2 Koryntian 5 – SZ-PL & YCB

Słowo Życia

2 Koryntian 5:1-21

Przyszłe ciała

1Wiemy przecież, że gdy runie doczesny dom, którym jest nasze ciało, otrzymamy od Boga nowe mieszkanie w niebie, które nie będzie zbudowane przez ludzi. 2Obecne ciało sprawia nam wiele trudności, dlatego tęsknimy za tym nowym ciałem w niebie. 3Nie będziemy bowiem bezcielesnymi duchami, ale otrzymamy nowe ciała.

4Chociaż trudno nam żyć w naszych obecnych ciałach, to nie chcielibyśmy umrzeć i rozstać się z nimi. Wolelibyśmy, aby zostały one od razu zastąpione przez te nowe ciała niebiańskie. 5Pamiętajcie, że to Bóg jest Tym, który to wszystko dla nas przygotował, a jako gwarancję już teraz dał nam Ducha Świętego. 6Dlatego możemy być pewni, że da nam to, co przygotował. Teraz bowiem, żyjąc w naszych śmiertelnych ciałach, nie jesteśmy jeszcze w naszym prawdziwym domu—u Pana. 7Idziemy więc przez życie kierując się wiarą, a nie tym, co widzimy. 8Wiedząc o tym wszystkim, nie boimy się śmierci i wolelibyśmy już pożegnać nasze ciała i odejść do Pana. 9Zawsze pragniemy też czynić to, co Mu się podoba—niezależnie od tego, czy jeszcze żyjemy w tych ciałach, czy nie. 10Wszyscy bowiem staniemy przed sądem Chrystusa. I każdy otrzyma wtedy to, na co zasłużył dobrymi lub złymi czynami, dokonanymi w ziemskim ciele.

Misja pojednania

11Wiemy, że Bóg oczekuje respektu, dlatego zachęcamy ludzi do przyjęcia dobrej nowiny. Bóg wie, dlaczego to czynimy, a mamy nadzieję, że nasze intencje są jasne także dla was i że nie budzą waszych zastrzeżeń. 12Nie chcemy zabiegać o waszą przychylność. Pragniemy jedynie, abyście mogli być z nas dumni i byście mieli argument przeciwko tym, którzy szczycą się sprawami powierzchownymi, a nie zwracają uwagi na stan swojego serca. 13Jeśli postępujemy jak szaleńcy, robimy to dla Boga. A jeśli zachowujemy rozsądek, czynimy to ze względu na was. 14Jesteśmy bowiem owładnięci miłością Chrystusa i twierdzimy, że skoro On jeden umarł za wszystkich, to znaczy, że wszyscy poumierali. 15Taka bowiem jest prawda: Jezus umarł za wszystkich, aby ci, którzy dzięki Niemu żyją, odtąd żyli już nie dla siebie, ale dla Tego, który za nich umarł i zmartwychwstał.

16Dlatego my nie patrzymy już na nikogo z ludzkiego punktu widzenia. A nawet jeśli poznaliśmy Chrystusa jako człowieka, to już w ten sposób na Niego nie patrzymy. 17Jeśli ktoś bowiem uwierzył Chrystusowi, jest zupełnie nową istotą. To, co było kiedyś, minęło. Teraz zaczęło się coś zupełnie nowego.

18A wszystko to pochodzi od Boga, który dzięki Chrystusowi pojednał nas ze sobą i—co więcej—powierzył nam misję jednania z Nim innych ludzi. 19Bóg przez Chrystusa pojednał bowiem ze sobą świat, nie wypominając ludziom ich grzechów, nam zaś polecił przekazywać innym wieść o tym pojednaniu. 20Mając więc za sobą autorytet Chrystusa, jesteśmy wysłannikami samego Boga, który przez nas przemawia do ludzi. Dlatego w imieniu Chrystusa błagamy: Pojednajcie się z Bogiem! 21Chrystus nigdy nie zgrzeszył, ale Bóg obciążył Go karą za nasze grzechy, abyśmy dzięki Niemu mogli zostać uniewinnieni przez Boga.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 5:1-21

Ibùgbé wa ọrun

1Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. 2Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. 3Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. 4Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì. 5Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.

6Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. 7Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. 8Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. 9Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀

11Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 125.12: 2Kọ 3.1.Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 145.14: Ro 5.15; 6.6-7.Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 175.17: Ro 16.7; Ga 6.15.Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 185.18: 1Kọ 11.12; Kl 1.20; Ro 5.10.Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 205.20: Ef 6.20.Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” 215.21: Hb 4.15; 7.25; 1Pt 2.22; 1Jh 3.5; Ap 3.14.Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.