กิจการของอัครทูต 17 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

กิจการของอัครทูต 17:1-34

ในเธสะโลนิกา

1เมื่อผ่านเมืองอัมฟีโปลิสและเมืองอปอลโลเนียแล้วพวกเขาก็มาถึงเมืองเธสะโลนิกาซึ่งมีธรรมศาลาของพวกยิว 2เปาโลเข้าไปในธรรมศาลาตามที่เขาเคยปฏิบัติมา และในวันสะบาโตทั้งสามสัปดาห์เปาโลได้ยกข้อพระคัมภีร์มาอภิปรายกับพวกเขา 3ชี้แจงและพิสูจน์ว่า พระคริสต์17:3 หรือพระเมสสิยาห์ต้องทนทุกข์และเป็นขึ้นจากตาย เปาโลกล่าวว่า “พระเยซูผู้นี้ที่ข้าพเจ้าประกาศแก่พวกท่านคือพระคริสต์17:3 หรือพระเมสสิยาห์4ชาวยิวบางคนเห็นด้วยและเข้าร่วมกับเปาโลและสิลาสเช่นเดียวกับชาวกรีกผู้ยำเกรงพระเจ้าจำนวนมากและสตรีคนสำคัญๆ อีกไม่น้อย

5แต่พวกยิวอิจฉาริษยาจึงระดมนักเลงจากตลาดรวมกลุ่มกันก่อการจลาจลในเมือง พวกเขาบุกเข้าไปหาตัวเปาโลกับสิลาสในบ้านของยาโสนเพื่อนำออกมาให้ฝูงชน17:5 หรือที่ประชุมของประชาชน 6แต่เมื่อไม่พบก็ลากตัวยาโสนกับพวกพี่น้องบางคนมาพบเจ้าหน้าที่ของเมืองและร้องตะโกนว่า “คนพวกนี้ที่ได้สร้างปัญหามาทั่วโลก บัดนี้ได้มาที่นี่ 7และยาโสนก็ต้อนรับพวกเขาไว้ในบ้านของตน คนพวกนี้ทั้งหมดท้าทายกฤษฎีกาของซีซาร์ พวกเขากล่าวว่ามีกษัตริย์อีกองค์หนึ่งที่เรียกว่าพระเยซู” 8เมื่อประชาชนและเจ้าหน้าที่ของเมืองได้ฟังดังนั้นก็ไม่พอใจลุกฮือขึ้น 9พวกเขาจึงให้ยาโสนกับคนอื่นๆ ประกันตัวแล้วปล่อยไป

ในเบเรอา

10ทันทีที่มืดค่ำพวกพี่น้องก็ส่งเปาโลกับสิลาสไปยังเมืองเบเรอา เมื่อพวกเขามาถึงก็เข้าไปในธรรมศาลาของพวกยิว 11ชาวเมืองเบเรอามีจิตใจสูงกว่าชาวเมืองเธสะโลนิกาเพราะพวกเขารับเรื่องนี้ด้วยความกระตือรือร้นและค้นพระคัมภีร์ทุกวันเพื่อตรวจสอบว่าสิ่งที่เปาโลกล่าวเป็นจริงหรือไม่ 12ชาวยิวหลายคนเชื่อเช่นเดียวกับสตรีคนสำคัญชาวกรีกจำนวนหนึ่งและบุรุษชาวกรีกอีกหลายคน

13เมื่อพวกยิวในเมืองเธสะโลนิกาทราบว่าเปาโลกำลังประกาศพระวจนะของพระเจ้าที่เมืองเบเรอา พวกเขาก็มาที่นั่นด้วย พวกเขาปลุกปั่นฝูงชนให้ลุกฮือขึ้น 14พวกพี่น้องจึงส่งเปาโลไปที่ชายฝั่งทันทีส่วนสิลาสกับทิโมธียังอยู่ที่เมืองเบเรอา 15ผู้คนที่คุ้มกันเปาโลนำเขาไปยังกรุงเอเธนส์จากนั้นก็รับคำสั่งกลับมาบอกสิลาสกับทิโมธีให้ไปสมทบกับเปาโลทันทีที่เป็นไปได้

