2พงศ์กษัตริย์ 17 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2พงศ์กษัตริย์ 17:1-41

โฮเชยากษัตริย์องค์สุดท้ายของอิสราเอล

(2พกษ.18:9-12)

1โฮเชยาบุตรเอลาห์ขึ้นเป็นกษัตริย์แห่งอิสราเอลในสะมาเรียตรงกับปีที่สิบสองของรัชกาลกษัตริย์อาหัสแห่งยูดาห์ พระองค์ทรงครองราชย์อยู่เก้าปี 2พระองค์ทรงทำสิ่งที่ชั่วในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้า แต่ไม่มากเท่ากษัตริย์อิสราเอลองค์ก่อนๆ

3กษัตริย์ชัลมาเนเสอร์แห่งอัสซีเรียมาโจมตีโฮเชยาซึ่งเคยสวามิภักดิ์และถวายบรรณาการ 4แต่กษัตริย์อัสซีเรียพบว่าโฮเชยาคิดกบฏ งดส่งเครื่องบรรณาการประจำปี และส่งทูตไปเข้าเฝ้ากษัตริย์โส17:4 อาจจะเป็นชื่อย่อของโอโสร์กอนแห่งอียิปต์ พระองค์จึงทรงให้จับโฮเชยาล่ามโซ่ตรวนและจำไว้ในคุก 5กษัตริย์อัสซีเรียทรงยกทัพมาตีทั่วแผ่นดินอิสราเอลและล้อมเมืองสะมาเรียอยู่สามปี 6ในปีที่เก้าแห่งรัชกาลโฮเชยา กษัตริย์อัสซีเรียก็เข้ายึดเมืองสะมาเรียและกวาดต้อนชนอิสราเอลไปเป็นเชลยที่อัสซีเรีย ทรงให้ตั้งหลักแหล่งในเมืองฮาลาห์ในโกซานบริเวณริมฝั่งแม่น้ำฮาโบร์ และตามเมืองต่างๆ ของมีเดีย

อิสราเอลตกเป็นเชลยเพราะบาป

7ที่เป็นเช่นนี้ก็เพราะอิสราเอลทำบาปต่อพระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา ผู้ทรงช่วยพวกเขาให้พ้นจากเงื้อมมือของฟาโรห์กษัตริย์แห่งอียิปต์ พวกเขาหันไปนมัสการพระอื่นๆ 8ดำเนินตามแบบอย่างของบรรดาชนชาติซึ่งองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงขับไล่ออกไปให้พ้นหน้าพวกเขา และตามแบบอย่างที่กษัตริย์อิสราเอลชักนำ 9ชนอิสราเอลยังได้ลอบทำบาปหลายอย่างต่อพระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา และสร้างสถานบูชาบนที่สูงไว้ทั่วแผ่นดิน จากหอคอยจดป้อมปราการ 10พวกเขาได้ตั้งหินศักดิ์สิทธิ์และเสาเจ้าแม่อาเชราห์บนเนินเขาสูงทุกยอดและโคนต้นไม้ใหญ่ทุกต้น 11พวกเขาเผาเครื่องหอมที่สถานบูชาบนที่สูงทุกแห่ง เหมือนอย่างชนชาติต่างๆ ซึ่งองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงได้ขับไล่ออกไปจากดินแดนเมื่ออิสราเอลเข้ามา อิสราเอลได้ทำสิ่งชั่วร้ายยั่วยุพระพิโรธขององค์พระผู้เป็นเจ้า 12เขานมัสการรูปเคารพต่างๆ ทั้งๆ ที่องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสห้ามว่า “เจ้าอย่าทำสิ่งนี้”17:12 อพย.20:4,5 13องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงใช้ผู้เผยพระวจนะและผู้ทำนายมาเตือนทั้งอิสราเอลและยูดาห์ว่า “จงหันจากวิถีชั่วร้ายของเจ้า จงปฏิบัติตามคำบัญชาและกฎหมายของเรา ตามบทบัญญัติทั้งสิ้นที่เราได้บัญชาให้บรรพบุรุษของเจ้าเชื่อฟัง และที่เราได้แจ้งแก่เจ้าผ่านทางผู้เผยพระวจนะผู้รับใช้ของเรา”

