เอเสเคียล 17 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

เอเสเคียล 17:1-24

นกอินทรีสองตัวและเถาองุ่น

1พระวจนะขององค์พระผู้เป็นเจ้ามาถึงข้าพเจ้าว่า 2“บุตรมนุษย์เอ๋ย จงยกอุทาหรณ์และกล่าวคำอุปมาแก่พงศ์พันธุ์อิสราเอล 3จงกล่าวกับพวกเขาว่า ‘พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิตตรัสดังนี้ว่า นกอินทรีใหญ่ตัวหนึ่งซึ่งมีปีกทรงพลัง และขนยาวดกหลากสีบินมายังเลบานอน มันเกาะที่ยอดต้นสนซีดาร์ต้นหนึ่ง 4มันจิกหน่อที่สูงที่สุด และคาบไปยังนครของพ่อค้าวาณิชทั้งหลาย แล้วปลูกหน่อนั้นลงในเมืองของพ่อค้า

5“ ‘นกอินทรีนั้นคาบเมล็ดพืชจากดินแดนของเจ้าไปปลูกไว้ในดินที่อุดมสมบูรณ์ มันปลูกไว้เหมือนต้นหลิวที่อยู่ริมน้ำอันอุดมสมบูรณ์ 6ต้นไม้นั้นก็งอกงามและกลายเป็นเถาองุ่นพุ่มเตี้ย มันแผ่กิ่งก้านเลื้อยไปทางนกอินทรี แต่รากของมันยังคงอยู่ข้างใต้ ดังนั้นมันจึงกลายเป็นเถาองุ่นที่แผ่กิ่งก้านและใบดกหนา

7“ ‘แต่มีนกอินทรีใหญ่อีกตัวหนึ่งบินมา มันมีปีกทรงพลังและมีขนดก เถาองุ่นก็ชอนรากจากจุดที่ขึ้นอยู่และแผ่ก้านมาหามันเพื่อให้มันรดน้ำให้ 8ทั้งๆ ที่ตัวเองก็งอกอยู่ในดินดีมีน้ำอุดมสมบูรณ์ พร้อมที่จะแผ่กิ่งก้านสาขา ออกผล และกลายเป็นเถาองุ่นชั้นเยี่ยมอยู่แล้ว’

9“จงบอกพวกเขาเถิดว่า ‘พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิตตรัสดังนี้ว่า เถาองุ่นนั้นจะเจริญงอกงามได้หรือ? มันจะไม่ถูกถอนรากปลิดผลจนเหี่ยวแห้งไปหรือ? ใบอ่อนของมันจะเหี่ยวแห้งหมด ไม่ต้องใช้แขนที่แข็งแรงมากหรือคนหมู่ใหญ่ในการถอนรากเถาองุ่นนั้นขึ้นมา 10แม้มันถูกย้ายไปปลูก มันจะเจริญงอกงามได้หรือ? มันจะไม่เหี่ยวแห้งไปหมดสิ้นเมื่อถูกลมตะวันออกพัดกระหน่ำหรือ? มันจะไม่เหี่ยวแห้งคาที่ที่มันงอกขึ้นมาหรือ?’ ”

11แล้วพระดำรัสขององค์พระผู้เป็นเจ้ามาถึงข้าพเจ้าว่า 12“จงกล่าวแก่พงศ์พันธุ์ที่ชอบกบฏนี้ว่า ‘เจ้าไม่รู้หรือว่าสิ่งเหล่านี้หมายความว่าอะไร?’ จงบอกพวกเขาว่า ‘กษัตริย์บาบิโลนมายังเยรูซาเล็มและกวาดต้อนกษัตริย์และบรรดาขุนนางพากลับไปยังบาบิโลน 13แล้วพระองค์ทรงพาเจ้านายผู้หนึ่งมาและได้ทำสัญญากับเขา ให้เขาถวายสัตยาบันว่าจะจงรักภักดี แล้วพระองค์ก็ทรงนำคนระดับผู้นำของดินแดนนั้นไปด้วย 14เพื่ออาณาจักรนั้นจะตกต่ำลงและไม่สามารถรุ่งเรืองขึ้นมาได้อีก จะอยู่รอดได้ก็ต่อเมื่อรักษาสัญญา 15แต่กษัตริย์นั้นก็กบฏต่อพระองค์โดยส่งทูตไปยังอียิปต์ ขอม้าและกองทัพใหญ่มาช่วย เขาจะทำการสำเร็จหรือ? ผู้ที่ทำเช่นนั้นจะหนีรอดไปได้หรือ? เขาละเมิดสัญญาแล้วยังจะหนีรอดไปได้หรือ?