ในกรุงเอเธนส์

16ขณะรอสิลาสกับทิโมธีอยู่ในกรุงเอเธนส์เปาโลก็ทุกข์ใจยิ่งนักที่เห็นเมืองนี้เต็มไปด้วยรูปเคารพ 17ดังนั้นเขาจึงยกเหตุผลมาอภิปรายกับพวกยิวและชาวกรีกที่ยำเกรงพระเจ้าในธรรมศาลาและกับผู้คนซึ่งเขาพบที่ย่านตลาดแต่ละวัน 18มีนักปรัชญาแนวเอปิคูเรียนและสโตอิกกลุ่มหนึ่งมาถกเถียงกับเขา บางคนเอ่ยว่า “เจ้าคนนี้มาพล่ามอะไร?” คนอื่นๆ กล่าวว่า “ดูเหมือนเขาจะนำเทพเจ้าต่างชาติมาเผยแพร่” ที่พวกเขาพูดเช่นนี้เพราะเปาโลประกาศข่าวประเสริฐเรื่องพระเยซูและการคืนพระชนม์ 19พวกเขาจึงนำตัวเปาโลมาที่สภาอาเรโอปากัสและกล่าวว่า “พวกเราขอทราบคำสอนใหม่ที่ท่านกำลังนำเสนอได้ไหม? 20ท่านนำความคิดแปลกๆ เข้ามา เราเลยอยากรู้ว่าสิ่งเหล่านี้มีความหมายอย่างไร” 21(ชาวเอเธนส์และชาวต่างชาติที่นั่นวันๆ ไม่ทำอะไรนอกจากพูดคุยและรับฟังความคิดใหม่ๆ)

22เปาโลจึงยืนขึ้นต่อหน้าที่ประชุมสภาอาเรโอปากัสแล้วกล่าวว่า “ชาวเอเธนส์ทั้งหลาย! ข้าพเจ้าเห็นว่าพวกท่านเคร่งศาสนามากในทุกด้าน 23เพราะขณะที่ข้าพเจ้าเดินไปทั่วและได้สังเกตดูสิ่งที่ท่านนมัสการข้าพเจ้าถึงกับพบแท่นบูชาแท่นหนึ่งที่มีคำจารึกไว้ว่า ‘แด่พระเจ้าที่ไม่รู้จัก’ บัดนี้ข้าพเจ้ามาประกาศแก่ท่านถึงสิ่งที่ท่านนมัสการทั้งที่ไม่รู้จัก

24“พระเจ้าองค์นี้ผู้ทรงสร้างโลกและสรรพสิ่งในโลกทรงเป็นเจ้าเหนือฟ้าสวรรค์และแผ่นดินโลก พระองค์ไม่ได้ประทับในวิหารที่สร้างขึ้นด้วยน้ำมือมนุษย์ 25และไม่ได้พึ่งการปรนนิบัติจากมือมนุษย์เสมือนหนึ่งว่าทรงต้องการสิ่งใดเพราะพระองค์เองคือผู้ประทานชีวิต ลมปราณ และสิ่งอื่นๆ ทั้งปวงแก่มนุษย์ 26จากมนุษย์เพียงคนเดียวพระองค์ทรงสร้างมนุษย์ทุกชาติให้อาศัยทั่วพิภพ พระองค์ทรงกำหนดเวลาและเขตแดนที่พวกเขาควรจะอยู่ 27พระเจ้าทรงทำเช่นนี้เพื่อมนุษย์จะได้แสวงหาพระองค์ เผื่อว่าพวกเขาจะไขว่คว้าหาพระองค์และพบพระองค์ แต่ว่าพระองค์ไม่ได้ทรงอยู่ไกลจากเราแต่ละคนเลย 28‘เพราะว่าในพระองค์เรามีชีวิต เคลื่อนไหว และเป็นอยู่’ เหมือนที่กวีบางคนในพวกท่านเองกล่าวว่า ‘เราเป็นเชื้อสายของพระองค์’

