต์ ผู้ซึ่งสิบสี่ปีที่แล้วถูกรับขึ้นไปยังสวรรค์ชั้นที่สาม จะไปในกายหรือนอกกายข้าพเจ้าไม่รู้ พระเจ้าทรงทราบ 3ข้าพเจ้าไม่รู้ว่าเขาไปในกายนี้หรือนอกกาย พระเจ้าทรงทราบ แต่ข้าพเจ้ารู้ว่าชายผู้นี้ 4ถูกรับขึ้นไปถึงเมืองบรมสุขเกษม เขาได้ยินสิ่งต่างๆ ซึ่งไม่อาจจะพรรณนาได้ สิ่งซึ่งไม่อนุญาตให้มนุษย์บอกเล่า 5ข้าพเจ้าจะอวดถึงคนเช่นนี้แหละ แต่ข้าพเจ้าจะไม่อวดตนเอง เว้นแต่เรื่องความอ่อนแอของข้าพเจ้า 6ถ้าหากว่าข้าพเจ้าเลือกที่จะอวด ข้าพเจ้าก็จะไม่เป็นเช่นคนโง่ เพราะข้าพเจ้าจะพูดความจริง แต่ข้าพเจ้ายับยั้งไว้เพื่อไม่ให้ใครยกย่องข้าพเจ้าเกินเลยจากสิ่งที่ข้าพเจ้าพูดหรือทำ

7เพื่อไม่ให้ข้าพเจ้าผยองเนื่องด้วยการทรงสำแดงอันยิ่งใหญ่เลิศล้ำเหล่านี้ จึงทรงให้มีหนามในเนื้อของข้าพเจ้า เป็นทูตของซาตานคอยทรมานข้าพเจ้า 8ข้าพเจ้าทูลวิงวอนองค์พระผู้เป็นเจ้าสามครั้งให้ทรงเอาหนามนี้ออกไปจากข้าพเจ้า 9แต่พระองค์ตรัสกับข้าพเจ้าว่า “พระคุณของเราเพียงพอสำหรับเจ้า เพื่อว่าฤทธิ์อำนาจของเราจะได้ปรากฏเต็มที่ในความอ่อนแอ” ฉะนั้นข้าพเจ้าจึงอวดความอ่อนแอของตนด้วยความยินดี เพื่อฤทธิ์อำนาจของพระคริสต์จะได้อยู่ในข้าพเจ้า 10ด้วยเหตุนี้แหละเพื่อพระคริสต์ ข้าพเจ้าจึงชื่นชมในความอ่อนแอ ในการสบประมาท ในความยากลำบาก ในการกดขี่ข่มเหง ในความยุ่งยาก เพราะเมื่อใดที่ข้าพเจ้าอ่อนแอเมื่อนั้นข้าพเจ้าก็เข้มแข็ง

เปาโลห่วงใยพี่น้องชาวโครินธ์

11ข้าพเจ้าได้ทำตนเองให้เป็นคนโง่ไปแล้วสิ แต่พวกท่านก็เป็นผู้ผลักดันให้ข้าพเจ้าเป็นอย่างนี้ ท่านทั้งหลายน่าจะชมเชยข้าพเจ้า เพราะถึงแม้ว่าข้าพเจ้าจะไม่มีอะไรดีเด่น แต่ข้าพเจ้าก็ไม่ได้ด้อยไปกว่า “ยอดอัครทูต” เหล่านั้น 12สิ่งต่างๆ ที่บ่งบอกถึงความเป็นอัครทูตเช่น หมายสำคัญ การอัศจรรย์และปาฏิหาริย์ต่างๆ ก็ทำแล้วท่ามกลางพวกท่านด้วยความพากเพียรอดทนบากบั่น 13ท่าน

ด้อยกว่าคริสตจักรอื่นๆ ตรงไหน? ยกเว้นที่ข้าพเจ้าไม่เคยเป็นภาระแก่ท่าน โปรดอภัยข้าพเจ้าในความผิดข้อนี้!

