Deuteronómio 26 – OL & YCB

O Livro

Deuteronómio 26:1-19

Os primeiros frutos e os dízimos

1Quando chegarem à terra que o Senhor, vosso Deus, vos dará, depois de a terem conquistado, e quando começarem a viver ali, 2deverão apresentar ao Senhor, vosso Deus, no lugar que ele tiver escolhido para habitação do seu nome, os primeiros frutos de cada colheita anual. Tragam-nos num cesto 3e entreguem-nos ao sacerdote em exercício nessa altura e digam-lhe: “Estes dons são a prova do meu agradecimento ao Senhor, meu Deus, por me ter trazido à terra que prometeu aos meus antepassados.” 4O sacerdote tomará então o cesto da vossa mão e o porá diante do altar do Senhor, vosso Deus. 5Cada pessoa deverá então dizer diante do Senhor, seu Deus: “O meu antepassado, Jacob, era um velho arameu errante que desceu ao Egito com apenas algumas pessoas. No entanto, ele e os seus descendentes tornaram-se um povo numeroso e forte, uma grande nação. 6Os egípcios maltrataram-nos e oprimiram-nos, obrigando-nos a fazer trabalhos muito pesados. 7Então nós clamámos pelo auxílio do Senhor, o Deus dos nossos antepassados. Ele ouviu-nos, viu a nossa aflição, a nossa miséria, a opressão em que vivíamos; 8tirou-nos de lá por meio de poderosos milagres, com o seu poderoso e forte braço; 9trouxe-nos para este lugar, dando-nos esta terra na qual jorra leite e mel! 10Agora, Senhor, como vês, trago-te este símbolo dos primeiros frutos da terra que nos deste.” Cada um colocará então esses frutos na presença do Senhor, seu Deus, e se inclinará em adoração. 11Depois vão e façam uma festa, alegrando-se por todas as coisas que o Senhor, vosso Deus, vos deu. Comemorem com a vossa família, com os levitas e com os estrangeiros que vivam no vosso meio.

12De três em três anos haverá um dízimo especial. Nesse ano deverão dar todos os vossos dízimos aos levitas, aos estrangeiros, aos órfãos e às viúvas dentro das vossas cidades, para que fiquem satisfeitos. 13Declararão então perante o Senhor, vosso Deus: “Dei todos os meus dízimos aos levitas, aos estrangeiros, aos órfãos e às viúvas, tal como me ordenaste; não esqueci nem violei nenhum dos teus regulamentos. 14Não toquei em nenhum dízimo, enquanto estava cerimonialmente impuro ou quando estava de luto, nem disso ofereci pela memória dum morto. Obedeci ao Senhor, meu Deus, e fiz tudo o que me ordenaste. 15Olha desde a tua santa habitação no céu e abençoa o teu povo e a terra que nos deste, tal como prometeste aos nossos pais; uma terra donde jorrem leite e mel!”

Obediência aos mandamentos do Senhor

16Deverão obedecer de todo o coração a todos estes mandamentos e regulamentos que o Senhor, vosso Deus, hoje vos dá. 17Declararam hoje que ele é o vosso Deus e prometeram obedecer-lhe e guardar as suas leis e ordenações, cumprindo tudo o que vos diz para fazerem. 18O Senhor hoje também declara que são o seu próprio povo, como tinha prometido antes, e que deverão obedecer às suas leis. 19Se assim fizerem, fará de vocês a maior nação entre todas as outras e receberão louvores, honra e fama; contudo, para poder atingir essa fama e prestígio terão de ser um povo santo para o Senhor, vosso Deus; é isso que requer de vós.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 26:1-19

Àkọ́so àti ìdámẹ́wàá

126.1-11: El 22.29; 23.19; 34.26; Nu 18.12,13.Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, 2mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. 3Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.” 4Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ. 5Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. 6Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. 7Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. 8Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu. 9Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. 11Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.

12Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. 13Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn. 14Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pàṣẹ fún mi. 15Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Israẹli, àti fún ilẹ̀ náà tí ìwọ ti fi fún wa, bí ìwọ ti búra fún àwọn baba ńlá wa, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin.”

Tẹ̀lé Àṣẹ Olúwa

16Olúwa Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ. 17Ìwọ jẹ́wọ́ Olúwa ní òní pé Olúwa ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i. 18Ní òní ni Olúwa jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́. 19Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.