1 Koryntian 2 – SZ-PL & YCB

Słowo Życia

1 Koryntian 2:1-16

1Przyjaciele, ja także, gdy do was przybyłem i opowiadałem wam o Bożej tajemnicy, nie używałem wielkich słów i błyskotliwych myśli. 2Postanowiłem bowiem mówić tylko o Jezusie Chrystusie i Jego śmierci na krzyżu. 3Stanąłem przed wami jako słaby człowiek—nieśmiały i drżący ze strachu. 4Moje nauczanie nie było podobne do przemówień mędrców, ale było za to pełne Ducha i mocy Boga. 5Chciałem bowiem, aby wasza wiara opierała się właśnie na Jego mocy, a nie na ludzkiej mądrości.

Mądrość od Ducha

6A jednak to, co głosimy, ludzie dojrzali w wierze przyjmują jako mądrość, choć nie jest to mądrość tego świata ani jego przemijających przywódców. 7Mówimy bowiem o tajemnej mądrości samego Boga, która, ze względu na nas, była ukryta przez całe wieki. 8Żaden z przywódców tego świata jej nie pojął, bo gdyby było inaczej, nie ukrzyżowaliby Pana chwały. 9Pismo mówi:

„Dla tych, którzy kochają Boga,

przygotował On rzeczy,

jakich nikt nigdy nie widział,

o jakich nikt nigdy nie słyszał,

i jakie nikomu nawet nie przyszły na myśl”.

10Bóg objawił to nam przez swojego Ducha! On bowiem przenika wszystko i zna najgłębsze Boże tajemnice. 11Kto wie, co kryje się w człowieku, jeśli nie on sam, czyli jego duch? Podobnie nikt, poza Duchem Bożym, nie może wniknąć w Boga. 12Nie przyjęliśmy przecież ducha tego świata. Otrzymaliśmy Ducha Boga, abyśmy mogli zrozumieć, czym nas obdarował. 13I mówimy o tym nie w błyskotliwych słowach ludzkiej mądrości, ale słowami pochodzącymi od Ducha Świętego—duchowe sprawy wyrażając w duchowy sposób. 14Człowiek, kierujący się tylko zmysłami, nie rozumie rzeczy pochodzących od Ducha Bożego. Wydają mu się głupie i nie jest w stanie ich pojąć, bo można je zrozumieć tylko dzięki Duchowi. 15Człowiek kierowany przez Ducha Świętego rozumie zaś to wszystko, ale inni go nie rozumieją. 16Pismo mówi:

„Kto ogarnie myśli Pana?

Kto może zostać Jego doradcą?”.

My znamy zamiary Chrystusa!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 2:1-16

12.1: 1Kọ 1.17.Nígba tí èmí tọ̀ yín wá, ẹ̀yin ará, kì í ṣe nípa ọ̀rọ̀ gíga àti ọgbọ́n gíga ni mo fi bá yín sọ̀rọ̀, nígbà tí èmi ń sọ̀rọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run fún un yín. 22.2: Ga 6.14; 1Kọ 1.23.Èmi ti pinnu láti má mọ ohunkóhun nígbà ti mo wà láàrín yín bí kò ṣe Jesu Kristi, ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 32.3: Ap 18.1,6,12; 1Kọ 4.10; 2Kọ 11.30.Èmi sì tọ̀ yín wá ni àìlera, àti ní ẹ̀rù, àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwárìrì. 42.4: Ro 15.19; 1Kọ 4.20.Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí. 52.5: 2Kọ 4.7; 6.7; 1Kọ 12.9.Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

Ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí wá

62.6: Ef 4.13.Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán 72.7: Ro 8.29-30.Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa. 82.8: Ap 7.2; Jk 2.1.Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀. Ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tún kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 92.9: Isa 64.4; 65.17.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Ojú kò tí ì rí,

etí kò tí í gbọ́,

kò sì ọkàn ènìyàn tí ó tí í mọ̀

ohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”

102.10: Mt 11.25; 13.11; 16.17; Ef 3.3,5.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀.

Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àṣírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ. 11Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni ti ó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bí kò ṣe Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnrarẹ̀. 122.12: Ro 8.15.Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 132.13: 1Kọ 1.17.Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 142.14: 1Kọ 1.18; Jk 3.15.Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 152.15: 1Kọ 3.1; 14.37; Ga 6.1.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

162.16: Isa 40.13; Ro 11.34.“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,

ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.