16“ ‘พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิตตรัสว่า เรามีชีวิตอยู่แน่ฉันใด เขาจะตายในบาบิโลน ในดินแดนของกษัตริย์ผู้ที่ตั้งเขาขึ้นครองราชบัลลังก์ ผู้ที่เขาลบหลู่สัตยาบันและผิดสัญญาที่ให้ไว้ฉันนั้น 17ฟาโรห์พร้อมกับทัพหลวงอันเกรียงไกรและกำลังพลมากมายจะช่วยเขาไม่ได้ในสงคราม เมื่อเชิงเทินถูกสร้างขึ้นและเครื่องล้อมเมืองถูกตั้งขึ้นเพื่อทำลายชีวิตคนเป็นอันมาก 18เขาผิดสัตยาบันโดยละเมิดพันธสัญญา เพราะเขาถวายสัตยาบันแล้วยังทำเช่นนี้ เขาจะหนีไม่รอด

19“ ‘ฉะนั้นพระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิตจึงตรัสดังนี้ว่า เรามีชีวิตอยู่แน่ฉันใด เราจะลงทัณฑ์เขาตามคำปฏิญาณของเราที่เขาลบหลู่ และตามพันธสัญญาของเราที่เขาละเมิดฉันนั้น 20เราจะกางตาข่ายของเราดักเขา และเขาจะติดอยู่ในกับดักของเรา เราจะนำเขาไปยังบาบิโลนและพิพากษาลงโทษเขาที่นั่น เพราะเขาไม่ซื่อสัตย์ต่อเรา 21ทหารทั้งปวงของเขาที่หนีไปจะตายด้วยดาบและผู้รอดชีวิตอยู่จะถูกทำให้กระจัดกระจายไปตามลม เมื่อนั้นเจ้าจะรู้ว่าเราผู้เป็นพระยาห์เวห์ได้ลั่นวาจาไว้

22“ ‘พระยาห์เวห์องค์เจ้าชีวิตตรัสดังนี้ว่า เราเองนี่แหละจะเอาหน่อจากยอดของสนซีดาร์ไปปลูกไว้ เราจะหักหน่ออ่อนจากยอดไปปลูกไว้บนภูเขาสูง 23เราจะปลูกมันไว้บนยอดเขาแห่งอิสราเอล มันจะแผ่กิ่งก้านสาขาและผลิผลกลายเป็นสนซีดาร์ชั้นเยี่ยม นกทุกชนิดจะมาสร้างรังและอาศัยอยู่ใต้ร่มไม้ของมัน 24ต้นไม้ทั้งปวงในท้องทุ่งจะรู้ว่าเราผู้เป็นพระยาห์เวห์ได้โค่นต้นไม้สูงลงและทำให้ต้นไม้เตี้ยสูงขึ้น ทำให้ต้นไม้เขียวเหี่ยวเฉา และให้ต้นไม้แห้งผลิงาม

“ ‘เราผู้เป็นพระยาห์เวห์ได้ลั่นวาจาไว้และเราจะทำเช่นนั้น’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 17:1-24

Ẹyẹ idì méjì àti àjàrà

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ní wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Israẹli. 3Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi Kedari tó ga jùlọ, 4ó gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, ó mú un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò.

5“ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò. 6Ó dàgbà, ó sì di àjàrà tó kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú sí i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó di àjàrà, ó sì mu ẹ̀ka àti ewé jáde.

7“ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó le fún un ni omi. 8Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sì so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

9“Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì nígbà agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòǹgbò rẹ̀ tu. 10Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”

11Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé: 12“Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ-aládé ibẹ̀ lọ sí Babeli lọ́dọ̀ rẹ̀. 13Lẹ́yìn èyí, ó bá ọ̀kan nínú ọmọ ọba dá májẹ̀mú, ó mú un ìbúra, ó tún kó àwọn alágbára ilẹ̀ náà lọ. 14Kí ìjọba ilẹ̀ náà le rẹ ilẹ̀, kí ó má lè gbé ara rẹ̀ sókè, kí ó lè dúró nípa pípa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. 15Ṣùgbọ́n ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ sí Ejibiti, kí wọn bá à lè fún un ni ẹṣin àti àwọn ọmọ-ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyọrí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò ha dalẹ̀ tán kí ó sì bọ́ níbẹ̀ bí?

16“ ‘Bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, òun yóò kú ní Babeli, ní ilẹ̀ ọba tó fi sórí oyè, ìbúra ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà. 17Farao pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún un lójú ogun. Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, 18Nítorí pé ó kẹ́gàn ìbúra nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kì yóò bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí ó ṣe yìí.

19“ ‘Nítorí náà Olúwa Olódùmarè wí pé: Bí mo ti wà láààyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀. 20Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, Èmi yóò mú ọ lọ Babeli láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi. 21Gbogbo ìgbèkùn àti ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.”

22“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lórí igi Kedari gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí. 2317.23: El 31.6; Mt 13.32; Mk 4.32; Lk 13.19.Ní ibi gíga òkè Israẹli ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso, yóò wa di igi Kedari tí ó lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀ 24Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkúrú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé.

“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì ṣe e.’ ”