29“ฉะนั้นในเมื่อเราเป็นเชื้อสายของพระเจ้าเราก็ไม่ควรคิดว่าพระเจ้าทรงเป็นเหมือนทอง เงิน หรือหิน คือเป็นประติมากรรมที่สร้างขึ้นโดยการออกแบบและฝีมือของมนุษย์ 30ในอดีตพระเจ้าทรงมองข้ามความเขลาเช่นนั้น แต่บัดนี้ทรงบัญชามนุษย์ทั้งปวงทั่วทุกแห่งให้กลับใจใหม่ 31เพราะพระองค์ได้ทรงกำหนดวันหนึ่งไว้ วันซึ่งจะทรงพิพากษาโลกด้วยความยุติธรรมโดยผู้หนึ่งที่ได้ทรง แต่งตั้งไว้ พระองค์ทรงยืนยันข้อนี้แก่คนทั้งปวงโดยให้ผู้นั้นเป็นขึ้นจากตาย”

32เมื่อพวกเขาได้ยินเรื่องการเป็นขึ้นจากตายบางคนก็เย้ยหยันแต่บางคนกล่าวว่า “เราอยากฟังท่านพูดเรื่องนี้อีก” 33แล้วเปาโลก็ออกจากสภา 34มีบางคนติดตามเปาโลไปและได้เชื่อ เช่น ดิโอนิสิอัสผู้เป็นสมาชิกคนหนึ่งของสภาอาเรโอปากัส หญิงคนหนึ่งชื่อดามาริส และคนอื่นๆ อีกจำนวนหนึ่ง

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 17:1-34

Ní Tẹsalonika

1Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà: 2Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. 3Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” 4A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.

5Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. 6Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. 7Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” 8Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. 9Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.

Ní Berea

10Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ. 11Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀. 12Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Giriki ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin ti kì í ṣe díẹ̀.

13Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalonika mọ̀ pé, Paulu ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Berea, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè. 14Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun: ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea. 15Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

Ní Ateni

16Nígbà tí Paulu dúró dè wọ́n ni Ateni, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà. 17Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sinagọgu, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́. 18Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Epikure ni àti tí àwọn Stoiki kó tì í. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí oníwàásù àjèjì òrìṣà, Wọ́n sọ èyí nítorí Paulu ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu àti àjíǹde fún wọn.” 19Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Areopagu, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ tuntun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́? 20Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá sí etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.” 21Nítorí gbogbo àwọn ará Ateni, àti àwọn àjèjì tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí kí a máa gbọ́ ohun tuntun lọ.

22Paulu si dìde dúró láàrín Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Ateni, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún ẹ̀sìn lọ́pọ̀lọpọ̀. 23Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí sí:

fún ọlọ́run àìmọ̀.

Ǹjẹ́ ẹni tí ẹ̀yin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń sọ fún yin.

2417.24-25: Isa 42.5.“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́; 25Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn. 26Ó sì tí tipasẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn; 27Ọlọ́run ṣe eléyìí kí wọn bá le máa wa, bóyá wọn yóò lè ṣàfẹ́rí rẹ̀, kí wọn sì rí í. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa: 28Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láààyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkára yín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’

29“Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, ẹni tí a wa n sìn dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya ère àwòrán rẹ̀. 30Pẹ̀lúpẹ̀lú ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí fojú fò dá; ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà; 31Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”

32Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ti àjíǹde òkú, àwọn mìíràn ń ṣẹ̀fẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn mìíràn wí pé, “Àwa o tún nǹkan yìí gbọ́ lẹ́nu rẹ̀.” 33Bẹ́ẹ̀ ni Paulu sì jáde kúrò láàrín wọn. 34Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan fi ara mọ́ ọn, wọ́n sì gbàgbọ́: nínú àwọn ẹni tí Dionisiu ara Areopagu wà, àti obìnrin kan tí a ń pè ni Damari àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn.