Mateusza 26 – SZ-PL & YCB

Słowo Życia

Mateusza 26:1-75

Spisek przeciw Jezusowi

1Po zakończeniu tego nauczania Jezus rzekł do uczniów:

2—Za dwa dni rozpoczyna się święto Paschy i Ja, Syn Człowieczy, zostanę zdradzony i ukrzyżowany.

3Tymczasem na dziedzińcu rezydencji najwyższego kapłana, Kajfasza, zebrali się inni kapłani oraz starsi. 4Postanowili potajemnie uwięzić i zabić Jezusa.

5—Nie możemy jednak zrobić tego podczas święta—mówili—bo spowoduje to rozruchy.

Namaszczenie Jezusa w Betanii

6Jezus tymczasem zatrzymał się w Betanii, w domu Szymona Trędowatego. 7Wtedy właśnie przyszła tam pewna kobieta z butelką bardzo drogiego, wonnego olejku i wylała go na głowę Jezusa. 8Widząc to, uczniowie oburzyli się:

—Co za marnotrawstwo! 9Przecież można było sprzedać te perfumy i rozdać pieniądze biednym!

10—Dlaczego ją krytykujecie?—zapytał Jezus, widząc ich reakcję. —Przecież spełniła dobry uczynek! 11—Biedni zawsze będą wśród was, a Mnie już wkrótce zabraknie. 12Namaszczając tym olejkiem, przygotowała Mnie na pogrzeb. 13Zapewniam was: Gdziekolwiek na świecie będzie głoszona dobra nowina, wszędzie będzie się mówić o tym, co zrobiła, i będzie się o niej pamiętać.

Judasz zgadza się zdradzić Jezusa

14Tymczasem Judasz z Kariotu, jeden z Dwunastu, poszedł do najwyższych kapłanów 15i zapytał:

—Ile mi zapłacicie, jeśli wydam wam Jezusa?

I dali mu trzydzieści srebrnych monet. 16Od tej chwili Judasz czekał już tylko na sprzyjającą okazję, aby wydać Jezusa.

Ostatnia wieczerza

17W pierwszym dniu święta Paschy, uczniowie zapytali Jezusa:

—Gdzie mamy przygotować kolację paschalną?

18—Idźcie do miasta!—powiedział. —Udajcie się do naszego znajomego i powiedzcie mu: „Nasz Nauczyciel zawiadamia: Nadchodzi już czas! U ciebie chcę spożyć z moimi uczniami świąteczną kolację”.

19Uczniowie zrobili tak, jak im polecił, i zajęli się przygotowaniem posiłku.

20Wieczorem, wraz z Dwunastoma, Jezus zajął miejsce przy stole. 21Gdy zaczęli posiłek, powiedział:

—Mówię wam: Jeden z was, siedzących tu ze Mną, zdradzi Mnie.

22—Ale to chyba nie ja, Panie?—mówili zasmuceni jeden przez drugiego.

23—To ten, który jednocześnie ze Mną sięga do półmiska—odpowiedział. 24—Ja, Syn Człowieczy, muszę umrzeć, zgodnie z tym, co dawno zapowiedzieli prorocy. Marny jednak los tego, kto Mnie wyda. Lepiej byłoby, aby się wcale nie urodził!

25Judasz również Go zapytał:

—To ja, Nauczycielu?

—Sam to powiedziałeś—odrzekł Jezus.

26Później, podczas kolacji, Jezus wziął do rąk chleb. Podziękował za niego Bogu, połamał go na kawałki, i podał uczniom, mówiąc:

—Weźcie i jedzcie, to jest moje ciało.

27Wziął też do ręki kielich z winem. Podziękował, podał uczniom, i powiedział:

—Pijcie z niego wszyscy. 28To jest moja krew, pieczętująca przymierze. Przelewam ją, aby wielu otrzymało przebaczenie grzechów. 29Mówię wam, że nie skosztuję już wina do dnia, gdy będę pił nowe wino w królestwie mojego Ojca.

30Potem zaśpiewali pieśń i poszli na Górę Oliwną.

