2ซามูเอล 24 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

2ซามูเอล 24:1-25

ดาวิดทรงนับไพร่พล

(1พศด.21:1-17)

1อีกครั้งหนึ่งที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงพระพิโรธอิสราเอล และทรงดลใจดาวิดให้หาเรื่องเดือดร้อนมาให้พวกเขา โดยตรัสว่า “จงไปทำสำมะโนไพร่พลอิสราเอลและยูดาห์”

2ดาวิดจึงตรัสกับโยอาบและบรรดานายทัพ24:2 ภาษาฮีบรูว่าโยอาบผู้บังคับบัญชากองทัพ(ดูข้อ 4 และ1พศด.21:2)ว่า “จงทำทะเบียนพลรบทั้งหมดของทุกเผ่าในอิสราเอลจากดานจดเบเออร์เชบา เพื่อเราจะรู้ว่ามีคนอยู่เท่าไร”

3แต่โยอาบกราบทูลว่า “ขอพระยาห์เวห์พระเจ้าของฝ่าพระบาททรงเพิ่มกองทหารร้อยเท่า และขอให้ฝ่าพระบาทได้เห็นกับตา เหตุใดฝ่าพระบาทจึงมีพระประสงค์จะกระทำเช่นนี้”

4แต่คำบัญชาของกษัตริย์ย่อมมีอำนาจเหนือโยอาบและบรรดานายทัพ ฉะนั้นพวกเขาจึงทูลลาไปทำรายชื่อของพลรบอิสราเอล

5หลังจากข้ามแม่น้ำจอร์แดน พวกเขาไปตั้งค่ายพักในหุบเขาทางใต้ของเมืองอาโรเออร์ แล้วผ่านกาดไปยังยาเซอร์ 6พวกเขาไปที่กิเลอาดและเขตแดนทาห์ทิมโหดชิ แล้วไปดานยาอันและไปทั่วจนถึงไซดอน 7จากนั้นไปยังป้อมแห่งเมืองไทระ และหัวเมืองทั้งหมดของชาวฮีไวต์ และชาวคานาอัน ท้ายสุดไปยังเบเออร์เชบาในเนเกบแห่งยูดาห์

8หลังจากพวกเขาไปทั่วแดนก็กลับมายังเยรูซาเล็ม ใช้เวลาเก้าเดือนยี่สิบวัน

9โยอาบทูลรายงานจำนวนพลรบต่อกษัตริย์ คนที่อยู่ในเกณฑ์ออกรบได้มีแปดแสนคนในอิสราเอล ส่วนในยูดาห์มีห้าแสนคน

10หลังจากสำรวจไพร่พลแล้ว ดาวิดก็สำนึกผิดจึงกราบทูลองค์พระผู้เป็นเจ้าว่า “สิ่งที่ข้าพระองค์ทำนั้นบาปมาก ข้าแต่องค์พระผู้เป็นเจ้าบัดนี้ขอทรงโปรดยกโทษความผิดของผู้รับใช้ของพระองค์ ข้าพระองค์ได้ทำสิ่งที่โง่เขลามาก”

11ก่อนดาวิดตื่นบรรทมเช้าวันรุ่งขึ้น มีพระดำรัสขององค์พระผู้เป็นเจ้ามาถึงผู้เผยพระวจนะกาดซึ่งเป็นผู้ทำนายให้ดาวิด ความว่า 12“จงไปบอกดาวิดว่า องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสดังนี้ว่า ‘เรามีข้อเสนอสามประการ ให้เจ้าเลือกอย่างหนึ่งแล้วเราจะจัดการกับเจ้าตามนั้น’”

13กาดจึงมาเข้าเฝ้าดาวิดทูลว่า “ฝ่าพระบาทจะทรงเลือกการกันดารอาหารทั่วดินแดนสามปี24:13 ภาษาฮีบรูว่าเจ็ดปี(ดู1พศด.21:12) หรือเตลิดหนีจากศัตรูผู้รุกไล่สามเดือน หรือยอมให้มีโรคระบาดในดินแดนสามวัน ขอทรงตรึกตรองแล้วแจ้งคำตอบเพื่อข้าพระบาทจะนำไปทูลพระองค์ผู้ทรงใช้ข้าพระบาทมา”

14ดาวิดตรัสตอบกาดว่า “เราลำบากใจมาก แต่ขอตกอยู่ในอุ้งพระหัตถ์ขององค์พระผู้เป็นเจ้าดีกว่าตกอยู่ในเงื้อมมือของมนุษย์ เพราะพระเมตตาคุณของพระองค์ใหญ่หลวงนัก”

15ฉะนั้นองค์พระผู้เป็นเจ้าทรงให้เกิดโรคระบาดในอิสราเอลตั้งแต่เช้าวันนั้นจนครบกำหนด จากดานจดเบเออร์เชบา มีผู้เสียชีวิตเจ็ดหมื่นคน 16เมื่อทูตสวรรค์เงื้อมือขึ้นจะทำลายล้างกรุงเยรูซาเล็ม องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงทุกข์พระทัยเนื่องด้วยภัยพิบัตินั้น จึงตรัสกับทูตนั้นว่า “พอแล้ว! ยั้งมือเถิด” ขณะนั้นทูตขององค์พระผู้เป็นเจ้ากำลังยืนอยู่ที่ลานนวดข้าวของอาราวนาห์ชาวเยบุส

