Lucas 15 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Lucas 15:1-32

A Parábola da Ovelha Perdida

(Mt 18.12-14)

1Todos os publicanos e pecadores estavam se reunindo para ouvi-lo. 2Mas os fariseus e os mestres da lei o criticavam: “Este homem recebe pecadores e come com eles”.

3Então Jesus lhes contou esta parábola: 4“Qual de vocês que, possuindo cem ovelhas, e perdendo uma, não deixa as noventa e nove no campo e vai atrás da ovelha perdida, até encontrá-la? 5E quando a encontra, coloca-a alegremente nos ombros 6e vai para casa. Ao chegar, reúne seus amigos e vizinhos e diz: ‘Alegrem-se comigo, pois encontrei minha ovelha perdida’. 7Eu digo que, da mesma forma, haverá mais alegria no céu por um pecador que se arrepende do que por noventa e nove justos que não precisam arrepender-se.

A Parábola da Moeda Perdida

8“Ou, qual é a mulher que, possuindo dez dracmas15.8 A dracma era uma moeda de prata equivalente à diária de um trabalhador braçal. e, perdendo uma delas, não acende uma candeia, varre a casa e procura atentamente, até encontrá-la? 9E quando a encontra, reúne suas amigas e vizinhas e diz: ‘Alegrem-se comigo, pois encontrei minha moeda perdida’. 10Eu digo que, da mesma forma, há alegria na presença dos anjos de Deus por um pecador que se arrepende”.

A Parábola do Filho Perdido

11Jesus continuou: “Um homem tinha dois filhos. 12O mais novo disse ao seu pai: ‘Pai, quero a minha parte da herança’. Assim, ele repartiu sua propriedade entre eles.

13“Não muito tempo depois, o filho mais novo reuniu tudo o que tinha e foi para uma região distante; e lá desperdiçou os seus bens vivendo irresponsavelmente. 14Depois de ter gasto tudo, houve uma grande fome em toda aquela região, e ele começou a passar necessidade. 15Por isso foi empregar-se com um dos cidadãos daquela região, que o mandou para o seu campo a fim de cuidar de porcos. 16Ele desejava encher o estômago com as vagens de alfarrobeira que os porcos comiam, mas ninguém lhe dava nada.

17“Caindo em si, ele disse: ‘Quantos empregados de meu pai têm comida de sobra, e eu aqui, morrendo de fome! 18Eu me porei a caminho e voltarei para meu pai e lhe direi: Pai, pequei contra o céu e contra ti. 19Não sou mais digno de ser chamado teu filho; trata-me como um dos teus empregados’. 20A seguir, levantou-se e foi para seu pai.

“Estando ainda longe, seu pai o viu e, cheio de compaixão, correu para seu filho, e o abraçou e beijou.

21“O filho lhe disse: ‘Pai, pequei contra o céu e contra ti. Não sou mais digno de ser chamado teu filho15.21 Alguns manuscritos acrescentam Trata-me como um dos teus empregados.’.

22“Mas o pai disse aos seus servos: ‘Depressa! Tragam a melhor roupa e vistam nele. Coloquem um anel em seu dedo e calçados em seus pés. 23Tragam o novilho gordo e matem-no. Vamos fazer uma festa e alegrar-nos. 24Pois este meu filho estava morto e voltou à vida; estava perdido e foi achado’. E começaram a festejar o seu regresso.

25“Enquanto isso, o filho mais velho estava no campo. Quando se aproximou da casa, ouviu a música e a dança. 26Então chamou um dos servos e perguntou-lhe o que estava acontecendo. 27Este lhe respondeu: ‘Seu irmão voltou, e seu pai matou o novilho gordo, porque o recebeu de volta são e salvo’.

28“O filho mais velho encheu-se de ira e não quis entrar. Então seu pai saiu e insistiu com ele. 29Mas ele respondeu ao seu pai: ‘Olha! todos esses anos tenho trabalhado como um escravo ao teu serviço e nunca desobedeci às tuas ordens. Mas tu nunca me deste nem um cabrito para eu festejar com os meus amigos. 30Mas quando volta para casa esse teu filho, que esbanjou os teus bens com as prostitutas, matas o novilho gordo para ele!’

31“Disse o pai: ‘Meu filho, você está sempre comigo, e tudo o que tenho é seu. 32Mas nós tínhamos que celebrar a volta deste seu irmão e alegrar-nos, porque ele estava morto e voltou à vida, estava perdido e foi achado’ ”.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 15:1-32

Òwe àgùntàn tó sọnù

115.1-2: Lk 5.29-30; 19.7.Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 2Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”

3Ó sì pa òwe yìí fún wọn, pé, 415.4-7: Mt 18.10-14.“Ọkùnrin wo ni nínú yín, tí ó ní ọgọ̀rún-ún àgùntàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yóò sì tọ ipasẹ̀ èyí tí ó nù lọ, títí yóò fi rí i? 5Nígbà tí ó bá sì rí i tán, yóò gbé e lé èjìká rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀. 6Nígbà tí ó bá sì dé ilé yóò pe àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóò sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mí yọ̀; nítorí tí mo ti rí àgùntàn mi tí ó nù.’ 715.7: Jk 5.20; Lk 19.10; 15.10.Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yóò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà, ju lórí olóòtítọ́ mọ́kàn-dínlọ́gọ́rùn-ún lọ, tí kò nílò ìrònúpìwàdà.

Òwe owó tó sọnù

8“Tàbí obìnrin wo ni ó ní owó fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i? 9Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí owó fàdákà tí mo ti sọnù.’ 10Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

Òwe ọmọ tó sọnù

1115.11: Mt 21.28.Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì: 1215.12: De 21.15-17.“Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

13“Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. 14Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. 15Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. 16Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un.

17“Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín. 18Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Baba, èmí ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ; 19Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’ 20Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ.

“Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

21“Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́!

2215.22: Gẹ 41.42; Sk 3.4.“Ṣùgbọ́n baba náà wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀: 23Ẹ sì mú ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á; kí a máa ṣe àríyá: 2415.24: 1Tm 5.6; Ef 2.1; Lk 9.60.Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríyá.

25“Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin àti ijó. 26Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kín ni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí? 27Ó sì wí fún un pé, ‘Arákùnrin rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlàáfíà àti ní ìlera.’

28“Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; baba rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í ṣìpẹ̀ fún un. 29Ó sì dáhùn ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Wò ó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá: 30Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò, ìwọ sì ti pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa fún un.’

31“Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni. 32Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí arákùnrin rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”