14บัดนี้ข้าพเจ้าพร้อมที่จะมาเยี่ยมพวกท่านเป็นครั้งที่สาม และข้าพเจ้าจะไม่เป็นภาระแก่ท่าน เพราะสิ่งที่ข้าพเจ้าต้องการคือตัวท่านไม่ใช่ทรัพย์สินของท่าน ควรหรือที่ลูกๆ จะเก็บออมให้พ่อแม่? พ่อแม่ต่างหากที่ควรสะสมไว้ให้ลูก 15ดังนั้นข้าพเจ้าก็ยินดีที่จะใช้ทุกสิ่งที่มีและทุ่มเทตัวเองเพื่อท่าน ถ้าข้าพเจ้ารักท่านมากขึ้น ท่านจะรักข้าพเจ้าน้อยลงหรือ? 16อย่างที่เป็นมาข้าพเจ้าไม่เคยเป็นภาระแก่พวกท่าน แต่คนเจ้าเล่ห์อย่างข้าพเจ้าใช้กลเม็ดดักจับท่าน! 17ข้าพเจ้าฉกฉวยประโยชน์จากพวกท่านผ่านทางใครคนใดที่ข้าพเจ้าได้ส่งมาหรือ? 18ข้าพเจ้าขอให้ทิตัสมาหาท่านและข้าพเจ้าก็ส่งพี่น้องคนหนึ่งมากับเขาด้วย ทิตัสไม่ได้ฉกฉวยอะไรจากท่านใช่ไหม? เราไม่ได้ทำหน้าที่ด้วยใจแบบเดียวกันและดำเนินตามแนวทางเดียวกันหรอกหรือ? 19ตลอดมานี้ท่านคิดว่าเราแก้ตัวอยู่ใช่ไหม? ที่จริงเราพูดในสายพระเนตรของพระเจ้าอย่างคนที่อยู่ในพระคริสต์ ท่านที่รักทุกสิ่งที่เราทำก็ทำเพื่อเสริมสร้างพวกท่าน 20เนื่องจากข้าพเจ้าเกรงว่าเมื่อมาถึงข้าพเจ้าจะไม่เห็นท่านเป็นอย่างที่ข้าพเจ้าอยากให้เป็น และท่านก็จะไม่เห็นข้าพเจ้าเป็นอย่างที่ท่านอยากให้เป็น ข้าพเจ้ากลัวว่าอาจจะมีการทะเลาะเบาะแว้ง อิจฉาริษยา ฉุนเฉียว แตกแยก นินทาว่าร้าย หยิ่งลำพองและความวุ่นวาย 21ข้าพเจ้าเกรงว่าเมื่อข้าพเจ้ามาอีกครั้ง พระเจ้าของข้าพเจ้าจะทรงทำให้ข้าพเจ้าต่ำลงต่อหน้าพวกท่าน และข้าพเจ้าจะเศร้าเสียใจเนื่องด้วยหลายคนที่ได้ทำบาปและยังไม่ยอมกลับใจละทิ้งความเสื่อมทราม ความบาปทางเพศ และการเสเพลซึ่งเขาได้ปล่อยตัวลุ่มหลง

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 12:1-21

Ìṣípayá Paulu àti ẹ̀gún tí n bẹ lára rẹ̀

1Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. 2Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. 3Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀. 412.4: Lk 23.43.Pé a gbé e lọ sókè sí Paradise, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ. 5Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi. 6Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi, 712.7: Jb 2.6.àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. 8Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. 9Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. 1012.10: Ro 5.3; 2Kọ 6.4-5.Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.

Àníyàn Paulu nípa àwọn ará Kọrinti

1112.11: 2Kọ 11.5.Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fi ipá mú mi ṣe é: nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí: nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà aposteli bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan. 12Ohun kan tí ó ṣe ààmì aposteli, iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ agbára ni wọ́n ṣe ní àárín yín pẹ̀lú sùúrù tó ga. 13Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnu fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.

14Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. 15Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? 1612.16: 2Kọ 11.9.Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. 17Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? 1812.18: 2Kọ 2.13; 8.18.Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí?

19Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni. 2012.20: 2Kọ 2.1-4; 1Kọ 1.11; 3.3.Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà. 21Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má ba à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbèrè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.