Židům 3 – SNC & YCB

Slovo na cestu

Židům 3:1-19

Ježíš je srovnáván s Mojžíšem

1Proto se, bratři Bohem povolaní a Bohu oddaní, snažte poznávat Ježíše, který byl Božím vyslancem na zemi a nyní je naším zástupcem u Boha. 2Nezpronevěřil se Bohu, který jej ustanovil. Byl věrný jako Mojžíš, který se staral o Boží lid. 3-4Ale Ježíš převyšuje Mojžíše, jako tvůrce převyšuje své dílo. Vždyť on jako Bůh stvořil vše.

5Mojžíš byl pouze svědek toho, co pověděl Bůh. Byl věrný služebník Božího lidu. 6Kristus však jako Boží Syn je naším Pánem a zůstane jím, jestliže si až do konce zachováme pevnou jistotu a radostnou naději.

Nyní je čas naslouchat Bohu

7Proto nás Duch svatý napomíná:

„Když dnes zaslechnete jeho hlas,

8nezatvrzujte se ve vzdoru proti němu jako Izraelci při zkoušce na poušti,

9kde si vaši otcové žádali důkazy a tak mne pokoušeli.

10To pokolení se mi zošklivilo a řekl jsem:

‚Nerozumí sami sobě,

ani nechápou mé cesty.

11Proto jsem v hněvu přísahal,

že nedosáhnou odpočinku,

který jsem jim připravil.‘ “

12Dejte si tedy pozor, bratři, aby se ve vás neuhnízdilo zlo a nevěra, které by vás odváděly od živého Boha. 13Zkoumejte se každý den, dokud je k tomu příhodná chvíle, aby se někdo z vás nezatvrdil zaslepující a mámivou svůdností hříchu. 14Máme podíl na všem, co náleží Kristu, když setrváme do konce v počáteční důvěře. Ale vraťme se ke slovům:

15„Když dnes zaslechnete Boží hlas,

nezatvrzujte se vzpurně proti němu.“

16Kdo se to vlastně vzbouřil, když zaslechl Boží hlas? Ti, které Mojžíš vyvedl z Egypta. 17A koho měl Bůh v ošklivosti po čtyřicet let? Ty neposlušné, kteří pak zahynuli na poušti. 18-19Přísahal jim, že nedosáhnou odpočinku, který jim připravil. Nemohli ho dosáhnout pro nevěru.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Heberu 3:1-19

Jesu pọ̀ ju Mose lọ

1Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; 23.2: Nu 12.7.Ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. 3Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. 4Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. 53.5: Nu 12.7.Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. 6Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

Ìkìlọ̀ fún aláìgbàgbọ́

73.7-11: Sm 95.7-11.Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

8Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,

bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,

bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù:

9Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,

tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.

10Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,

mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn;

wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’

11Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,

‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”

12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin; 153.15: Sm 95.7-8.Nígbà tí a ń wí pé:

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

ẹ má sé ọkàn yin le,

bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”

163.16-19: Nu 14.1-35.Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 173.17: Nu 14.29.Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù? 18Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn? 19Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.