1ซามูเอล 23 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

1ซามูเอล 23:1-29

ดาวิดช่วยเมืองเคอีลาห์

1เมื่อมีคนมาบอกดาวิดว่า “ดูเถิด พวกฟีลิสเตียมาต่อสู้กับชาวเคอีลาห์และกำลังปล้นลานนวดข้าว” 2เขาจึงทูลถามองค์พระผู้เป็นเจ้าว่า “ข้าพระองค์ควรเข้าโจมตีพวกฟีลิสเตียหรือไม่?”

องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสตอบว่า “ไปเถิด ไปโจมตีชาวฟีลิสเตีย ป้องกันเมืองเคอีลาห์ไว้!”

3แต่คนของดาวิดพูดว่า “แม้แต่ในยูดาห์เรายังกลัว ถ้าเราไปเมืองเคอีลาห์เพื่อต่อสู้กับกองกำลังของฟีลิสเตียจะยิ่งน่ากลัวกว่านั้นสักเท่าใด!”

4ดาวิดจึงทูลถามองค์พระผู้เป็นเจ้าอีกครั้ง และองค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสตอบว่า “จงไปที่เมืองเคอีลาห์เถิด เพราะเราจะมอบชาวฟีลิสเตียไว้ในมือของเจ้า” 5ดาวิดและพวกจึงไปที่เมืองเคอีลาห์และสู้รบทำลายชาวฟีลิสเตียเสียหายยับเยิน ยึดเอาฝูงสัตว์ของเขามา และช่วยชีวิตชาวเมืองเคอีลาห์ไว้ได้ 6(เมื่อปุโรหิตอาบียาธาร์บุตรอาหิเมเลคหนีไปหาดาวิดที่เมืองเคอีลาห์ เขาได้นำเอโฟดติดตัวไปด้วย)

ซาอูลตามล่าดาวิด

7เมื่อซาอูลทรงทราบข่าวว่าดาวิดอยู่ที่เมืองเคอีลาห์ก็ตรัสว่า “พระเจ้ามอบดาวิดไว้ในมือของเราแล้ว เขาเองที่เข้ามาติดกับอยู่ในเมืองที่มีกำแพงและประตูแน่นหนาอย่างนี้” 8ฉะนั้นซาอูลทรงระดมพลไปที่เมืองเคอีลาห์เพื่อจับตัวดาวิดกับพรรคพวก

9แต่ดาวิดล่วงรู้แผนการของซาอูล เขาจึงกล่าวกับปุโรหิตอาบียาธาร์ว่า “โปรดนำเอโฟดออกมา” 10ดาวิดกราบทูลว่า “ข้าแต่พระยาห์เวห์พระเจ้าแห่งอิสราเอล ผู้รับใช้ของพระองค์ได้ยินมาอย่างแน่นอนแล้วว่าซาอูลทรงดำริจะมาทำลายล้างเมืองเคอีลาห์เพราะข้าพระองค์อยู่ที่นี่ 11ชาวเมืองเคอีลาห์จะจับกุมข้าพระองค์ไปมอบให้กษัตริย์หรือไม่? ซาอูลจะเสด็จมาจริงๆ อย่างที่ผู้รับใช้ของพระองค์ได้ยินข่าวหรือไม่? ข้าแต่พระยาห์เวห์พระเจ้าแห่งอิสราเอลโปรดแจ้งแก่ผู้รับใช้ของพระองค์ด้วยเถิด”

องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสว่า “เขาจะมา”

12ดาวิดทูลถามอีกว่า “แล้วชาวเคอีลาห์จะยอมมอบตัวข้าพระองค์และคนของข้าพระองค์แก่ซาอูลหรือไม่?”

องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสตอบว่า “เขาจะทำเช่นนั้น”

13ฉะนั้นดาวิดและพรรคพวกประมาณหกร้อยคนจึงออกจากเมืองเคอีลาห์และระเหเร่ร่อนไปยังที่ต่างๆ เมื่อซาอูลได้ข่าวว่าดาวิดหนีไปแล้ว พระองค์จึงไม่ได้เสด็จมาที่เมืองเคอีลาห์

14ดาวิดไปอาศัยอยู่ในที่มั่นตามถิ่นกันดารและในแดนเทือกเขาแห่งถิ่นกันดารศิฟ ซาอูลตามล่าดาวิดวันแล้ววันเล่า แต่พระเจ้าไม่ทรงมอบดาวิดไว้ในมือของซาอูล

15ขณะอยู่ที่โฮเรชในถิ่นกันดารศิฟ ดาวิดได้ข่าวว่าซาอูลออกตามล่าตัวเขาเพื่อจะฆ่าเสีย 16โยนาธานราชโอรสของซาอูลออกมาพบดาวิดที่โฮเรช และช่วยให้เขาเข้มแข็งขึ้นในพระเจ้า 17โยนาธานกล่าวว่า “อย่ากลัวเลย ซาอูลเสด็จพ่อของเราไม่มีวันทำอันตรายท่านได้ ท่านจะได้เป็นกษัตริย์อิสราเอล และเราจะเป็นอุปราช แม้แต่เสด็จพ่อของเราก็ทราบเรื่องนี้” 18คนทั้งสองก็ทำพันธสัญญากันต่อหน้าองค์พระผู้เป็นเจ้าแล้วโยนาธานก็กลับเข้าวัง ส่วนดาวิดยังคงอยู่ที่โฮเรชต่อไป