Jezus zapowiada zaparcie się Piotra

Wtedy Jezus powiedział:

31—Jeszcze tej nocy wszyscy Mnie opuścicie. Stanie się tak, jak Bóg zapowiedział ustami proroków:

„Uderzę pasterza

i rozproszą się owce jego stada”.

32Lecz gdy znów powrócę do życia, udam się do Galilei i tam się z wami spotkam.

33—Ja nigdy Cię nie opuszczę!—zapewniał Piotr. —Nawet jeśli inni odejdą od Ciebie!

34—Zapewniam cię, że jeszcze tej nocy, zanim o świcie zapieje kogut, trzy razy zaprzeczysz, że Mnie znasz—odpowiedział Jezus.

35—Nigdy!—zaprotestował Piotr. —Nie wyprę się Ciebie, nawet gdybym miał iść z Tobą na śmierć!

Pozostali również przysięgali wierność Jezusowi.

W Getsemane

36Następnie wszyscy razem udali się do ogrodu Getsemane. Gdy dotarli na miejsce, Jezus rzekł:

—Usiądźcie tutaj, a ja pójdę tam się modlić.

37Zabrał ze sobą tylko Piotra oraz synów Zebedeusza—Jakuba i Jana. I ogarnął Go smutek oraz głęboki niepokój.

38—Moją duszę ogarnął śmiertelny smutek—powiedział. —Zostańcie ze Mną i czuwajcie.

39Odszedł na bok, padł na twarz i modlił się:

—Ojcze mój, jeśli to możliwe, oddal ode Mnie ten „kielich cierpienia”. Jednak to Twoja wola niech się stanie, a nie to, czego ja chcę.

40Wrócił do trzech uczniów i zastał ich śpiących. Wtedy powiedział do Piotra:

—Nie daliście rady czuwać ze Mną nawet przez godzinę? 41Uważajcie i módlcie się, abyście nie poddali się pokusie! Duch jest gorliwy, ale ciało słabe.

42Ponownie odszedł i modlił się:

—Ojcze mój, jeśli nie może Mnie ominąć ten „kielich”, to niech się stanie Twoja wola.

43Lecz uczniowie byli tak bardzo zmęczeni, że gdy do nich wrócił, znowu spali. 44Odszedł więc po raz trzeci i raz jeszcze modlił się o to samo. 45Po skończeniu modlitwy wrócił do nich i powiedział:

—Wciąż spokojnie śpicie i odpoczywacie? Wybiła moja godzina. Teraz Ja, Syn Człowieczy, zostanę wydany w ręce grzeszników. 46Wstańcie, chodźmy! Nadchodzi już ten, który Mnie zdradził!

Aresztowanie Jezusa

47Ledwie skończył mówić, stanął przed Nim Judasz, jeden z Dwunastu, na czele zgrai uzbrojonej w miecze i pałki, wysłanej przez najwyższych kapłanów i starszych. 48Ten zdrajca tak się z nimi umówił: „Łapcie tego, którego pocałuję na powitanie”. 49Gdy więc tylko się zbliżyli, Judasz podszedł do Jezusa.

—Witaj, Mistrzu!—rzekł i przywitał Go pocałunkiem.

50—Przyjacielu!—rzekł Jezus. —Po co przyszedłeś?

Wówczas pozostali rzucili się na Niego i złapali Go. 51Wtedy jeden z uczniów szybko wyjął miecz, zamachnął się i odciął ucho słudze najwyższego kapłana.

52—Schowaj miecz!—powiedział Jezus. —Ci, którzy mieczem walczą, od miecza giną. 53Myślisz, że na moją prośbę Ojciec nie posłałby tu dwunastu oddziałów aniołów? 54Ale czy wtedy wypełniłyby się zapowiedzi Pisma?

55Następnie zwrócił się do tych, którzy Go aresztowali:

—Czy jestem jakimś groźnym przestępcą, że przyszliście po Mnie aż tak uzbrojeni? Dlaczego nie zatrzymaliście Mnie w świątyni? Przecież codziennie tam nauczałem! 56Wszystko jednak dzieje się zgodnie z tym, co przepowiedziały o Mnie proroctwa.

