2 Reis 6 – OL & YCB

O Livro

2 Reis 6:1-33

Eliseu faz flutuar um ferro

1Um dia, o grupo dos profetas veio ter com Eliseu: “Como estás a ver, as nossas habitações são muito acanhadas. 2Achas que podemos ir até ao Jordão e construir ali melhores alojamentos?” Ele retorquiu: “Podem ir.”

3“Por favor, vem connosco”, pediu-lhe um deles. Eliseu respondeu: “Pois sim.”

4Quando chegaram ao Jordão, começaram a cortar madeira. 5A certa altura, o ferro de um machado caiu ao rio. “Oh! Senhor!”, exclamou ele. “Era emprestado!”

6“Onde foi que ele caiu?”, perguntou o homem de Deus. O jovem mostrou-lhe o sítio; Eliseu cortou um pedaço de madeira e lançou-o à água; o ferro do machado veio ao de cima e ficou a flutuar! 7“Vai apanhá-lo”, disse-lhe o profeta. E assim o recuperou.

Deus cega o exército arameu

8Numa altura em que o rei de Aram estava em guerra contra Israel, aquele rei disse aos seus chefes militares: “Vamos mobilizar as nossas tropas.” E deu-lhes indicações quanto ao processo e ao local de concentração.

9Imediatamente Eliseu avisou o rei de Israel: “Não te aproximes de tal sítio, porque os arameus estão a planear mobilizar ali o seu exército!” 10O rei mandou um estafeta espiar se era assim como Eliseu dizia; e era verdade. Isto aconteceu não só uma vez, mas em várias ocasiões. O homem de Deus salvou dessa forma o rei, repetidas vezes, dum desastre militar.

11O soberano arameu estava atónito. Chamou os seus chefes militares e perguntou-lhes: “Quem é que nos anda a trair? Quem é que faz saber ao rei de Israel os nossos planos?”

12“Não somos nós, senhor”, respondeu um deles. “É o profeta Eliseu que comunica ao rei de Israel até aquilo que dizes na intimidade do teu quarto!”

13“Vão já ver onde é que ele se encontra para que envie soldados que o tragam cá!”, exclamou o rei. E vieram dizer-lhe: “Eliseu está em Dotã.” 14Então, uma noite, o rei de Aram enviou um grande exército, com muitos carros e cavalos, cercar a povoação.

15Quando, no dia seguinte, o criado do homem de Deus se levantou de manhã cedo e saiu de casa, havia tropas, cavalos e carros por toda a parte. “Ai, meu senhor, que vamos fazer agora?”, gritou ele para Eliseu.

16“Não tenhas medo, porque os que estão connosco são muito mais numerosos do que todos eles juntos!” 17Eliseu fez então a seguinte oração: “Senhor, abre-lhe os olhos para que veja!” E o Senhor abriu os olhos do moço, que pôde ver cavalos e carros de fogo por todo o lado na montanha.

18Quando o exército arameu avançou sobre eles, Eliseu orou: “Senhor, peço-te que os cegues.” E assim aconteceu. 19Eliseu foi ao encontro deles: “Vieram pelo caminho errado; não é esta a povoação que vos interessa. Venham comigo e levar-vos-ei ao homem que procuram.” E conduziu-os a Samaria.

20Assim que chegaram, Eliseu orou de novo: “Senhor, abre-lhes os olhos para que vejam.” O Senhor assim fez e os soldados constataram que estavam em Samaria, a capital de Israel!

21O rei de Israel, ao vê-los, gritou para Eliseu: “Senhor, mato-os? Mato-os?”

22Eliseu respondeu: “De maneira nenhuma! Iríamos matar prisioneiros de guerra? Dá-lhes de comer e beber e manda-os embora.” 23O rei preparou-lhes uma grande festa e depois deixou-os ir ter com o seu rei. Depois disso, os comandos arameus suspenderam as investidas na terra de Israel.

Samaria é sitiada

24Mais tarde, contudo, o rei Ben-Hadade de Aram mobilizou todo o seu exército e atacou Samaria. 25Como resultado, houve uma grande fome na cidade. Passado algum tempo, a cabeça dum jumento chegou a custar um quilo de prata e um quarto de litro de esterco de pomba era vendido por uma peça de 60 gramas de prata!

26Um dia em que o rei de Israel ia andando sobre a muralha da cidade, uma mulher chamou-o: “Ajuda-me, ó rei, meu senhor!”

