Římanům 7 – SNC & YCB

Slovo na cestu

Římanům 7:1-25

Neslužme liteře zákona, ale živému Kristu

1Milí, bratři, vy se přece dobře vyznáte v zákoně, a tak víte, že se vztahuje pouze na živého člověka. 2Podle zákona je například žena vázána věrností svému muži jen potud, dokud její muž žije. 3Jestliže však manžel zemřel, závazek tím pro ženu skončil; když se tedy provdá za jiného, nikdo ji nemůže obžalovat z mnohomužství. 4Tak i vaše podřízenost zákonu Kristovou smrtí skončila a vy teď náležíte jinému Pánu, totiž vzkříšenému Kristu, aby z vás měl užitek Bůh. 5Dokud jsme si žili po svém, ovládal nás hlad po zakázaném ovoci, touha po tom, co zákon zakazuje; tím jsme si vysloužili smrt. 6Když jsme však s Kristem obrazně zemřeli, unikli jsme moci zákona. Nad naším nynějším životem už není nejvyšší autoritou mrtvá litera zákona, nýbrž Duch živého Krista.

Zákon sám neuschopňuje k bezhříšnému životu

7Tím však nechceme říci, že zákon není dobrý. Vždyť právě zákon nám říká, co je hřích. Kdyby zákon nezakazoval touhu po cizím vlastnictví, ani bych nevěděl, že je to něco špatného. 8Na druhé straně však zákon také ukazuje, že existuje i zakázané ovoce, když říká: Nepožádáš. Tím podněcuje k silnější touze po zakázaném ovoci. A tak vidíme, že kdyby tu nebyl zákon, nebyl by tu ani hřích. 9Příchodem zákona do mého života hřích začal existovat 10-11a s hříchem přišla smrt. A tak se ukázalo, že Boží příkaz, který měl můj život chránit, způsobil vlastně jeho zkázu. Jakmile jsem chtěl jednat nezávisle na Bohu, byl ortel smrti zpečetěn. 12-13Nuže, byla to tedy ta dobrá a správná Boží přikázání, která zapříčinila moji smrt? Nikoliv ona, nýbrž neposlušnost, pýcha mého „já“ přivolala na mou hlavu prostřednictvím dobrých přikázání rozsudek smrti a tím se odhalila jako skutečný nepřítel života. 14Zákon, jak víme, pochází od Boha. My jsme však slabí lidé, jako otroci prodaní hříchu. 15I když víme, co je dobré a správné, a chceme se tím řídit, vyzní naše snaha často v pravý opak. 16Třebaže dobrou vůli máme, neumíme ji proměnit v čin. 17Jako by v nás jednal kdosi jiný proti našemu lepšímu přesvědčení, takže Boží vůli neustále přestupujeme, ačkoliv ji rozumem schvalujeme. Čemu to nasvědčuje? 18-23Ukazuje to, že uvnitř jsme ovládáni zákonem zla, který i naše nejlepší úmysly dovede převrátit ve špatné jednání. Na jedné straně tedy rozumem chceme sloužit Bohu a dobru, na druhé straně neustále podléháme zlu. 24Jak ubozí jsme my lidé! Což neexistuje vysvobození z tohoto nešťastného otroctví? 25Díky Bohu existuje. Je tu cesta, kterou nám otevřel Ježíš Kristus.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Romu 7:1-25

Àpèjúwe kan láti inú ìgbéyàwó

1Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láààyè nìkan? 27.2: 1Kọ 7.39.Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà. 3Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láààyè, panṣágà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóò sì jẹ́ panṣágà bí ó bá ní ọkọ mìíràn.

47.4: Ro 6.2,11; Ga 2.19; Kl 1.22.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run 57.5: Ro 6.13,21; 8.8; Jk 1.15.Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. 6Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé.

Bíbá ẹ̀ṣẹ̀ wọ ìjàkadì

77.7: Ro 3.20; 5.20; Ek 20.17; De 5.21.Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” 87.8: 1Kọ 15.56.Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí ààyè ṣiṣẹ́ onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú. 9Èmi sì ti wà láààyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú. 107.10: Le 18.5; Ro 10.5.Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá. 11Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí ààyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin ṣe ikú pa mi. 127.12: 1Tm 1.8.Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.

13Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá.

147.14: 1Kọ 3.1.Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 157.15: Ga 5.17.Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. 16Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára. 17Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí kì í ṣe èmi ni ó ṣe é bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 18Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. 19Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. 20Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é.

21Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. 227.22: Sm 1.2.Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; 237.23: 5.17.mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi. 247.24: Ro 6.6; Kl 2.11.Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí? 25Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa!

Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.