Êxodo 35 – OL & YCB

O Livro

Êxodo 35:1-35

As instruções sobre o sábado

1Moisés convocou todo o povo de Israel e disse-lhes: “Estas são as leis do Senhor a que devem obedecer.

2Trabalharão apenas seis dias. O sétimo é um dia de solene repouso, um dia santo. Todo aquele que trabalhar nesse dia deverá morrer. 3Nem sequer acendam o fogo nas vossas casas nesse dia.”

Ofertas para o tabernáculo

(Êx 25.1-9; 39.32-43)

4E continuou: “Isto é o que o Senhor vos ordenou: 5Todos os que tiverem um coração generoso podem trazer, se assim o desejarem, estas ofertas ao Senhor:

ouro, prata, bronze;

6tecido azul, púrpura e vermelho, feito de linho fino retorcido ou de pelo de cabra;

7peles de carneiro tingidas de vermelho e curtidas, assim como, especialmente, peles de couro fino; madeira de acácia;

8azeite para os candeeiros; especiarias para o óleo da unção e para o incenso aromático;

9pedras de ónix, e pedras para serem usadas no éfode e no peitoral.

10Que todos aqueles que são habilidosos no trabalho manual, e os que têm talentos especiais, venham para construir o que o Senhor mandou:

11o tabernáculo, as suas cobertas, colchetes, tábuas, barras, colunas e bases;

12a arca e as varas de transporte; o propiciatório; o véu para separar o lugar santo;

13a mesa e as varas para transportá-la, assim como os seus utensílios; o pão da Presença,

14o candelabro, com as lâmpadas e o óleo respetivo;

15o altar do incenso e as varas de transporte; o óleo da unção e o incenso aromático; o véu da porta do tabernáculo;

16o altar dos holocaustos; as grelhas de bronze para o altar e as suas respetivas varas e utensílios; a bacia e a sua base;

17os véus das divisórias do pátio e as suas colunas e bases; os véus da entrada do pátio;

18as estacas do pátio do tabernáculo mais as suas cordas;

19os fatos dos sacerdotes, para usarem no ministério do lugar santo; as vestimentas santas para Aarão e os seus filhos.”

20Todo o povo saiu da presença de Moisés e foi para as tendas preparar estes donativos, 21e todos aqueles que sentiram boa vontade e coração generoso foram levar a sua oferta ao Senhor para a construção da tenda do encontro, bem como para as vestimentas sagradas. 22Tanto homens como mulheres, vieram todos aqueles que dispuseram o seu coração para tal. Assim trouxeram ao Senhor ofertas de ouro, pedras preciosas, brincos, anéis e colares e toda a espécie de objetos em ouro, com um gesto de apresentação cerimonial. 23Outros trouxeram tecidos de linho fino retorcido, ou pelos de cabra, em azul, púrpura e vermelho, assim como peles de carneiro tingidas de vermelho, especialmente peles de couro fino. 24Outros ainda trouxeram prata e bronze como oferta para o Senhor. Por fim houve quem trouxesse madeira de acácia necessária para a construção.

25As mulheres hábeis a fiar e coser trouxeram já preparado fio e tecido, e linho fino retorcido em azul, púrpura e vermelho. 26Outras usaram com alegria os seus dons especiais para fiar e fazer tecido de pelo de cabra. 27Os chefes trouxeram pedras de ónix para serem postas no éfode e no peitoral, 28assim como especiarias e óleo, tanto para as luzes, como para a composição do óleo da unção e do incenso aromático. 29E foi desta maneira que o povo de Israel, todos os homens e mulheres que quiseram colaborar na obra que lhes foi dada por mandamento do Senhor a Moisés, trouxeram de livre vontade as suas ofertas ao Senhor.

Os chefes do projeto

(Êx 31.1-11)

30E Moisés disse-lhes: “O Senhor designou especialmente Bezalel, filho de Uri e neto de Hur, da tribo de Judá, como superintendente-geral deste santo projeto. 31O Espírito de Deus encheu-o de sabedoria, capacidade e conhecimentos para a construção do tabernáculo e de tudo o que deve conter. 32Ele está, pois, altamente dotado como artista e desenhador de todas as peças feitas em ouro, prata e bronze. 33Será capaz de trabalhar pedras preciosas e tal como um joalheiro fará também belas gravações. Na verdade é um homem dotado para tudo.

34Deus também dispôs o coração dele e de Aoliabe para ensinarem a outros aquilo que sabem. Aoliabe é filho de Aisamaque da tribo de Dan. 35Deus encheu-os a ambos com um talento pouco vulgar para serem joalheiros, carpinteiros, bordadores em linho e tecidos de azul, púrpura e vermelho, e ainda tecelãos. Eles serão excelentes em todas as tarefas que é preciso executar para esta obra.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 35:1-35

Àwọn ìlànà ọjọ́ ìsinmi

1Mose pe gbogbo ìjọ Israẹli ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti Olúwa ti pàṣẹ fún un yín láti ṣe: 235.2,3: Ek 23.12; 31.12-17; 34.21; De 5.12-15.Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa. 3Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”

Ohun èlò fun Àgọ́

435.4-9: Ek 25.1-9.Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: 5Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti:

“wúrà, fàdákà àti idẹ;

6aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára;

àti irun ewúrẹ́;

7awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù;

odò igi kasia;

8òróró olifi fún títan iná;

olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

9òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.

10“Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrín yín, kí ó wa, kí ó sì wá ṣe gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ:

11“àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

12Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ìbò àánú àti aṣọ títa náà tí ó ṣíji bò ó;

13Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;

14Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;

15Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn;

aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà;

16Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú ààrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀;

agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

17aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà;

18Èèkàn àgọ́ náà fún àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;

19aṣọ híhun láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”

20Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì kúrò níwájú Mose, 21Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà. 22Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa. 23Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá. 24Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá. 25Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára. 26Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́ 27Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. 28Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. 29Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose.

Besaleli àti Oholiabu

3035.30–36.1: Ek 31.1-6.Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 31Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà 32Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, 33láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti ṣiṣẹ́ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù. 35Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.