14แต่อิสราเอลไม่ยอมฟัง เขามีใจดื้อดึงเช่นเดียวกับบรรพบุรุษผู้ที่ไม่ได้วางใจในพระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา 15พวกเขาทิ้งกฎหมายและพันธสัญญาซึ่งพระองค์ทรงให้ไว้แก่บรรพบุรุษ ไม่ยอมฟังคำเตือนของพระองค์ หันไปติดตามรูปเคารพอันไร้ค่า ตนเองจึงเป็นคนไร้ค่า พวกเขาทำตามอย่างชนชาติต่างๆ ที่อยู่แวดล้อม ทั้งๆ ที่องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสห้ามว่า “จงอย่าทำตามพวกเขา” แต่เขากลับทำในสิ่งที่พระองค์ทรงห้ามไว้

16เขาลบหลู่พระดำรัสสั่งของพระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา สร้างรูปเคารพเป็นลูกวัวสองตัว และเสาเจ้าแม่อาเชราห์ เขานมัสการพระบาอัล กราบไหว้ดวงดาวต่างๆ ในฟากฟ้า 17เขาถึงกับเอาลูกชายลูกสาวของตนเผาบูชายัญ17:17 หรือพวกเขาให้ลูกชายลูกสาวลุยไฟ เขาใช้ไสยศาสตร์และเวทมนตร์คาถา ปล่อยตัวทำสิ่งที่ชั่วในสายพระเนตรขององค์พระผู้เป็นเจ้าและยั่วยุพระพิโรธของพระองค์

18ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงพระพิโรธอิสราเอลยิ่งนักและขับไล่เขาออกไปให้พ้นพระพักตร์ เหลืออยู่แต่เพียงเผ่ายูดาห์ 19แม้แต่ยูดาห์เองก็ไม่ปฏิบัติตามพระบัญชาของพระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา แต่ทำตามอิสราเอล 20ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงละทิ้งชนชาติอิสราเอลทั้งหมด พระองค์ทรงลงโทษเขาและมอบเขาไว้ในมือของผู้ปล้นชิง ตราบจนทรงขจัดเขาออกไปให้พ้นพระพักตร์

21เมื่อพระเจ้าทรงฉีกอิสราเอลออกไปจากวงศ์วานของดาวิด พวกเขาเลือกเยโรโบอัมบุตรเนบัทเป็นกษัตริย์ เยโรโบอัมชักนำอิสราเอลออกจากการติดตามองค์พระผู้เป็นเจ้า ไปทำบาปอันใหญ่หลวง 22ชาวอิสราเอลจมอยู่ในบาปของเยโรโบอัมไม่ยอมเลิกรา 23จนกระทั่งองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงขจัดเขาออกไปให้พ้นพระพักตร์ตามที่พระองค์ได้ทรงเตือนไว้ผ่านทางผู้เผยพระวจนะผู้รับใช้ของพระองค์ ฉะนั้นอิสราเอลจึงถูกกวาดต้อนจากบ้านเกิดเมืองนอนไปเป็นเชลยอยู่ในอัสซีเรียตราบจนทุกวันนี้

คนต่างชาติมาตั้งถิ่นฐานอยู่ในสะมาเรีย

24กษัตริย์อัสซีเรียทรงนำคนจากบาบิโลน คูธาห์ อัฟวา ฮามัท และเสฟารวาอิมเข้ามาตั้งถิ่นฐานในเมืองต่างๆ ของสะมาเรียแทนที่ชาวอิสราเอล พวกเขามายึดครองสะมาเรียและอาศัยอยู่ในเมืองต่างๆ 25เมื่อพวกเขามาถึงเป็นครั้งแรก เขาไม่ได้นมัสการองค์พระผู้เป็นเจ้า พระองค์จึงทรงส่งสิงโตมาอยู่ท่ามกลางพวกเขาและฆ่าบางคนไป 26กษัตริย์อัสซีเรียทรงได้รับรายงานว่า “ประชาชนที่พระองค์ให้เข้ามาตั้งถิ่นฐานในเมืองสะมาเรียไม่ทราบบทบัญญัติของพระแห่งดินแดนนี้ พระองค์จึงทรงส่งสิงโตเข้ามาฆ่าเสียหลายคนเพราะไม่รู้สิ่งที่ควรปฏิบัติ”

27กษัตริย์อัสซีเรียจึงมีพระบัญชาว่า “ให้ส่งปุโรหิตคนหนึ่งที่ถูกกวาดต้อนมาจากสะมาเรียกลับไปอยู่ที่นั่น เพื่อสอนประชาชนให้ทราบสิ่งที่พระแห่งดินแดนนั้นประสงค์” 28ดังนั้นปุโรหิตคนหนึ่งซึ่งเป็นเชลยมาจากสะมาเรียจึงมาอยู่ที่เบธเอลและสอนประชาชนให้นมัสการองค์พระผู้เป็นเจ้า

