Mateus 18 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Mateus 18:1-35

O Maior no Reino dos Céus

(Mc 9.33-37,42-46; Lc 9.46-48)

1Naquele momento, os discípulos chegaram a Jesus e perguntaram: “Quem é o maior no Reino dos céus?”

2Chamando uma criança, colocou-a no meio deles, 3e disse: “Eu asseguro que, a não ser que vocês se convertam e se tornem como crianças, jamais entrarão no Reino dos céus. 4Portanto, quem se faz humilde como esta criança, este é o maior no Reino dos céus.

5“Quem recebe uma destas crianças em meu nome, está me recebendo. 6Mas, se alguém fizer cair no pecado um destes pequeninos que creem em mim, melhor lhe seria amarrar uma pedra de moinho no pescoço e se afogar nas profundezas do mar.

7“Ai do mundo, por causa das coisas que fazem cair no pecado! É inevitável que tais coisas aconteçam, mas ai daquele por meio de quem elas acontecem! 8Se a sua mão ou o seu pé o fizerem tropeçar, corte-os e jogue-os fora. É melhor entrar na vida mutilado ou aleijado do que, tendo as duas mãos ou os dois pés, ser lançado no fogo eterno. 9E, se o seu olho o fizer tropeçar, arranque-o e jogue-o fora. É melhor entrar na vida com um só olho do que, tendo os dois olhos, ser lançado no fogo do inferno.

A Parábola da Ovelha Perdida

(Lc 15.3-7)

10“Cuidado para não desprezarem um só destes pequeninos! Pois eu digo que os anjos deles nos céus estão sempre vendo a face de meu Pai celeste. 11O Filho do homem veio para salvar o que se havia perdido.18.11 Vários manuscritos não trazem o versículo 11.

12“O que acham vocês? Se alguém possui cem ovelhas, e uma delas se perde, não deixará as noventa e nove nos montes, indo procurar a que se perdeu? 13E, se conseguir encontrá-la, garanto que ele ficará mais contente com aquela ovelha do que com as noventa e nove que não se perderam. 14Da mesma forma, o Pai de vocês, que está nos céus, não quer que nenhum destes pequeninos se perca.

Como Tratar a Ofensa de um Irmão

15“Se o seu irmão pecar contra você18.15 Alguns manuscritos não trazem contra você., vá e, a sós com ele, mostre-lhe o erro. Se ele o ouvir, você ganhou seu irmão. 16Mas, se ele não o ouvir, leve consigo mais um ou dois outros, de modo que ‘qualquer acusação seja confirmada pelo depoimento de duas ou três testemunhas’18.16 Dt 19.15. 17Se ele se recusar a ouvi-los, conte à igreja; e, se ele se recusar a ouvir também a igreja, trate-o como pagão ou publicano.

18“Digo a verdade: Tudo o que vocês ligarem na terra terá sido ligado no céu, e tudo o que vocês desligarem na terra terá sido desligado18.18 Ou será ligado… será desligado no céu.

19“Também digo que, se dois de vocês concordarem na terra em qualquer assunto sobre o qual pedirem, isso será feito a vocês por meu Pai que está nos céus. 20Pois onde se reunirem dois ou três em meu nome, ali eu estou no meio deles”.

A Parábola do Servo Impiedoso

21Então Pedro aproximou-se de Jesus e perguntou: “Senhor, quantas vezes deverei perdoar a meu irmão quando ele pecar contra mim? Até sete vezes?”

22Jesus respondeu: “Eu digo a você: Não até sete, mas até setenta vezes sete18.22 Ou 77.

23“Por isso, o Reino dos céus é como um rei que desejava acertar contas com seus servos. 24Quando começou o acerto, foi trazido à sua presença um que lhe devia uma enorme quantidade de prata18.24 Grego: 10.000 talentos. O talento equivalia a 35 quilos.. 25Como não tinha condições de pagar, o senhor ordenou que ele, sua mulher, seus filhos e tudo o que ele possuía fossem vendidos para pagar a dívida.

26“O servo prostrou-se diante dele e lhe implorou: ‘Tem paciência comigo, e eu te pagarei tudo’. 27O senhor daquele servo teve compaixão dele, cancelou a dívida e o deixou ir.

28“Mas, quando aquele servo saiu, encontrou um de seus conservos, que lhe devia cem denários18.28 O denário era uma moeda de prata equivalente à diária de um trabalhador braçal.. Agarrou-o e começou a sufocá-lo, dizendo: ‘Pague-me o que me deve!’

29“Então o seu conservo caiu de joelhos e implorou-lhe: ‘Tenha paciência comigo, e eu pagarei a você’.

30“Mas ele não quis. Antes, saiu e mandou lançá-lo na prisão, até que pagasse a dívida. 31Quando os outros servos, companheiros dele, viram o que havia acontecido, ficaram muito tristes e foram contar ao seu senhor tudo o que havia acontecido.

32“Então o senhor chamou o servo e disse: ‘Servo mau, cancelei toda a sua dívida porque você me implorou. 33Você não devia ter tido misericórdia do seu conservo como eu tive de você?’ 34Irado, seu senhor entregou-o aos torturadores, até que pagasse tudo o que devia.

35“Assim também fará meu Pai celestial a vocês se cada um de vocês não perdoar de coração a seu irmão”.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 18:1-35

Ẹni tí ó tóbi jù ní ìjọba Ọ̀run

118.1-5: Mk 9.33-37; Lk 9.46-48.Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó pọ̀jù ní ìjọba ọ̀run?”

2Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. 318.3: Mk 10.15; Lk 18.17; 1Pt 2.2.Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. 4Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. 518.5: Mt 10.40; Lk 10.16; Jh 13.20.Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí.

6“Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun. 7Ègbé ni fún ayé nítorí gbogbo ohun ìkọ̀sẹ̀ rẹ̀! Ohun ìkọ̀sẹ̀ kò le ṣe kó má wà, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí ìkọ̀sẹ̀ náà ti wá! 8Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé. 9Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì.

Òwe àgùntàn tó sọnù

1018.10: Ap 12.11.“Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèkéé wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. 11Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn wá láti gba àwọn tí ó nù là.

1218.12-14: Lk 15.3-7; 19.10.“Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí? 13Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ? 14Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.

Arákùnrin tí ó ṣẹ̀ sí ọ

1518.15-17: Lk 17.3; 1Kọ 6.1-6; Ga 6.1; Jk 5.19-20; Le 19.17.“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò. 16Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà. 17Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.

1818.18: Mt 16.19; Jh 20.23.“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhun ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run.

1918.19-20: Mt 7.7; 21.22; Jk 1.5-7; 1Jh 5.14; Jh 14.13.“Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín. 20Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrín wọn níbẹ̀.”

Òwe aláìláàánú ọmọ ọ̀dọ̀

2118.21-22: Lk 17.4; Gẹ 4.24.Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”

22Jesu dáhùn pé, “Mo wí fún ọ, kì í ṣe ìgbà méje, ṣùgbọ́n ní ìgbà àádọ́rin méje.

2318.23: Mt 25.19.“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 24Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. 25Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.

2618.26: Mt 8.2.“Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ 27Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.

28“Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’

29“Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’

30“Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. 31Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.

32“Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. 33Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ 34Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́.

3518.35: Mt 6.14.“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”