19แต่ชาวเมืองศิฟนำความมาทูลซาอูลที่เมืองกิเบอาห์ว่า “ดาวิดหลบซ่อนตัวอยู่ท่ามกลางพวกเราในที่มั่นที่โฮเรช บนเนินเขาฮาคีลาห์ ทางใต้ของเยชิโมนไม่ใช่หรือ? 20ข้าแต่กษัตริย์ บัดนี้ขอเชิญเสด็จมาเมื่อฝ่าพระบาทพอพระทัย และเหล่าข้าพระบาทจะรับผิดชอบในการมอบตัวเขาให้แก่ฝ่าพระบาท”

21ซาอูลตรัสตอบว่า “ขอองค์พระผู้เป็นเจ้าอวยพรพวกเจ้าที่ห่วงใยเรา 22จงดำเนินการต่อไป ไปหาว่าดาวิดอยู่ที่ไหน มีใครเห็นเขาบ้าง เรารู้มาว่าเขาเหลี่ยมจัด 23จงไปค้นหาที่ซ่อนตัวของเขาทุกที่ แล้วกลับมารายงานให้เรารู้อย่างละเอียด23:23 หรือแล้วกลับมาพบเราที่นาโคน แล้วเราจะไปกับพวกเจ้า ถ้าเขาอยู่ที่นั่นเราจะสืบเสาะเอาตัวเขามาจากทุกตระกูลของยูดาห์ให้ได้”

24ชาวเมืองศิฟจึงเดินทางล่วงหน้าซาอูลไป ฝ่ายดาวิดกับพวกอยู่ในถิ่นกันดารมาโอนในอาราบาห์ ทางใต้ของเยชิโมน 25ซาอูลกับพวกเริ่มค้นหา เมื่อดาวิดรู้ข่าวจึงหลบไปที่ภูเขาและพักอยู่ที่ถิ่นกันดารมาโอน เมื่อซาอูลทรงทราบก็เข้าไปในถิ่นกันดารมาโอนเพื่อตามล่าดาวิด

26ซาอูลและดาวิดต่างมาถึงคนละฟากของภูเขาลูกเดียวกัน ดาวิดกับพวกก็รีบหนี ขณะที่ซาอูลกับพวกเริ่มตีวงล้อมเข้ามาเพื่อจับกุม 27มีผู้สื่อสารคนหนึ่งมาทูลซาอูลว่า “ขอรีบเสด็จกลับเถิด พวกฟีลิสเตียมาปล้นดินแดนแล้ว” 28ซาอูลจึงละจากการตามล่าดาวิดกลับไปสู้รบกับชาวฟีลิสเตีย ที่แห่งนั้นจึงได้ชื่อว่าเสลาฮัมมาห์เลโคท23:28 หรือศิลาแห่งการแยกจากกัน 29จากที่นั่นดาวิดก็ไปอาศัยอยู่ในที่มั่นแห่งเอนเกดี

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 23:1-29

Dafidi gbà Keila lọ́wọ́ àwọn Filistini

1Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.” 2Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?”

Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.”

3Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhìn-ín yìí ní Juda; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Keila láti fi ojú ko ogun àwọn ara Filistini?”

4Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.” 5Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Keila, wọ́n sì bá àwọn ará Filistini jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dafidi sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀. 6Ó sì ṣe, nígbà tí Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú efodu kan lọ́wọ́ rẹ̀.

7A sì sọ fún Saulu pé Dafidi wá sí Keila. Saulu sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.” 8Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

9Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín-yìí!” 10Dafidi sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi. 11Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?”

Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”

12Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?”

Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”

13Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.”

14Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sápamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.

Àwọn ará Sifi dalẹ̀ Dafidi

15Nígbà tí Dafidi wà ní Horeṣi ní aginjù Sifi, Dafidi sì rí i pé, Saulu ti jáde láti wá ẹ̀mí òun kiri. 16Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run. 17Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jẹ ọba lórí Israẹli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” 18Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú Olúwa; Dafidi sì jókòó nínú igbó Horeṣi. Jonatani sì lọ sí ilé rẹ̀.

19Àwọn ará Sifi sì gòkè tọ Saulu wá sí Gibeah, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ́ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Horeṣi, ní òkè Hakila, tí ó wà níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 20Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.”

21Saulu sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa Olúwa; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi. 22Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé, ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ. 23Ẹ sì wò, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Israẹli, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Juda!”

24Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Saulu lọ sí Sifi: ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní aginjù Maoni, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 25Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dafidi: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní aginjù ti Maoni. Saulu sì gbọ́, ó sì lépa Dafidi ní aginjù Maoni.

26Saulu sì ń rin apá kan òkè kan, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apá kejì òkè náà. Dafidi sì yára láti sá kúrò níwájú Saulu; nítorí pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn. 27Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Saulu wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Filistini ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.” 28Saulu sì padà kúrò ní lílépa Dafidi, ó sì lọ pàdé àwọn Filistini nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Selahamalekoti (èyí tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìpinyà”). 29Dafidi sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní En-Gedi.