29แต่ชนชาติเหล่านี้ได้สร้างพระของตนในเมืองต่างๆ ที่มาตั้งถิ่นฐานด้วย และตั้งพระไว้ตามสถานบูชาบนที่สูงทั้งหลายซึ่งชาวสะมาเรียได้สร้างไว้ 30คนที่มาจากบาบิโลนก็สร้างพระสุคคทเบโนท คนจากคูธาห์สร้างพระเนอร์กัล ส่วนคนจากฮามัทสร้างพระอาชิมา 31ชาวอัฟวิมสร้างพระนิบหัสและพระทารทัก และชาวเสฟารวาอิมเผาลูกของตนสังเวยแด่พระอัดรัมเมเลคและพระอานัมเมเลค ซึ่งเป็นพระของเมืองเสฟารวาอิม 32พวกเขานมัสการองค์พระผู้เป็นเจ้า แต่ตั้งคนของพวกเขาเองจากทุกประเภทให้เป็นปุโรหิตประจำสถานบูชาบนที่สูงทั้งหลาย 33พวกเขานมัสการองค์พระผู้เป็นเจ้า แต่ก็นมัสการเทพเจ้าของตนที่นำมาด้วยตามประเพณีดั้งเดิม

34พวกเขายังคงยึดถือขนบธรรมเนียมเดิมจวบจนทุกวันนี้ พวกเขาไม่ได้นมัสการองค์พระผู้เป็นเจ้าอย่างแท้จริงหรือยึดมั่นในกฎหมายและกฎเกณฑ์ บทบัญญัติและพระบัญชาที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงให้ไว้แก่วงศ์วานของยาโคบซึ่งพระองค์ประทานนามว่าอิสราเอล 35เมื่อองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงกระทำพันธสัญญากับชนอิสราเอล พระองค์ทรงบัญชาไว้ว่า “อย่านมัสการพระอื่นใด อย่ากราบไหว้ปรนนิบัติหรือถวายเครื่องบูชาแก่พระเหล่านั้น 36แต่เจ้าจงนมัสการองค์พระผู้เป็นเจ้าเพียงผู้เดียว ผู้นำเจ้าทั้งหลายออกจากอียิปต์ด้วยฤทธานุภาพอันยิ่งใหญ่และด้วยพระกรที่เหยียดออก เจ้าจะกราบลงและถวายเครื่องบูชาแด่พระองค์ 37เจ้าทั้งหลายจะต้องใส่ใจปฏิบัติตามกฎหมาย กฎเกณฑ์ บทบัญญัติ และพระบัญชาที่พระองค์เขียนไว้ให้เจ้า อย่าไปนมัสการพระอื่นๆ 38อย่าลืมพันธสัญญาที่เราทำกับเจ้า อย่านมัสการพระอื่นใด 39แต่จงนมัสการพระยาห์เวห์พระเจ้าของเจ้า ผู้ซึ่งจะกอบกู้เจ้าให้พ้นจากมือของศัตรูทั้งปวง”

40แต่คนเหล่านั้นไม่ฟัง พวกเขายังคงทำตามขนบธรรมเนียมดั้งเดิม 41พวกเขานมัสการทั้งองค์พระผู้เป็นเจ้าและรูปเคารพต่างๆ ของตน ลูกหลานของเขาก็ทำตามอย่างบรรพบุรุษเช่นนี้เรื่อยมา

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 17:1-41

Hosea ọba tí ó gbẹ̀yìn ní Israẹli

1Ní ọdún kejìlá ọba Ahasi ará Juda, Hosea ọmọ Ela jẹ ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ fún ọdún mẹsàn án. 2Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i ti ọba Israẹli ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀.

