Salmo 110
Salmo de David.
1Así dijo el Señor a mi Señor:
«Siéntate a mi derecha,
hasta que ponga a tus enemigos
por debajo de tus pies».
2El Señor extenderá desde Sión el poder de tu cetro.
Domina tú en medio de tus enemigos.
3Tus tropas estarán dispuestas
cuando manifiestes tu poder,
ordenadas en santa majestad.
De las entrañas de la aurora
recibirás el rocío de tu juventud.
4El Señor ha jurado
y no cambiará de parecer:
«Tú eres sacerdote para siempre,
según el orden de Melquisedec».
5El Señor está a tu mano derecha;
aplastará a los reyes en el día de su ira.
6Juzgará a las naciones y amontonará cadáveres;
aplastará cabezas en toda la tierra.
7Beberá de un arroyo junto al camino
y por eso levantará su cabeza.
Saamu 110
Ti Dafidi. Saamu.
1110.1: Mt 22.44; 26.64; Mk 12.36; 14.62; 16.19; Lk 20.42-43; 22.69; Ap 2.34; 1Kọ 15.25; Ef 1.20; Kl 3.1; Hb 1.3,13; 10.12-13; 12.2.Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
2Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
3Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
4110.4: Hb 5.6,10; 6.20; 7.11,15,21.Olúwa ti búra,
kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
5Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
6Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
7Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.