17เมื่อดาวิดเห็นทูตองค์นั้นผู้ทำให้ประชากรล้มตายก็กราบทูลองค์พระผู้เป็นเจ้าว่า “ข้าพระองค์คือผู้ที่ทำผิดทำบาป ประชากรเหล่านี้เป็นเพียงฝูงแกะ พวกเขาทำผิดอันใดเล่า? ขอทรงลงโทษข้าพระองค์กับครอบครัวเท่านั้นเถิด”

ดาวิดสร้างแท่นบูชา

(1พศด.21:18-26)

18ในวันนั้นกาดมาทูลดาวิดว่า “ขอทรงขึ้นไปสร้างแท่นบูชาถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้าที่ลานนวดข้าวของอาราวนาห์ชาวเยบุสเถิด” 19ดาวิดจึงไปปฏิบัติตามที่องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสสั่งผ่านทางกาด 20เมื่ออาราวนาห์เห็นกษัตริย์และผู้ตามเสด็จมาหาตนก็เข้าไปหมอบกราบลงกับพื้น

21ทูลถามว่า “ฝ่าพระบาทเสด็จมาด้วยพระประสงค์อันใด?”

ดาวิดตรัสว่า “เพื่อมาซื้อลานนวดข้าวของเจ้า เราจะสร้างแท่นบูชาถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้า พระองค์จะได้ทรงระงับโรคระบาดครั้งนี้เสีย”

22อาราวนาห์ทูลว่า “ขอฝ่าพระบาททรงใช้ทุกสิ่งตามที่ต้องประสงค์เถิด นี่คือวัวสำหรับเป็นเครื่องเผาบูชา และนี่คือเลื่อนนวดข้าวกับแอกวัวใช้เป็นฟืน 23ข้าพระบาทอาราวนาห์ขอถวายทั้งหมด และขอพระยาห์เวห์พระเจ้าของฝ่าพระบาททรงโปรดฝ่าพระบาทด้วยเถิด”

24แต่กษัตริย์ตรัสตอบอาราวนาห์ว่า “เรายืนยันที่จะซื้อจากเจ้า เราจะไม่ถวายเครื่องเผาบูชาแด่พระยาห์เวห์พระเจ้าของเราโดยที่ไม่ลงทุนอะไรเลย”

เป็นอันว่าดาวิดทรงซื้อลานนวดข้าวกับวัวด้วยเงินหนัก 50 เชเขล24:24 1 เชเขล คือเงินหนักประมาณ 11.5 กรัม มีค่าเท่ากับค่าแรงสองเดือน 25แล้วดาวิดสร้างแท่นบูชาขึ้นที่นั่นถวายแด่องค์พระผู้เป็นเจ้า และถวายเครื่องเผาบูชากับเครื่องสันติบูชา องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงตอบคำอธิษฐานเพื่อแผ่นดิน โรคระบาดที่เกิดแก่อิสราเอลก็หมดไป

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 24:1-25

Kíka àwọn ènìyàn Israẹli

124.1-25: 1Ki 21.1-27.Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!”

2Ọba sì wí fún Joabu Olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsin yìí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!”

3Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i: ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?”

4Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli.

5Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín Àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri. 6Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni, 7Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani: wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba.

8Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu ní òpin oṣù kẹsànán àti ogúnjọ́.

9Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́: ó sì jẹ́ òjì ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà: àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn.

Dafidi yan ìbáwí Olúwa

10Àyà Dafidi sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dafidi sì wí fún Olúwa pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe: ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!”

11Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé: 12“Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”

13Gadi sì tọ Dafidi wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí ààrùn ìparun ọjọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Rò ó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

14Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé Olúwa ní ọwọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn ní ọwọ́.”

15Olúwa sì rán ààrùn ìparun sí Israẹli láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá: ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dani títí fi dé Beerṣeba. 16Nígbà tí angẹli náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jerusalẹmu láti pa á run, Olúwa sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún angẹli tí ń pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyí!” Angẹli Olúwa náà sì wà níbi ìpakà Arauna ará Jebusi.

17Dafidi sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí angẹli tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”

Pẹpẹ ní ibi ìpakà Ornani

18Gadi sì tọ Dafidi wá ní ọjọ́ náà, ó sì wí fún un pé, “Gòkè, tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.” 19Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, Dafidi sì gòkè lọ bí Olúwa ti pa á ní àṣẹ. 20Arauna sì wò, ó sì rí ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ wá lọ́dọ̀ rẹ̀: Arauna sì jáde, ó sì wólẹ̀ níwájú ọba ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀.

21Arauna sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ọba ṣe tọ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá?”

Dafidi sì dáhùn pé, “Láti ra ibi ìpakà rẹ lọ́wọ́ rẹ, láti tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa, kí ààrùn ìparun lè dá lára àwọn ènìyàn náà.”

22Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba ó mú èyí tí ó dára lójú rẹ̀, kí o sì fi í rú ẹbọ: wò ó, màlúù nìyìí láti fi ṣe ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà, àti ohun èlò mìíràn ti màlúù fún igi. 23Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Arauna fi fún ọba, bí ọba. Arauna sì wí fún ọba pé, Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ ó gba ọrẹ rẹ.”

24Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run mi.”

Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà. 25Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ sí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ti ìlàjà. Olúwa sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, ààrùn náà sì dá kúrò ní Israẹli.