3Ṣalamaneseri ọba Asiria wá sókè láti mú Hosea, ẹni tí ó ti jẹ fún Ṣalamaneseri ó sì ti san owó òde fún un. 4Ṣùgbọ́n ọba Asiria rí i wí pé Hosea jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ ọba Ejibiti, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Asiria, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọọdún. Nígbà náà ọba Asiria fi agbára mú-ún, ó sì fi sínú túbú. 5Ọba Asiria gòkè wá sí gbogbo ibi ilé náà, ó sì lọ sí Samaria, ó sì dúró tí ì fún ọdún mẹ́ta. 6Ní ọdún kẹsànán ti Hosea, ọba Asiria mú Samaria ó sì kó Israẹli lọ sí Asiria. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hala, ní Gosani ní etí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

Israẹli sá kúrò ní ìlú nítorí ẹ̀ṣẹ̀

7Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Ejibiti lábẹ́ agbára Farao ọba Ejibiti. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn 8Wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Israẹli tí ó ti paláṣẹ 9Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìṣọ́ sí ìlú tí a dáàbò bò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn. 10Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀ sókè àti ère òrìṣà Aṣerah lórí gbogbo igi tútù 11Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n sun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búburú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè. 12Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.” 13Olúwa kìlọ̀ fún Israẹli àti Juda nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi paláṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán sí i yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”

14Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́rùn líle gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́. 15Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.

16Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbẹ́ ẹ ọ̀kan ní ère ẹgbọrọ màlúù, àti ọ̀kan ní ère òrìṣà Aṣerah. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Baali. 17Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rú ẹbọ nínú iná. Wọ́n sì ń fọ àfọ̀ṣẹ, wọ́n sì ń ṣe àlúpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa, wọ́n sì mú un bínú.

18Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gidigidi pẹ̀lú Israẹli ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀. Ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo ni ó kù, 19Àti pẹ̀lú, Juda kò pa òfin Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Wọ́n tẹ̀lé ìhùwàsí àwọn Israẹli tí wọ́n ṣe. 20Nítorí náà Olúwa kọ gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli; ó sì jẹ wọ́n ní yà. Ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn olè títí tí ó fi ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.

21Nígbà tí ó ta Israẹli kúrò láti ìdílé Dafidi, wọ́n sì mú Jeroboamu ọmọ Nebati jẹ ọba wọn. Jeroboamu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli yípadà kúrò ní títẹ̀lé Olúwa, ó sí mú kí wọn dẹ́ṣẹ̀ ńlá. 22Àwọn ọmọ Israẹli forítì í nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu kò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ wọn 23Títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni a kó gbogbo ènìyàn Israẹli kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn ni Asiria, títí di òní yìí.

Samaria tún fìdímúlẹ̀

24Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà. 25Nígbà tí wọ́n gbé bẹ̀ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárín wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn. 26Wọ́n sì sọ fún ọba Asiria pé: “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Samaria kò mọ ohun tí ọlọ́run ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárín wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”

27Nígbà náà ọba Asiria pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Samaria lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí ọlọ́run ilẹ̀ náà béèrè.” 28Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samaria wá gbé ní Beteli ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

29Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀-èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Samaria ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì. 30Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Babeli ṣe àgọ́ àwọn wúńdíá, àwọn ènìyàn Kuti ṣe òrìṣà Nergali, àti àwọn ènìyàn Hamati ṣe ti Aṣima; 31Àti àwọn ará Afa ṣe Nibhasi àti Tartaki, àti àwọn ará Sefarfaimi sun àwọn ọmọ wọn níná gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Adrameleki àti Anameleki, àwọn òrìṣà Sefarfaimi. 32Wọ́n sin Olúwa, ṣùgbọ́n wọ́n sì tún yan gbogbo ẹgbẹ́ tí ènìyàn wọn láti ṣe iṣẹ́ oyè fún wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ibi gíga. 33Wọ́n sin Olúwa ṣùgbọ́n wọ́n sin òrìṣà wọn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àṣà orílẹ̀-èdè wọn láti ibi tí wọ́n ti gbé wọn wá.

34Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá. Wọn kò sin Olúwa tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí Olúwa fi fún ìránṣẹ́ Jakọbu, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Israẹli. 35Nígbà tí Olúwa ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe sin òrìṣà mìíràn tàbí tẹríba fún wọn, sìn wọ́n tàbí kí ẹ rú ẹbọ sí wọn. 36Ṣùgbọ́n Olúwa, ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn. Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rú ẹbọ fún. 37Ó yẹ kí ẹ̀yin kí ó máa kíyèsi ara yín gidigidi láti pa ìlànà àti àṣẹ, àti òfin tí ó kọ fún un yín mọ́. Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn. 38Ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú tí mo ti ṣe pẹ̀lú yín mọ́ àti kí ẹ má sin ọlọ́run mìíràn. 39Kúkú sin Olúwa Ọlọ́run rẹ; Òun ni ẹni náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a yín.”

40Wọn kò ní gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ wọ́n ti àtijọ́. 41Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn wọn sin Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn. Títí di ọjọ́ òní ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn sì ń ṣe bí àwọn baba wọn ti ń ṣe.