2พงศาวดาร 31 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2พงศาวดาร 31:1-21

1เมื่อจบพิธีฉลองแล้ว ชนอิสราเอลซึ่งอยู่ที่นั่นก็ออกไปยังเมืองต่างๆ ของยูดาห์ ทุบทำลายหินศักดิ์สิทธิ์ โค่นเสาเจ้าแม่อาเชราห์ ทำลายสถานบูชาบนที่สูงทั้งหลาย และทำลายแท่นบูชาต่างๆ ทั่วยูดาห์ เบนยามิน และในเอฟราอิมกับมนัสเสห์ หลังจากทำลายหมดสิ้นแล้วชาวอิสราเอลทั้งปวงก็กลับสู่บ้านเมืองและที่ดินของตน

ร่วมกันถวายเพื่อการนมัสการ

(2พกษ.18:5-7)

2เฮเซคียาห์ทรงแบ่งปุโรหิตและคนเลวีเป็นหมู่เหล่าตามหน้าที่ของแต่ละคน เพื่อถวายเครื่องเผาบูชากับเครื่องสันติบูชา เพื่อปรนนิบัติ ถวายคำขอบพระคุณ และร้องเพลงสรรเสริญที่ประตูต่างๆ ของที่ประทับขององค์พระผู้เป็นเจ้า 3เฮเซคียาห์ถวายทรัพย์สินส่วนพระองค์เพื่อเครื่องเผาบูชาประจำวันเวลาเช้าและเวลาเย็น เพื่อเครื่องเผาบูชาสำหรับวันสะบาโต วันขึ้นหนึ่งค่ำ และเทศกาลต่างๆ ประจำปีตามที่ระบุไว้ในบทบัญญัติขององค์พระผู้เป็นเจ้า 4พระองค์ทรงบัญชาให้ประชากรในกรุงเยรูซาเล็มนำส่วนที่ปุโรหิตและคนเลวีควรได้รับมาให้พวกเขา เพื่อปุโรหิตและคนเลวีจะอุทิศตนตามบทบัญญัติขององค์พระผู้เป็นเจ้า 5ประชากรตอบสนองต่อพระบัญชาทันทีอย่างใจกว้างขวาง โดยนำผลแรกของเมล็ดข้าว เหล้าองุ่นใหม่ น้ำมัน น้ำผึ้ง และพืชพันธุ์ทุกชนิดมาถวาย พวกเขาได้นำของถวายมามากมายคือหนึ่งในสิบของทุกอย่างที่มี 6ชนอิสราเอลและยูดาห์ซึ่งอาศัยในเมืองต่างๆ ของยูดาห์ยังนำหนึ่งในสิบของฝูงวัวกับฝูงแพะแกะ และหนึ่งในสิบของสิ่งบริสุทธิ์มาถวายแด่พระยาห์เวห์พระเจ้าของพวกเขา โดยรวมไว้เป็นกองๆ 7พวกเขาเริ่มนำเข้ามาในเดือนที่สามจนครบถ้วนในเดือนที่เจ็ด 8เมื่อเฮเซคียาห์และเหล่าข้าราชบริพารมาเห็นกองของถวายเหล่านี้ก็สรรเสริญองค์พระผู้เป็นเจ้าและอวยพรประชากรอิสราเอล

9เฮเซคียาห์ตรัสถามปุโรหิตและคนเลวีเกี่ยวกับของถวายเหล่านั้น 10และหัวหน้าปุโรหิตอาซาริยาห์จากครอบครัวของศาโดกทูลตอบว่า “ตั้งแต่ประชาชนนำของถวายมายังพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า พวกข้าพเจ้ารับประทานจนอิ่มและยังเหลือมากมายขนาดนี้ เพราะองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงอวยพรเหล่าประชากร”

11เฮเซคียาห์ทรงบัญชาให้จัดเตรียมคลังไว้ในพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า พวกเขาก็จัด 12แล้วนำของถวายต่างๆ รวมทั้งสิบลดเข้ามาเก็บไว้อย่างซื่อสัตย์ โคนานิยาห์คนเลวีเป็นหัวหน้าดูแล รองลงมาคือชิเมอีน้องชายของเขา 13เยฮีเอล อาซาซิยาห์ นาหาท อาสาเฮล เยรีโมท โยซาบาด เอลีเอล อิสมาคิยาห์ มาฮาท และเบไนยาห์ เป็นผู้กำกับดูแลภายใต้การบังคับบัญชาของโคนานิยาห์กับชิเมอีน้องชายของเขา คนเหล่านี้ได้รับการแต่งตั้งโดยกษัตริย์เฮเซคียาห์และอาซาริยาห์เจ้าหน้าที่ดูแลพระวิหารของพระเจ้า

