กันดารวิถี 34 – TNCV & YCB

Thai New Contemporary Bible

กันดารวิถี 34:1-29

เขตแดนคานาอัน

1องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 2“จงสั่งประชากรอิสราเอลว่า ‘เมื่อเจ้าทั้งหลายเข้าสู่คานาอันดินแดนซึ่งจะแบ่งสรรยกให้เป็นมรดกของเจ้านั้นจะมีพรมแดนดังนี้

3“ ‘ดินแดนทางใต้คือถิ่นกันดารศิน เลียบไปตามพรมแดนเอโดม เขตแดนทางใต้ด้านฝั่งตะวันออกเริ่มจากทะเลตาย 4ไล่ลงมาผ่านช่องแคบแมงป่องไปยังศิน ลงใต้ไปที่คาเดชบารเนีย เรื่อยมาถึงฮาซารัดดาร์และอัสโมน 5จากอัสโมนวกไปตามลำน้ำแห่งอียิปต์และสิ้นสุดลงที่ทะเลเมดิเตอร์เรเนียน

6“ ‘พรมแดนตะวันตกของเจ้าคือชายฝั่งทะเลเมดิเตอร์เรเนียน

7“ ‘พรมแดนด้านเหนือของเจ้าเริ่มจากทะเลเมดิเตอร์เรเนียนเรื่อยไปถึงภูเขาโฮร์ 8ไปยังเลโบฮามัท34:8 หรือทางเข้าสู่ฮามัท ไปเศดัด 9เรื่อยไปถึงศิโฟรนจนจดฮาซาเรนัน

10“ ‘พรมแดนตะวันออกเริ่มจากฮาซาเรนันจนถึงที่เชฟาม 11เรื่อยลงมาถึงริบลาห์ ด้านตะวันออกของเมืองอายิน ไล่มาตามลาดเขาด้านตะวันออกของทะเลคินเนเรท34:11 คือ กาลิลี 12แล้วเรื่อยมาตามแม่น้ำจอร์แดนและสิ้นสุดที่ทะเลเกลือ

“ ‘นี่จะเป็นดินแดนของพวกเจ้าตามพรมแดนโดยรอบ’ ”

13โมเสสสั่งชนอิสราเอลว่า “จงจับฉลากแบ่งสรรดินแดนนี้เป็นมรดก องค์พระผู้เป็นเจ้าได้ทรงบัญชาไว้ให้แบ่งกันในหมู่เก้าเผ่าและอีกครึ่งเผ่า 14เพราะเผ่ารูเบน กาดและมนัสเสห์ครึ่งเผ่าได้รับมรดกของตนแล้ว 15สองเผ่าและครึ่งเผ่านี้ได้รับดินแดนทางฟากตะวันออกของแม่น้ำจอร์แดนแห่งเยรีโคเป็นมรดก”

16องค์พระผู้เป็นเจ้าตรัสกับโมเสสว่า 17“ต่อไปนี้เป็นรายชื่อผู้ที่จะทำหน้าที่จัดสรรมรดกในดินแดนคือ ปุโรหิตเอเลอาซาร์ โยชูวาบุตรนูน 18และผู้นำซึ่งได้รับแต่งตั้งจากแต่ละเผ่า เพื่อช่วยแบ่งสรรดินแดนนั้น 19รายชื่อของพวกเขา ได้แก่

คาเลบบุตรเยฟุนเนห์

จากเผ่ายูดาห์

20เชมูเอลบุตรอัมมีฮูด

จากเผ่าสิเมโอน

21เอลีดาดบุตรคิสโลน

จากเผ่าเบนยามิน

22บุคคีบุตรโยกลี

ผู้นำจากเผ่าดาน

23ฮันนีเอลบุตรเอโฟด

ผู้นำจากเผ่ามนัสเสห์บุตรโยเซฟ

24เคมูเอลบุตรชิฟทาน

ผู้นำจากเผ่าเอฟราอิมบุตรโยเซฟ

25เอลีซาฟานบุตรปารนาค

ผู้นำจากเผ่าเศบูลุน

26ปัลทีเอลบุตรอัสซาน

ผู้นำจากเผ่าอิสสาคาร์

27อาหิฮูดบุตรเชโลมี

ผู้นำจากเผ่าอาเชอร์

28เปดาเฮลบุตรอัมมีฮูด

ผู้นำจากเผ่านัฟทาลี”

29คนเหล่านี้คือผู้ที่องค์พระผู้เป็นเจ้าทรงบัญชาให้จัดสรรมรดกแก่ชนอิสราเอลในดินแดนคานาอัน

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 34:1-29

Ààlà ti Kenaani

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kenaani, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí:

334.3-5: Jo 15.1-4.“ ‘Ìhà gúúsù yín yóò bọ́ sí ara aginjù Sini lẹ́bàá Edomu, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà gúúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀, 4kọjá lọ sí gúúsù Akrabbimu, tẹ̀síwájú lọ si Sini: kó bọ́ si gúúsù Kadeṣi-Barnea, kí o sì dé Hasari-Addari, kí o sì kọjá sí Asmoni. 5Kí òpin ilẹ̀ rẹ̀ kí ó sì yíká láti Asmoni lọ dé odò Ejibiti, Òkun ni yóò sì jẹ òpin rẹ.

6Ìhà ìwọ̀-oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà ìwọ̀-oòrùn.

7Fún ààlà ìhà àríwá, fa ìlà láti Òkun ńlá lọ sí orí òkè Hori 8Àti láti orí òkè Hori sí Lebo-Hamati. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Ṣedadi, 9Tẹ̀síwájú lọ sí Sifroni, kí o sì fò pín si ní Hasari-Enani, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá.

10Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ tiyín ní ìhà ìlà-oòrùn láti Hasari-Enani lọ dé Ṣefamu. 11Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn. 12Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun.

“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

1334.13-15: Jo 14.1-5.Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀. 14Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn. 15Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.”

16Olúwa sọ fún Mose pé, 17“Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni. 18Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

19“Èyí ni orúkọ wọn:

“Kalebu ọmọ Jefunne, láti ẹ̀yà Juda;

20Ṣemueli ọmọ Ammihudu, láti ẹ̀yà Simeoni;

21Elidadi ọmọ Kisloni, láti ẹ̀yà Benjamini;

22Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;

23Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,

24Kemueli ọmọ Ṣiftani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Efraimu, ọmọ Josẹfu;

25Elisafani ọmọ Parnaki, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Sebuluni;

26Paltieli ọmọ Assani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Isakari;

27Ahihudu ọmọ Ṣelomi, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Aṣeri;

28Pedaheli ọmọ Ammihudu, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Naftali.”

29Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.