Wtedy wszyscy uczniowie opuścili Go i uciekli.

Jezus przed Wysoką Radą

57Napastnicy zaprowadzili Jezusa do rezydencji Kajfasza, u którego wkrótce zebrali się przywódcy religijni i starsi. 58Piotr zaś, który podążał za Jezusem, trzymając się z daleka, wszedł za nimi i usiadł razem z żołnierzami. Czekał, co będzie dalej.

59Najwyżsi kapłani wraz z całą Wysoką Radą przesłuchiwali świadków, by znaleźć jakieś fałszywe oskarżenie przeciw Jezusowi i skazać Go na śmierć. 60Ale pomimo wielu fałszywych zeznań nie udało się im to. W końcu znalazło się dwóch, 61którzy zgodnie oświadczyli:

—Ten człowiek powiedział: „Mogę zburzyć Bożą świątynię i w trzy dni ją odbudować!”.

62Wtedy najwyższy kapłan wstał i zapytał Jezusa:

—Nie będziesz się bronił wobec tych oskarżeń?

63Lecz Jezus milczał. Wtedy najwyższy kapłan zadał mu kolejne pytanie:

—W imię żyjącego Boga żądam, abyś odpowiedział: Jesteś Mesjaszem, Synem Bożym?

64—Sam to potwierdziłeś—rzekł Jezus. —Mówię wam: Wkrótce zobaczycie Mnie, Syna Człowieczego, zasiadającego na tronie z Bogiem i powracającego w obłokach na ziemię.

65Słysząc to, najwyższy kapłan rozdarł szaty i powiedział:

—To bluźnierstwo! Czego więcej trzeba? Po co nam świadkowie? Sami słyszeliście bluźnierstwo! 66Jaki jest wasz wyrok?

—Kara śmierci!—zawołali.

67I zaczęli pluć Jezusowi w twarz i bić po głowie. Ci, którzy Go bili, 68szyderczo wołali:

—Teraz prorokuj, Mesjaszu! Zgadnij, kto Cię teraz uderzył?

Piotr wypiera się Jezusa

69Tymczasem Piotr wciąż przebywał na dziedzińcu rezydencji. Nagle podeszła do niego jakaś dziewczyna i powiedziała:

—Ty też byłeś z Jezusem z Galilei!

70—Nie wiem, o czym mówisz!—zaprzeczył wobec wszystkich Piotr.

71Odszedł do bramy wejściowej, ale zauważyła go tam inna służąca.

—On był z Jezusem z Nazaretu!—powiedziała do stojących.

72—Nawet nie znam tego Człowieka!—przysięgając zaprzeczył Piotr.

73Po pewnej chwili stojący tam ludzie podeszli do niego i stwierdzili:

—Na pewno i ty jesteś jednym z jego uczniów. Twój galilejski akcent cię zradza.

74—Naprawdę Go nie znam!!!—znowu zaczął się zaklinać i przysięgać.

I wtedy właśnie zapiał kogut. 75Wówczas Piotr przypomniał sobie słowa Jezusa: „Zanim o świcie zapieje kogut, trzy razy zaprzeczysz, że Mnie znasz”. Odszedł stamtąd i gorzko zapłakał.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 26:1-75

Ìdìtẹ̀ mọ́ Jesu

126.1: Mt 7.28; 11.1; 13.53; 19.1.Nígbà tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, 226.2-5: Mk 14.1-2; Lk 22.1-2; Jh 11.47-53.“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”

3Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa. 4Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á. 5Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”

A fi òróró kun Jesu lára ní Betani

626.6-13: Mk 14.3-9; Jh 12.1-8; Lk 7.36-38.Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀; 7Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.

8Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? 9Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”

10Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi 11Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo. 12Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni. 13Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìhìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”

Judasi gbà láti fi Jesu hàn

1426.14-16: Mk 14.10-11; Lk 22.3-6.Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 1526.15: Ek 21.32; Sk 11.12.Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. 16Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

Oúnjẹ alẹ́ ìkẹyìn

1726.17-19: Mk 14.12-16; Lk 22.7-13.Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”

1826.18: Mt 26.45; Jh 7.6; 12.23; 13.1; 17.1.Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ” 1926.19: Mt 21.6; De 16.5-8.Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.