14โคเรบุตรอิมนาห์คนเลวีซึ่งเป็นยามเฝ้าประตูตะวันออกดูแลของถวายตามความสมัครใจแด่พระเจ้า มีหน้าที่แจกจ่ายของที่ถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าและของถวายอันบริสุทธิ์ 15เอเดน มินยามิน เยชูอา เชไมอาห์ อามาริยาห์ และเชคานิยาห์ คอยช่วยเหลือเขาอย่างซื่อสัตย์ในเมืองต่างๆ ของปุโรหิต โดยทำหน้าที่แจกจ่ายให้แก่พี่น้องปุโรหิตตามหมู่เหล่าของพวกเขาอย่างเท่าเทียมกันไม่ว่าหนุ่มหรือแก่

16นอกจากนี้พวกเขายังแจกจ่ายให้กับผู้ชายอายุสามปีขึ้นไปซึ่งมีชื่ออยู่ในบันทึกลำดับวงศ์ตระกูล คือทุกคนที่จะเข้าไปยังพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้า เพื่อปฏิบัติหน้าที่ประจำวันของพวกเขา ตามหน้าที่รับผิดชอบและหมู่เหล่าของพวกเขา 17และพวกเขาแจกจ่ายแก่ปุโรหิตที่มีชื่อในบันทึกลำดับวงศ์ตระกูลตามครอบครัวของพวกเขา และแก่คนเลวีอายุยี่สิบปีขึ้นไป ตามความรับผิดชอบและหมู่เหล่าของพวกเขาด้วยเช่นกัน 18รวมทั้งลูกเล็กเด็กแดง ภรรยา และบุตรชายบุตรสาวในชุมชนทั้งหมด ตามรายชื่อบันทึกลำดับวงศ์ตระกูล เพราะพวกเขาซื่อสัตย์ในการชำระตนให้บริสุทธิ์

19สำหรับปุโรหิตซึ่งเป็นวงศ์วานของอาโรนที่อาศัยอยู่ในทุ่งหญ้าโดยรอบหรือในเมืองอื่นๆ จะมีการระบุชื่อผู้แจกจ่ายส่วนแบ่งให้แก่ชายทุกคนในพวกเขาและแก่คนทั้งปวงที่มีชื่ออยู่ในบันทึกลำดับวงศ์ตระกูลของคนเลวี

20เฮเซคียาห์ทรงทำเช่นนี้ทั่วยูดาห์เป็นการทำสิ่งที่ดีงาม ถูกต้อง และซื่อสัตย์ต่อหน้าพระยาห์เวห์พระเจ้าของพระองค์ 21เฮเซคียาห์ทรงทำทุกสิ่งเพื่องานในพระวิหารของพระเจ้า และปฏิบัติตามบทบัญญัติและพระบัญชาด้วยการแสวงหาพระเจ้าและทำงานอย่างสุดใจ พระองค์จึงทรงเจริญรุ่งเรือง

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 31:1-21

1Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ jákèjádò Juda àti Benjamini àti ní Efraimu àti Manase. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Israẹli padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn.

Ìdáwó fún ìjọ́sìn

2Hesekiah fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Lefi láti tẹ́ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu-ọ̀nà ibùgbé Olúwa. 3Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin Olúwa. 4Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa. 5Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. 6Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. 7Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. 8Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.

9Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; 10àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.”

11Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí. 12Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. 13Jehieli, Asasiah, Nahati, Asaheli, Jerimoti, Josabadi, Elieli, Ismakia, Mahati àti Benaiah jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konaniah àti Ṣimei arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Hesekiah àti Asariah olórí ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run.

14Kore ọmọ Imina ará Lefi Olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, o ń pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ 15Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.

16Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbí ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbà wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn. 17Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn. 18Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kéékèèkéé sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlú tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.

19Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Aaroni, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàrín wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Lefi.

20Èyí ni Hesekiah ṣe jákèjádò Juda, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 21Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé ní ti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere.