2พงศาวดาร 16 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2พงศาวดาร 16:1-14

บั้นปลายของกษัตริย์อาสา

(1พกษ.15:17-24)

1กษัตริย์บาอาชาแห่งอิสราเอลมาสู้รบกับยูดาห์ในปีที่สามสิบหกแห่งรัชกาลอาสา และบาอาชาทรงสร้างป้อมปราการที่เมืองรามาห์เพื่อปิดทางเข้าออกสู่เขตแดนของกษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์

2อาสาจึงทรงนำเงินและทองคำจากคลังพระวิหารขององค์พระผู้เป็นเจ้าและจากท้องพระคลังของพระราชวังของพระองค์เอง ส่งไปถวายกษัตริย์เบนฮาดัดแห่งอารัมซึ่งปกครองอยู่ที่เมืองดามัสกัส และตรัสว่า 3“ขอให้เราเป็นพันธมิตรกันเหมือนดังราชบิดาของเราทั้งสอง ข้าพเจ้าส่งเงินและทองนี้มากำนัลแด่ท่าน ขอให้ท่านตัดสัมพันธไมตรีกับกษัตริย์บาอาชาแห่งอิสราเอล เพื่อเขาจะได้ถอยทัพไปจากข้าพเจ้า”

4เบนฮาดัดทรงเห็นชอบกับกษัตริย์อาสา และส่งแม่ทัพและกองกำลังไปโจมตีเมืองต่างๆ ของอิสราเอล พวกเขาพิชิตเมืองอิโยน ดาน อาเบลมาอิม16:4 เป็นที่รู้จักในอีกชื่อหนึ่งว่าอาเบลเบธมาอาคาห์ และเมืองคลังเสบียงทุกเมืองในนัฟทาลี 5เมื่อบาอาชาทราบเรื่องนี้ก็หยุดสร้างเมืองรามาห์และทิ้งงาน 6กษัตริย์อาสาจึงทรงนำชายชาวยูดาห์ทั้งหมดไปยังเมืองรามาห์ ให้ขนหินและไม้ซึ่งบาอาชาทรงใช้อยู่นั้นไปสร้างเมืองเกบาและเมืองมิสปาห์

7ครั้งนั้นผู้ทำนายฮานานีมาเข้าเฝ้ากษัตริย์อาสาแห่งยูดาห์และทูลว่า “เนื่องจากท่านพึ่งกษัตริย์แห่งอารัมแทนที่จะพึ่งพระยาห์เวห์พระเจ้าของท่าน กองทัพของกษัตริย์อารัมจึงหลุดมือท่านไปเสียแล้ว 8ครั้งนั้นชาวคูช16:8 คือ ประชากรจากเขตแม่น้ำไนล์ตอนบนกับชาวลิเบียมีกองทัพมหาศาล รถม้าศึกและพลม้า16:8 หรือพลรถรบมากมายไม่ใช่หรือ? แต่เมื่อท่านพึ่งองค์พระผู้เป็นเจ้า พระองค์ก็ทรงมอบพวกเขาไว้ในมือของท่าน 9เพราะองค์พระผู้เป็นเจ้าทอดพระเนตรทั่วโลก เพื่อทำให้ผู้ที่ภักดีต่อพระองค์อย่างสุดใจเข็มแข็งขึ้น ท่านช่างโง่เขลาเสียจริงที่ทำเช่นนั้น นับแต่นี้ไปท่านจะต้องมีสงครามเรื่อยๆ”

10อาสาทรงพระพิโรธอย่างยิ่งที่ผู้ทำนายกล่าวเช่นนั้น ถึงกับให้นำตัวไปขังคุก ครั้งนั้นอาสากดขี่ข่มเหงราษฎรบางคนอย่างทารุณด้วย

11เหตุการณ์ต่างๆ ในรัชกาลอาสาตั้งแต่ต้นจนจบมีบันทึกไว้ในจดหมายเหตุกษัตริย์แห่งอิสราเอลและยูดาห์ 12ในปีที่สามสิบเก้าแห่งรัชกาลอาสา พระองค์ประชวรหนักด้วยโรคที่พระบาท ถึงแม้โรคนั้นจะร้ายแรง แต่พระองค์ไม่ได้แสวงหาความช่วยเหลือจากองค์พระผู้เป็นเจ้า พระองค์พึ่งแต่แพทย์เท่านั้น 13แล้วในปีที่สี่สิบเอ็ดแห่งรัชกาลอาสา พระองค์ก็สิ้นพระชนม์และล่วงลับไปอยู่กับบรรพบุรุษ 14ทรงถูกฝังไว้ในอุโมงค์ที่ทรงสกัดขึ้นเพื่อพระองค์เองในเมืองดาวิด เขาวางพระศพบนพระแท่นที่สุมด้วยเครื่องเทศและเครื่องหอมนานาชนิด และพวกเขาก่อไฟกองใหญ่ถวายพระเกียรติ

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 16:1-14

Ìgbẹ̀yìn ọdún asà

1Ní ọdún kẹrìn-dínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ.

2Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé, 3“Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”

4Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. 5Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. 6Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.

7Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. 8Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. 9Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”

10Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.

11Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. 1216.12-14: 1Ọb 15.23,24.Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. 13Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, 14Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.