2026.20-24: Mk 14.17-21; Lk 22.14,21-23; Jh 13.21-30.Ní àṣálẹ́ ọjọ́ kan náà, bí Jesu ti jókòó pẹ̀lú àwọn méjìlá, 21nígbà tí wọ́n sì ń jẹun, ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀kan nínú yín yóò fi mí hàn.”

22Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?”

23Jesu dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn. 24Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”

25Judasi, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Rabbi, èmi ni bí?”

Jesu sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i.”

2626.26-29: Mk 14.22-25; Lk 22.17-19; 1Kọ 10.16; 11.23-26; Mt 14.19; 15.36.Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”

27Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀. 28Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn. 29Sì kíyèsi àwọn ọ̀rọ̀ mi. Èmi kì yóò tún mu nínú ọtí wáìnì yìí mọ́ títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín ní ìjọba Baba mi.”

3026.30-35: Mk 14.26-31; Lk 22.33-34,39; Jh 14.31; 18.1; 13.36-38.Wọ́n sì kọ orin kan, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sórí òkè Olifi.

Jesu sọ pé Peteru yóò sẹ́ òun

3126.31: Sk 13.7; Jh 16.32.Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé:

“ ‘Èmi yóò kọlu olùṣọ́-àgùntàn

a ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’

3226.32: Mt 28.7,10,16.Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo bá jí dìde, èmi yóò ṣáájú yín lọ sí Galili.”

33Peteru sì dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”

34Jesu wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ pé, ní òru yìí, kí àkùkọ kí ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.”

35Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.

Jesu ní Getsemane

3626.36-46: Mk 14.32-42; Lk 22.40-46.Nígbà náà ni Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi kan ti à ń pè ní ọgbà Getsemane, ó wí fún wọn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbàdúrà lọ́hùn ún ni.” 37Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. 3826.38: Jh 12.27; Hb 5.7-8.Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”

3926.39: Jh 18.11; Mt 20.22.Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

40Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Peteru, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 41Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹwò. Nítorí Ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”

4226.42: Jh 4.34; 5.30; 6.38.Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá bí kò ṣe pé mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”

43Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun. 44Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.

4526.45: Mt 26.18; Jh 12.23; 13.1; 17.1.Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

A mú Jesu

4726.47-56: Mk 14.43-50; Lk 22.47-53; Jh 18.2-11.Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà Júù wá. 48Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi ààmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.” 49Nísinsin yìí, Judasi wá tààrà sọ́dọ̀ Jesu, ó wí pé, “Àlàáfíà, Rabbi” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

5026.50: Mt 20.13; 22.12.Jesu wí pé, “Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá.”

Àwọn ìyókù sì sún síwájú wọ́n sì mú Jesu. 51Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì sá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.

5226.52: Gẹ 9.6; If 13.10.Jesu wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni a ó fi idà pa. 53Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) angẹli méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 54Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsin yìí?”

5526.55: Lk 19.47; Jh 18.19-21.Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà. 56Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ.

Níwájú Sahẹndiri

5726.57-75: Mk 14.53-72; Lk 22.54-71; Jh 18.12-27.Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí. 58Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu.

59Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un. 60Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan.

Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde. 6126.61: Mt 24.2; 27.40; Ap 6.14; Jh 2.19.Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Èmi lágbára láti wó tẹmpili Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”

62Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?” 6326.63: Mt 27.11; Jh 18.33.Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́.

Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”

6426.64: Mt 16.28; Da 7.13; Sm 110.1.Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”

6526.65: Nu 14.6; Ap 14.14; Le 24.16.Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” 66Ki ni ẹ ti rò èyí sí.

Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”

67Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú. 68Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kristi, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”

Peteru sẹ́ Jesu

69Lákòókò yìí, bí Peteru ti ń jókòó ní àgbàlá, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jesu ti Galili.”

70Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”

71Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.”

72Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”

73Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa ààmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”

74Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.”

Lójúkan náà àkùkọ sì kọ. 7526.75: Mt 26.34.Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.