27O rei retorquiu: “Se não for o Senhor que te ajude, que poderei fazer por ti? Não tenho nada que te possa dar; nem da eira trigo, nem do lagar vinho. 28Afinal, de que é que te queixas?” Ela respondeu: “Aqui esta mulher propôs-me que comêssemos num dia o meu filho e no outro o dela. 29Então cozinhámos o meu filho e comemo-lo. Mas, no dia seguinte, quando lhe disse: ‘Dá cá o teu filho para que o cozinhemos’, ela escondeu-o.”

30Quando o rei ouviu isto, rasgou a roupa que tinha vestida. O povo que ali estava, perto da muralha, reparou que o soberano trazia junto ao corpo roupa interior feita de saco. 31“Que Deus me tire a mim a vida, se eu não cortar a cabeça a Eliseu hoje mesmo!”, exclamou o rei.

32Eliseu estava reunido em casa com os anciãos de Israel, quando chegou o recado do rei que o convocava. No entanto, antes mesmo que o mensageiro chegasse, Eliseu disse aos anciãos: “Este assassino enviou-me alguém com a intenção de me matar. Quando ele aparecer, fechem-lhe a porta e não o deixem entrar, porque o seu senhor vem, com certeza, atrás dele.”

33Estava Eliseu ainda a dizer estas palavras, quando o mensageiro chegou; e o rei vinha logo atrás dele: “Foi o Senhor quem provocou toda esta miséria em que estamos!” rouquejou o rei. “Por que razão haveria eu de ficar à espera de alguma ajuda da sua parte?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 6:1-33

Orí àáké fò lójú omi

1Àwọn ọmọ wòlíì sọ fún Eliṣa pé, “Wò ó, ní ibi tí a ti pàdé pẹ̀lú rẹ, ó kéré fún wa. 2Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jordani, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé.”

Ó sì wí pé, “lọ.”

3Nígbà náà ni ọ̀kan lára wọn wí pé, “Kí ó wù ọ́, èmí bẹ̀ ọ́, láti bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ?”

Eliṣa dá a lóhùn pé “Èmi yóò lọ,” 4Ó sì lọ pẹ̀lú wọn.

Wọ́n sì lọ sí Jordani wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gé igi 5Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kígbe sókè pé, “O! Olúwa mi, mo yá a ni!”

6Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Eliṣa gé igi kan ó sì jù ú síbẹ̀, ó sì mú irin náà fò lójú omi. 7Ó wí pé, “Gbé e jáde.” Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un.

8Nísinsin yìí ọba Aramu wà ní ogun pẹ̀lú Israẹli ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbèrò, ó wí pé “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.”

9Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Israẹli, “kíyèsi ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Aramu wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.” 10Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fihàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Eliṣa kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀.

11Èyí mú ọba Aramu bínú. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ìwọ kò ní sọ fún mi èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Israẹli?”

12“Kò sí ọ̀kan nínú wa, olúwa ọba mi,” ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “ṣùgbọ́n Eliṣa, wòlíì tí ó wà ní Israẹli, sọ fún ọba Israẹli ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.

13“Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà,” ọba pa á láṣẹ, “Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá. “Ó wà ní Dotani.” 14Nígbà náà ni ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká.

15Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.

16“Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.”

17Eliṣa sì gbàdúrà, “Olúwa, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká.

18Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Eliṣa gbàdúrà sí Olúwa pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti béèrè.

19Eliṣa sọ fún wọn pé “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samaria.

20Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Eliṣa wí pé, “Olúwa, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samaria.

21Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, Baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?”

22“Má ṣe pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi síwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.” 23Bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè àsè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Aramu dáwọ́ ìgbógunti ilẹ̀ Israẹli dúró.

Ìyàn mú ní Samaria

24Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria. 25Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́ọ̀rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún.

26Gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sọkún sí i pé, “Ràn mí lọ́wọ́, olúwa ọba mi!”

27Ọba sì dá a lóhùn pé, “Bí Olúwa kò bá gbà ọ́, níbo ni èmi yóò gbé ti gbà ọ́? Láti inú ilẹ̀ ìpakà, tàbí láti inú ibi ìfúntí?” 28Nígbà náà ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?”

Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’ 29Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.”

30Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀. 31Ó sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Eliṣa ọmọ Ṣafati kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!”

32Nísinsin yìí Eliṣa jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbàgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Eliṣa sọ fún àwọn àgbàgbà pé, “Ṣé ẹ̀yin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dìímú ṣinṣin ní ẹnu-ọ̀nà, ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ?”

33Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de Olúwa sí i?”